Díẹ̀ ló kù kí n jáwọ́ nínú dídu ipò ààrẹ lásìkò ọ̀wọ́ńgógó Naira, ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò kọjú re sí mi – Tinubu

Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti ṣalaye pe diẹ lo ku ki oun jawọ ninu idije ipo aarẹ toun gbegba rẹ ni 2023, lasiko kan ti aisi owo naira gbode.

Aarẹ Tinubu sọrọ yii lọjọ Abamẹta, lasiko ti awọn eeyan n ṣinu aawẹ ọjọ naa pẹlu rẹ nile agbara to wa l'Abuja.

Gẹgẹ bi Tinubu ṣe wi, "awọn to sunmọ mi mọ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ nigba yẹn ko kọ oju ire si mi rara.

"Lasiko ti mo n polongo ibo, ẹnikan ninu wọn wa ba mi laago mẹta aabọ ìdájí, o loun nilo ẹgbẹrun lọna aadọta naira pere (50,000) lati fi ra ounjẹ fun ẹgbọn wa agba.

" O sọ fun pe nitori temi ni ko ṣe si owo naira nita mọ, awọn eeyan n fo lati ori kanta kan sikeji ni banki nitori ko sowo.

"O ni ẹgbọn wa agba to lowo lọwọ daadaa ko da ni kaaṣi ẹgbẹrun mẹwaa lọwọ mọ. Ipo aarẹ wo lo wa n du, ki lo n dupo fun?"

Aarẹ Tinubu ni oun da a lohun lọjọ naa pe ipo aarẹ loun n du, oun ko si tori tirẹ tabi ti ẹgbọn awọn du u rara.

'Ohun tí mo ṣe fẹ́ jáwọ́ nígbà náà gan-an rèé'

Ninu alaye rẹ, Aarẹ sọ pe oun fun ẹbi oun naa ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira to wa gba, ṣugbọn oun pada mọ pe ẹgbẹrun mẹwaa pere lo kan ẹgbọn agba to tori rẹ wa gba owo.

"Lasiko yẹn, diẹ bayii lo ku ki n sọ pe mi o dupo aarẹ mọ. Ṣugbọn ọpẹlọpẹ Aminu Masari ati ẹyin naa ti ẹ ki mi laya.

"Nigba ti mo de Abuja, Masari sọ fun mi pe oun ni alaga ẹgbẹ Ariwa-Iwọ-Oorun, ki n ma ṣiyemeji rara."

Tinubu sọ pe bayii loun ṣe fi ọkan akin gbe e, ti oun si dije.

Ko ṣai sọrọ lori adojukọ ọrọ aje to ni oun ba nilẹ lẹyin toun di aarẹ tan.

Tinubu sọ pe tori ẹ loun ṣe yọ sọbsidi, iyẹn owo iranwọ ori epo lai ro tẹlẹ.

O ni bo tilẹ jẹ pe ko si ninu ọrọ apilẹkọ toun fẹ ẹ ka lọjọ iburawọle, oun ni lati kede lọjọ naa pe sọbsidi ti lọ.