Kí ni Ààrẹ Tinubu, Peter Obi àti Kayode Fayemi bá ara wọn sọ nígbà tí wọ́n pàdé nibi ayẹyẹ Poopu ni Rome?

Gomina Ekiti tẹlẹ, Kayode Fayemi; Peter Obi;ondupo aarẹ lẹgbẹ Labour ati Aarẹ Bola Tinubu ni Rome.

Oríṣun àwòrán, Kayode Fayemi/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ni ana ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun oṣu Karun-un ọdun 2025, Aarẹ Bola Tinubu, Peter Obi to dupo aarẹ ninu ẹgbẹ Labour ati gomina Ekiti tẹlẹ, Kayode Fayemi; pade niluu Rome, nibi ayẹyẹ ifinijoye Poopu Leo XIV.

Iroyin sọ pe bi Fayemi ṣe ri Aarẹ nibi to jokoo si pẹlu awọn olori orilẹede mi-in, o sọ fun Peter Obi pe ko jẹ k'awọn lọọ fi ọla fun ẹni to tọ si, kawọn lọọ ki aarẹ Naijiria.

Fayemi lo kọkọ sọrọ bi wọn ṣe debẹ, o ni: "Aarẹ, ẹ kaabọ si ṣọọṣi wa, ẹ si ṣeun ti ẹ waa pọn Poopu naa le."

"Emi lo yẹ ki n maa ki iwọ ati Peter kaabọ. Emi ni olori ikọ̀ Naijiria".

Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu fesi ti awọn eeyan n gbe kiri pe o fi ajulọ han Obi ati Fayemi.

Ṣugbọn niṣe lawọn mejeeji bu sẹrin, wọn gba pe bo ṣe ri gan-an ni aarẹ sọ.

Nigba to n da Tinubu loun, obi sọ pe: "Bẹẹ ni o, ara ikọ̀ yin ni awa naa".

Gẹgẹ bi a ṣe mọ, ọmọ ijọ Aguda pọnbele ni Peter Obi ati Kayode Fayemi, wọn si joye pataki ninu ijọ Katoliiki naa.