Kọngílá parí títì, àgbàrá òjò wọ́ọ lọ lọ́jọ́ kejì, Gómìnà Adeleke bá fárígá l'Osun

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Osun ti paṣẹ pe ki wọn lọ ṣe atunṣe si oju ọna ti agbara ojo gbe lẹyin ọjọ diẹ ti wọn da ọda le lori.

Adugbo Aduramigba, to wa ni Ido-Osun, ni ijọba ibile Egbedore ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ṣaaju ni awọn eeyan agbegbe ọhun ti kọkọ fẹhonuhan lẹyin iṣẹlẹ naa ti wọn si di ẹbi ṣiṣẹ iṣẹ ti ko bojumu kan awọn alagbaṣe to ṣe ọna ọhun.

Awọn eeyan naa sọ pe iṣẹ naa ko daa rara, koda laarin ọsẹ diẹ ti wọn pari rẹ ni ọda ori rẹ bẹrẹ si n ṣi.

Lẹyin ti iroyin naa jade ni gomina Ademola Adeleke ke si awọn alabaṣiṣẹ rẹ lati tẹkọ leti siluu naa lati foju ganni ipo ti oju ọna ọhun wa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina Osun, Olawale Rasheed fi lede, o ni ojuṣe awọn to lọ sibẹ ni lati wo bi ọna naa ṣe ri, ki wọn ba awọn eeyan ilu naa sọrọ ki wọn si fi ọkan wọn balẹ pe gomina ko fi ọwọ kekere mu ọrọ ọhun.

Yatọ si awọn araalu, awọn aṣoju ijọba naa tun ṣe ipade pẹlu awọn alaṣẹ ileeṣẹ to ṣe titi tuntun naa lati mọ ohun to ṣẹlẹ ati ọna abayọ.

Lẹyin ipade naa ni awọn aṣoju ọhun yoo fun gomina Adeleke lesi ohun ti wọn ba bọ lati ibi to ran wọn.

Rasheed ni "Awọn aṣoju naa sọrọ lori aṣẹ gomina pe ki wọn ṣatunṣe iṣẹ ọhun ni kankan ni ọna to bojumu.

"Wọn fi da awọn eeyan ilu naa loju pe yatọ si atunṣe ọna yii, gomina tun ti n wo awọn akanṣẹ iṣẹ mii to le ṣe fun wọn.

"Awọn aṣoju ọhun ti n ba ileeṣẹ naa sọrọ lọwọ lati ṣe iwadii ohun to ṣẹlẹ ki wọn le fi esi iwadii wọn to gomina leti.

"Ọjọ Aje ni wọn yoo fi esi iwadii wọn to gomina leti lati mọ igbesẹ to kan."