Ọrọ̀-ajé ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ l‘Oyo, N12bn la fi ń sanwó oṣù òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀, N10bn fún òṣìṣẹ́ ìbílẹ̀ lóṣooṣù - Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti sọ pe ọrọ aje ipinlẹ ti fẹsẹ mulẹ debi pe owo bii biliọnu mẹrinlelogun naira ni ijọba fi n sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ loṣooṣu bayii.
Makinde ni igbiyanju ijọba oun lati mu ọrọ-aje ipinlẹ Oyo gbooro si naa ti n so eso rere pẹlu bawọn ileeṣẹ aladaani ti n gberu si.
Gomina ni ọpọ awọn ileeṣẹ aladaani naa lo ti n fẹsẹ mulẹ daadaa kaakiri ipinlẹ Oyo bayii.
Makinde fọrọ yii lede lasiko tawọn ọba alaye, awọn musulumi, awọn ojiṣẹ Ọlọrun atawọn to di ipo kan tabi omiran mu ninu ijọba ṣe abẹwo si i nile rẹ to wa lagbegbe Ikolaba niluu Ibadan fun ayẹyẹ ọdun itunu awẹ.
Awọn alẹnulọrọ lagbo oṣelu bii Otun Olubadan ti ilẹ Ibadan, Sẹnẹtọ Rashidi Ladoja, Oloye Sharafabdeen Alli to jẹ sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun guusu Oyo, igbakeji alaga gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu PDP, Taofeek Arapaja ati Ọjọgbọn Kamil Oloso ti igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Abdulraheem Bayo Lawal, dari wọn wa lara awọn to ṣabẹwo si Makinde nile rẹ.
Gomina ipinlẹ Oyo ko ṣai gboṣuba fun wọn fun adura, ifaraẹnijin ati atilẹyin wọn fun ijọba ipinlẹ naa.
Makinde ni idagbasoke ati ọrọ aje ipinlẹ Oyo to fẹsẹ mulẹ bayii ko ṣẹyin alaafia ati ibagbepọ pẹlu iṣọkan to wa laarin awọn eeyan ipinlẹ naa.
''Ti a ba le ba ara wa gbe pẹlu iṣọkan ati alaafia, ilọsiwaju ati idagbasoke yoo ba ipinlẹ wa''
Gomina ko ṣai rọ araalu lati tubọ maa gbe pọ ni alaafia si, ki idagbasoke le ba ipinlẹ Oyo siwaju si.
''Ti a ba le ba ara wa gbe pẹlu iṣọkan ati alaafia, ilọsiwaju ati idagbasoke yoo ba ipinlẹ wa.
Ohun to n ṣẹlẹ lọwọ bayii niyẹn ni ipinlẹ Oyo, ti a ba ni suuru, gbogbo nnkan ti a fẹ ṣe ni yoo di ṣiṣe ni irọrun.
Lara nnkan ti a fẹ ni pe ki eto ọrọ aje wa nipinlẹ Oyo fẹsẹ mulẹ daadaa.
Ni bayii, lọsẹ mẹrin-mẹrin, owo bii ₦24bn lo n wọ inu ọrọ aje wa nipasẹ owo oṣu awọn oṣiṣẹ.
₦14bn ni a fi n sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ ipinlẹ, nigba ti ₦10bn n ba owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ lọ loṣooṣu,'' Makinde lo sọ bẹẹ.
Makinde fikun ọrọ rẹ pe ọpọ oniṣowo lo ti n wa dokowo bayii lai si ifoya.
Gomina ipinlẹ Oyo wa rọ awọn alaṣẹ to dipo oṣelu mu ni Naijiria lati ṣe daadaa fun awọn araalu tori ilu ko fara rọ lasiko yii.
Ninu ọrọ tiẹ, Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Owolabi Olakulehin, ẹni ti Otun Olubadan, Rashidi Ladoja ṣoju rẹ, rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati ni suuru pẹlu ijọba ki wọn si maa sọ ireti nu.
Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo naa lu gomina lọgọ ẹnu lori bii ijọba rẹ ṣe n sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ deedee ati lori bi o ṣe n fi ibẹru Ọlọrun ati otitọ ṣe ijọba.















