Ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ Póòpù Leo XIV wáyé, Tinubu, Zelensky àtọ̀pọ̀ olórí orílẹ́èdè àgbáyé péjú

Aworan Poopu Leo XIV

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ olori orilẹede agbaye lo peju pesẹ sibi ayẹyẹ ifilọlẹ Poopu Leo XIV gbagede St Peter's Square niluu Rome lorilẹede Italy lonii ọjọ kejidinlogun oṣu Karun un yii.

Nibẹ ni wọn ti fi oruka apẹja si Poopu lọwọ eyi to n ṣapejuwe ipo rẹ ati aṣa to ni ṣe pẹlu Apọsu Peteru inu Bibeli.

Ṣaaju laarọ oni ni Poopu Leo XIV ti ki awọn eeyan lati inu ọkọ to wa, eyi to jẹ igba akọkọ ti wọn iru ọkọ bẹẹ lati igba to ti di Poopu.

Aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymyr Zelensky ati Igbakeji Aarẹ Amẹrika, JD Vance wa lara awọn olujọsin ni St. Peter's Square nibi ifilọlẹ Poopu Leo XIV.

Ọjọ kẹjọ oṣu Karun un yii ni Poopu waasu fun igba akọkọ lẹyin iyansipo rẹ.

Ninu iwaasu rẹ akọkọ naa si lo ti pe fun iṣọkan ninu ijọ Katoliiki ati lati mu opin ba ogun lagbaaye.

Poopu tun gba aṣọ to da bii iborun ti o fi le ejika eyi to ṣapujuwe ipo rẹ gẹgẹ bii oluṣọ agutan.

Ninu iwaasu rẹ, Poopu tun pe fun iṣọkan ninu ijọ Katoliiki, o ni pẹlu ibẹru loun fi bawọn ọmọ ijọ naa sọrọ gẹgẹ bi ara ninu Oluwa.

Ṣaaju ni ibẹrẹ oṣu yii ni wọn Leo gẹgẹ bii Poopu tuntun ati olori ijọ Aguda, lẹyin iku Poopu Francis.

Ọjọ meji gbako lawọn alufaa fi dibo niluu Vatican City lati yan Poopu Leo XIV sipo.

Ọjọ kẹsan an oṣu Karun un yii ni Poopu Leo XIV waasu fun igba akọkọ nile ijọsin Sistine Chapel.

O lo iwaasu naa lati tako iwa ainigbagbọ ọpọ ijọ, nigba ti o pe fun iṣọkan laarin awọn alufaa ijọ Aguda.

Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Leo XIV, Póòpù tuntun ìjọ Kátólíìkì

Aworan Poopu Leo XIV

Oríṣun àwòrán, Reuters

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ki wọn to kede orukọ rẹ gẹgẹ bi Poopu tuntun ni awọn ero to wa niwaju ile ijọsin St. Peter's Basilica ti n pariwo "Kẹmi poopu o gun".

Robert Prevost, ẹni ọdun mọkandinlaadọrin, ni popu ọtalerugba ati meje ti yoo gun ori akeefa ni St Peter, orukọ apejẹ ti wọn si fun un ni, Leo kẹrinla, XIV.

Robert Prevost ni Popu akọkọ lati orilẹede Amẹrika, bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọlọpọ eeyan lo tun n fi oju ara ilẹ Larin Amerika wo o nitori ọpọlọpọ ọdun to fi ṣe iṣẹ oniwaasu lorilẹede Peru, ki o to di Biṣọọbu nibẹ.

Ni ọdun 1955 ni wọn bii ni Chicago. Prevost ṣíṣe gẹgẹ bi oṣiṣẹ ori pẹpẹ ki wọn ti ta ororo lee lori si ipo alufaa lọdun 1982. Bi o tilẹ jẹ pe o pada si Peru lẹyin ọdun kẹta, sibẹ kii ye ṣe abẹwo si orilẹede Amẹrika loorekoore lati ṣiṣẹ oluṣọaguntan nibẹ.

Poopu Leo XIV tun ni iwe omo onilu orilẹede Peru lọwọ, bẹẹni wọn ko gbagbe awọn iṣẹ takuntakun ti ṣe fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ ati mimu alaafia ati iṣọkan wa fun awọn eeyan nibẹ.