Mọ̀ nípa àbá òfin tó lè mú ọ ṣ'ẹ̀wọ̀n tàbí san fáìní N100,000 tí o bá kọ̀ látì dìbò

Awuyewuye ti wa lori aba ofin kan ti ile aṣofin agba l'Abuja n ṣiṣẹ le lori rẹ, eyi ti yoo mu ni dandan fún gbogbo ọmọ Naijiria to ba ti to ọjọ ori lati dibo, ko maa kopa ninu gbogbo eto idibo orilẹede Naijiria.
Ile aṣòfin agba àti ti aṣoju-ṣofin l'Abuja lo jọ n ṣiṣẹ pọ lori abadofin naa.
Ti aba yìí ba le di ofin, ijiya tawọn aṣofin n gbero fun ẹnikẹni to ba ti to lati dibo amọ to kọ lati ṣe bẹẹ ni ẹwọn oṣu mẹfa tabi fáìní N100,000.
Gẹgẹ bi ohun tàwọn aṣofin n gbero, o ṣee ṣe ki ẹnikẹni to ba kọ lati kopa ninu eto idibo ni Nàìjíríà lọ sẹwọn, kí o si tun san faini N100,000.
SERAP kepe ile aṣofin lati yi aba to fẹ fi kan an nipa f'ọmọ Naijiria lati maa dibo danu
Ajọ SERAP, to n ja fún ẹtọ ọmọniyan, ti wa rọ aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio ati adari ile aṣoju-ṣofin, Họnọrebu Tajudeen Abbas, lati yi aba ofin ti wọn n gbero lati mu ni dandan fawọn ọmọ Naijiria, ti ọjọ ori wọn ba ti to dibo, lati maa dibo ni gbogbo igba.
Ninu iwe ti SERAP fi ṣọwọ si ile aṣofin agba l'Abuja, ajọ naa sapejuwe ìgbésẹ yii gẹgẹ bi eyi to tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
SERAP sọ ninu iwe to kọ si ile aṣofin pe "riran awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti to ibo di ṣugbọn ti wọn ko dibo lọ sẹwọn tako alakalẹ to wa ninu iwe ofin Naijiria àti ẹtọ ọmọniyan lagbaaye."
Ajọ SERAP wa rọ awọn aṣofin lati ṣe atunṣe lori eto idibo orilẹede Naijiria, ki o le maa wu araalu lati dibo.
"Dipo ṣiṣe agbekalẹ ofin ti yoo máa fiya jẹ ọmọ Naijiria ti ko dibo, ni ṣe lo yẹ kí awọn aṣofin yọ ofin to daabo bo awọn gomina ati igbakeji wọn eyi ti ẹnikẹni ko fi le pe wọn lẹjọ lori oye kuro.
Nítorí awọn lo maa n tẹ oju ofin eto idibo mọlẹ lasiko idibo.
Dida eeru siṣe duro lasiko idibo ati wiwa ojutuu si eto abo to mẹhẹ jẹ ọna kan pataki lati le ṣe koriya fawọn araalu ki wọn le máa dibo.
Kii ṣe nipa riran awọn eeyan lọ sẹwọn ni araalu yoo fi maa tu jade dibo, bi ko se ki ijọba pese eto abo to peye ki wọn si dẹkùn awọn agba oloṣelu ti wọn maa n ṣe magomago lasiko idibo."
SERAP ni oun yoo gba ile ẹjọ lọ ti ile aṣofin agba ba le buwọlu abadofin naa.
Ajọ naa tun sọ pe ti ile ba gbe aba ọhun de iwaju Aarẹ Bola Tinubu ti o si buwọlu u, SERAP ni awọn yóò ri pe ofin ọhun ko ni f'ẹsẹ mulẹ ni Naijiria.















