'Ìfìyà-jẹ-ara ẹni ni Libya tí mo wá, mi ò tọrọ irú ẹ fún ọ̀tá mi'

Oríṣun àwòrán, Mukthar
"Mo fi Ọlọrun bura, bi wọn ba ni ki n ko gbogbo ohun ti mo ni bayii silẹ, pe wọn a jẹ ki n maa lọ sile, ma a da gbogbo ẹ silẹ lọwọ kan ni. Ti mo ba dele, ma a da omi silẹ, ma a mu un, ma a si dọbalẹ fi dupẹ fun Ọlọrun."
Wọnyi ni ọrọ ti ọmọkunrin kan, Mukhtar, to fẹẹ gba ọna ẹburu lọ si Europe ṣugbọn to ba ara rẹ ni Libya, sọ nigba to n ṣalaye iriri rẹ fun BBC.
Ipinlẹ Maiduguri ni Muktahr ti wa gẹgẹ bo ṣe wi, o wa lara ọpọ ọmọ ilẹ Iwọ-Oorun Africa ti wọn fẹẹ japa lọ si apa Europe, ṣugbọn ti wọn ko sinu agbami iṣoro ni Ariwa Africa.
Pupọ ninu wọn lo pade iku ojiji, yala nigba ti wọn n lọ tabi nigba ti wọn ba ara wọn ni awọn ilu bii Libya, nibi ti awọn ologun ti n ba ara wọn ja ija agba.
Awọn ti wọn ba jaja rọna wọle lati ibi alagbalugbu omi okun (Mediterranean Sea),ijakulẹ ti ko lẹgbẹ ni wọn n koju.
Ni Libya ti Mukthar ha si, ko si ijọba gidi nibẹ latigba ti wọn ti pa Aarẹ Muammar Gaddafi ni 2011.
Igun meji lo ti n ba ara wọn ja ija agba latigba naa lati dari ilu.
Akọkọ ni ti Abdelhamid Dbeibah,ni Tripoli, eyi ti Ajọ Agbaye (UN) n ṣatileyin fun, ati igun ti Tobruk Khalifa Haftar n dari.
Awọn agbebọn tun kun ibẹ pẹlu, ti wọn n pade awọn arinrinajo ti wọn si n mu wọn lẹru.
Wọn le ta wọn bii nnkan elo, wọn si le pa wọn.
Ko si iṣẹ, ko si aabo fun arinrinajo to fọna ẹburu wọlu, bii ẹni pe ogun to ri ogun ni.
"Mi ò dágbére fawọn ẹbi mi ki n too gbera irinajo yii, ki wọn ma baa sọ pe ki n ma lọ, aṣe mo fẹẹ lọọ wẹwọn, jiya ni"

Oríṣun àwòrán, Mukthar
Ninu alaye rẹ siwaju, Muktar sọ pe:
"Mi o dagbere fun awọn ẹbi mi ti mo fi kuro ni Maiduguri, nitori mi o fẹ ki wọn sọ pe ki n ma lọ.
"Igbagbọ ni pe ti mo ba de ibi ti mo n lọ, ma a le ran wọn lọwọ.''
Akẹkọọ gboye naa tẹsiwaju pe airiṣẹ-ṣe ni Maiduguri pẹlu idaamu Boko Haram lo mu koun fẹẹ japa lọ si Europe.
O ni ẹsẹ loun fi rin lati abule oun de ibi kan ti a mọ si Baga.
Lẹyin to kuro ni Maiduguri, o dara pọ mọ awọn ti wọn jọ fẹẹ rin irin ajo naa ni Kano. Lati Kano ni wọn ti ko wọn sọkọ, wọn lo di Europe.
"A kọkọ de Agadez, lorilẹede olominira Niger, lẹyin ọjọ diẹ, wọn ko wa sinu tirela, a si rin fun ọjọ mejila gbako ni aginju Sahara ka too de ilu Qatrun, ni Libya.
"A bọ̀ sọ́wọ́ àwọn agbófinró, wọ́n kó wa mọ́ mààlúù, da àpò bò wá lórí"

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lẹyin ti wọn kọja awọn ibi kan, Mukhtar ṣalaye pe awọn bọ sọwọ awọn agbofinro nigba tawọn fẹẹ kuro ni Sabha, ti awọn fẹẹ wọ Tripoli.
"A de teṣan ọlọpaa, wọn beere ibi ti mo ti n bọ ati iwe irinna mi, ṣugbọn mi o ni."
"Wọn ni 'inta kilifti', ni mi, itumọ rẹ ni pe ọdaran ni mi."
"Bi wọn ṣe mu gbogbo awa ta a jẹ dudu niyẹn. Awọn ọmọ Sudan, Chad ati Niger, wọn si ko wa da si ọgba ẹwọn Misrata."
Ki wọn too ko wọn da si ọgba ẹwọn, Mukthar ṣalaye ohun ti oju rẹ ri loju ọna naa.
"Inu ọkọ ti maaluu wa ni wọn ko wa si, wọn to wa leri ara wa, wọn da apo tapoli bo wa lori, wọn ko tiẹ ro o boya ooru pa wa sibi tabi a yè."
"Mo fi Ọlọrun bura, mi o tọrọ iru irinajo yii fun ọta mi. Mi o fẹ ki wọn gba ọna Sahara de Libya."
Lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àárẹ̀ kọlu Mukthar.
Wọn tọju rẹ ninu ọsibitu ẹwọn, ṣugbọn aarẹ naa kọja agbara wọn.
Nigba naa ni wọn gbe e lọ sileewosan nigboro, nibi ti alaafia rẹ ti pada, awọn onitọju naa si ran an lọwọ ti ko fi pada sọgba ẹwọn mọ.
Ni bayii, telọ ni Mukhtar n ṣe ni Tripoli, labẹ oniṣowo ọmọ Egypt kan.
O wu u ko pada wa sile ṣugbọn ẹru ewu to pọ lọna to koju nigba to n bọ n ba a, bẹẹ ni ko ni iwe irinna to le fi wọ ọkọ ofurufu.
Kò sí ọ̀nà àbáyọ
Ninu oṣu Kẹta ọdun yii, ajọ Nigerians Overseas Commission (NiDCOM) to n ri si ọrọ awọn ọmọ orilẹede yii loke okun, kede pe oun ti ko ọmọ Naijiria 956 wale lati Libya.
NiDCOM sọ pe ninu oṣu mẹta akọkọ ọdun 2025 loun ko awọn eeyan naa wale pẹlu ajọṣepọ International Organization for Migration (IOM) ati awọn ajọ mi-in.
Ṣugbọn sibẹ naa, o jọ pe awọn ọmọ Naijiria ṣi ha si Libya, lai ri ọna ti wọn le gba pada wale. Ko si jọ pe yoo ṣee ṣe fun wọn laipẹ rara.
Mukhtar ṣalaye pe oun ti lọ so ọfiisi Naijiria to wa nibẹ titi, boya wọn yoo tiẹ le ṣaanu ki wọn ko oun naa mọ awọn to n bọ ni Naijiria.
O ni ṣugbọn ero bii ọja mẹta lo maa n wa nibẹ, bẹẹ ni ati ri fọọmu kọwọ bọ paapaa di ogun.
O ni wọn sọ foun pe awọn obinrin ati awọn ọmọde ni wọn ṣi n mu tiwọn ro lọwọ.
Iṣẹ́ wo ni àwọn èèyàn dúdú ń ṣe ní Libya?
Ọpọ awọn eeyan dudu ti wọn n de si Libya pẹlu erongba lati gbabẹ de ilẹ Europe ki I ri nnkan gidi ṣe.
Eyi ri bẹẹ nitori pupọ wọn ni ko kawe de aaye to yanju, bẹẹ ni wọn ko niṣẹ ọwọ gid ikan.
Koda bi wọn ba kawe gboye, pe wọn wọlu naa lọna èrú yoo jẹ ko ṣoro fun wọn lati ri iṣẹ gidi ṣe.
Bo tilẹ jẹ pe Mukhtar ni iwe ẹri oniwe giga ni Naijiria ni tiẹ, ko le fi waṣẹ ni Libya, eyi to fa a to fi jẹ abẹ Arab kan lo ti n dọgbọn ṣe telọ.
"Ni Tripoli, iṣẹ tawọn eeyan dudu n ṣe ko ju ki wọn maa ba wọn ko yẹpẹ, ki wọn maa ko biriki, ki wọn ṣiṣẹ aṣọ́gbà, darandaran tabi ki wọn maa sin nnkan ọsin, awọn mi-in si n ba wọn gbẹ kanga."
Mukhtar lo ṣalaye bẹẹ.














