Wo àwọn nǹkaan mẹ́wàá tó yẹ láti ṣe lọ́jọ́ ọdún Eid-el-fitr

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Lónìí, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni ọdún ìtunu ààwẹ̀ Ramadan fáwọn mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bí Sultan ìlú Sokoto, Alhaji Saad Abubakar kéde lálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n pé wọ́n ti rí oṣu Shawwal ní Nàìjíríà.
Èyí túmọ̀ sí pé wẹ̀jẹ wẹ̀mu ti bẹ̀rẹ̀ padà fún àwọn mùsùlùmí lẹ́yìn gbígba ààwẹ̀ fún ọjọ́ mọkàndínlọ́gbọ̀n tí ọgbọ̀n ọjọ́ sì jẹ́ ọjọ́ ọdún Eid-el-fitr.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Islam ṣe là á kalẹ̀, àwọn mùsùlùmí gbọdọ̀ ṣe nǹkan mẹ́wàá yìí lọ́jọ́ ọdún láti mú kí ọdún dùn fún wọn.
Sheikh Nuru Khalid, onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam tó fi ìlú Abuja ṣe ibújókòó ka àwọn nǹkan mẹ́wàá mùsùlùmí nílò láti ṣe lọ́jọ́ ọdún Eid-el- fitr fún BBC
Àwọn nǹkan mẹ́wàá náà nìyí:
- Jẹun kí o tó lọ kí irun Eid
- Ri dájú pé ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ síse oúnjẹ aládùn fún ìdílé rẹ kí ẹ tó lọ kírun Eid.
- Ri dájú pé ó yan Zakat-el-fitr fún aláìní kí o tó lọ kírun Eid.
- Fa irun ara à rẹ bíi irun abíyá àti abẹ́, kí o sì wẹ ìwẹ̀ láti ṣe ìmọ́ra fún Ọlọ́run
- Wọ aṣọ tuntun kí o sì lo àdídùn olóòórùn sí ara lọ sí Eid
- Lọ sí Eid pẹ̀lú gbogbo ìdílé rẹ àtọmọdé àti àgbà, ọkùnrin àti obìnrin kódà àwọn tí kò ní ìrun lẹ́tọ̀ọ́ láti lọ sí Eid.
- Ṣíṣe àfọ́mọ́ sí Ọlọ́run nígbà tí ẹ bá ń lọ kí ìrun Eid títí tí ẹ máa fi dé ààyè ìkírun.
- Ó dára láti dúró gbọ́ wáàsí Imam lẹ́yìn tí ẹ bá kí ìrun Eid tán.
- Gba ọ̀nà mìíràn padà sílé yàtọ̀ sí èyí tó gba lọ sí Eid.
- Ṣe àríyá ní ìwọ̀túnwọ̀nsì láì ṣe àwọn nǹkan tí kò lẹ́tọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ẹbí, ara àti ọ̀rẹ́.











