Ìdí tí mo fi pè fún àtúntò ìgbìmọ̀ àwọn ọba l' Oyo -Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Seyi Makinde.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/x

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Pelu bi awuyewuye ṣe n waye lori atunto igbimọ lọbalọba ni ipinlẹ Ọyọ, gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Seyi Makinde ti ṣalaye idi atunto naa.

Ninu ọrọ to sọ nibi ayẹyẹ aṣekagba ajọdun aṣa ni ipinlẹ Ọyọ eyi to waye ni ilu Ibadan lọjọ Satide, Gomina Makinde ṣalaye pe gbogbo ẹtọ to tọ si awọn ọbalaye loun yoo fun wọn. O ni ki oun to wọle sipo lọdun 2019, ko si nnkan to n mi lara igbimọ l'ọbal'ọba ni ipinlẹ Ọyọ, pẹlu bi awọn ọbalaye ni ipinlẹ naa ṣe sọ ajọṣepọ laarin ara wọn di konkojabele kaluku lo mi ṣe tirẹ.

O wa fi kun un pe awọn ọbalaye yio bẹrẹ si ni i ri ẹtọ wọn gbogbo gba ni kete ti wọn ba ti ṣe ifilọlẹ igbimọ l'ọbalọba naa.

"Awọn eeyan ti wa n bi mi pe ki gan lo n ṣẹlẹ pẹlu ọrọ igbimọ l'ọbal'ọba ni ipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn mo ṣalaye peko si igbimọ kankan nigba ti mo de ipo. Olori ile aṣofin wa nibi, wọn ko le gbe igbimọ kankan kalẹ.

"Ni kete ti wọn ba ti ṣe ifilọlẹ igbimọ yii, ẹtọ awọn ọbalaye yio maa tẹ wọn lọwọ loorekoore "

Gomina Seyi Makinde pẹlu olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/x

Mo ti paṣẹ fun awọn alaga kansu ni Ibadan lati ra ọkọ to jọju fun Olubadan – Gomina Makinde

Ninu itẹsiwaju ọrọ rẹ, Gomina Makinde fi kun un pe gẹgẹ bi ara imuṣẹ ìpinnu fifi ẹtọ awọn ọbalaye le wọn lọwọ, oun ti wa paṣẹ fun awọn ijọba ibilẹ mọkanla to wa ni ilu Ibadan lati parapọ ra awọn ọkọ to jọju fun elo Kabiyesi Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Owolabi Olakuleyin.

O ni kii oṣu karun un to pari ni ọkọ tuntun naa yoo de aafin Ọba naa.