''A kò lè sọ bóyá alága ẹgbẹ́ APC tí wọ́n jígbé l'Ondo ti kú tàbí kò tíì kú''

Aworan kọmiṣọnna ọlọpaa Ondo

Oríṣun àwòrán, Ondo State Police/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn ko le fi idi rẹ mulẹ titi di asiko ti a n kọ iroyin yi pe loootọ ni Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ijọba ibilẹ Ose, Ọgbẹni Nelson Adepoyigi, ti ku si akata awọn ajinigbe.

Ti ẹ o ba gbagbe, ni owurọ ọjọ Aiku to kọja ni iroyin jade pe awọn ajinigbe ti ṣekupa Ọgbẹni Adepoyigi.

Alaga ijọba ibilẹ Ose, Kolapo Ojo, lo kede iku oloogbe ọhun ninu atejade ti o fi sọwọ si awọn oniroyin.

Ṣugbọn alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo Olushola Alayande salaye pe awọn ikọ ileeṣẹ ọlọpaa ti lọ kaakiri inu igbo ti wọn gbe oloogbe naa si ti wọn ko si ri oku rẹ titi di asiko yi.

Alayande ni awọn eeyan meji lara awọn ọmọ ilu rẹ to yan lati lọ gbe owo itusilẹ naa fun awọn ajinigbe ọhun, ni wọn mu wọn lọ inu igbo ti wọn ko wọn si, ti wọn si gbiyanju lati wa oku rẹ, amọ ti wọn ko si ri titi di oni.

Alukoro Ọlọpaa naa sọ pe awọn mọlẹbi oloogbe naa ko fi ọrọ owo ti wọn san to ọlọpaa leti.

O ni ṣe ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣadeede gbọ pe wọn ti lọ san millionu marun-un naira eyi to ni o kudiẹ kaato.

Alayande seleri pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri daju pe wọn sawari okunrin naa, wọn yoo si tun fi panpe ofin mu awọn ajinigbe.

Ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ lori iṣẹlẹ naa

Agbenusọ fẹgbẹ Oṣelu APC l'Ondo, Alex Kalejaiye, ṣapejuwe iṣẹlẹ ijinigbe naa gẹgẹ bi ohun to buru jai.

O salaye pe iṣẹlẹ ijinigbe ọhun ko lọwọ oṣelu ninu, sugbọn o jẹ sababi ibi ti o si le sẹlẹ si ẹnikẹni.

Kalejaiye sọ pe iṣẹlẹ naa ba ẹgbẹ oṣelu APC ninu jẹ lọpọlọpọ, nitori wọn padanu ọkan lara ọmọ ẹgbẹ to to gbangba sun lọyẹ nijọba ibilẹ Ọsẹ.

O wa sọ di mimọ pe wọn ti n se ipade pẹlu awọn esọ alaabo lati ri daju pe iṣẹlẹ ijinigbe di ohun igbagbe nipinlẹ Ondo.

O parọwa si gbogbo awọn ara ilu lati ṣe ara wọn losusu ọwọ, ki wọn si fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn eleto abo ki adinku le deba iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe l'Ondo.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Iroyin sọ di mimọ pe asiko ti alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ijọba ibilẹ Ose n jade kuro ninu ọkọ ayekẹlẹ rẹ niluu Ifon ni awọn ajinigbe naa kọlu u, ti wọn si gbe lọ.

Lẹyin iṣẹlẹ naa lawọn ajinigbe ọhun beere ọgọrun miliọnu naira lọwọ awọn mọlẹbi rẹ gẹgẹ bii owo itusilẹ.

Amọ lẹyin ọpọ idunadura wọn fẹnuko si miliọnu marun un naira.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, eeyan meji lara awọn ọmọ ilu rẹ ni wọn yan lati lọ gbe owo itusilẹ naa fun awọn ajinigbe ọhun.

Amọ nigba ti wọn yoo de ibẹ, niṣe lawọn ajinigbe naa tun mu awọn eeyan ọhun mọlẹ ti wọn tun n bere owo gọbọi mii si.

Awọn ajinigbe naa kan si awọn ẹbi alaga ọhun pe ọgbọn milọnu naira lawọn yoo gba lati tu awọn mẹtẹta silẹ.

Amọ ṣa, lẹyin akoko diẹ, awọn ajinigbe yii tu awọn meji ti wọn ṣẹṣẹ mu silẹ ti a si gbọ pe wọn ti pinnu pe pipa lawọn yoo pa Adepoyigi.

Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, alaga ijọba ibilẹ Ose, Kolapo Ojo sọ pe eto abo agbegbe Ifon ati ijọba ibilẹ Ose ti buru kọja afẹnusọ.