Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò, dúkìá bàjẹ́ níbi ìjà ilẹ̀ láàrin ìlú Osi àti Epe Opin ní ìpínlẹ̀ Kwara

Ọpọ eyan lo padanu ẹmi wọn nibi ija ilẹ to bẹ silẹ laarin ilu Osi ati Ẹpẹ Ọpin ni ijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara.
Laasigbo naa bẹrẹ ni Ọjọbọ ọsẹ yii, eyi to si yọri si iku tẹgbọn taburo ọmọ iya kan naa ti wọn jẹ ọmọbibi ilu Osi.
Lasiko to n ba BBC yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọgbeni Oyelere ti iṣẹlẹ naa soju rẹ sọ fun sọ pe ija ilẹ laarin ilu Osi ati Ẹpẹ Ọpin ti pẹ.
O fi idi rẹ mulẹ pe l'Ọjọbọ ọsẹ yii ni wahala mii bẹ silẹ lasiko tawọn kan lọ ori ilẹ naa lati lọ ṣiṣẹ nibẹ.
Lasiko ti oun naa n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Ọgbẹni Sunday sọ pe wọn ti ba ọfiisi ajọ eleto abo ara ẹni laabo ilu to wa ni ilu Ẹpẹ Ọpin jẹ, ti ọpọ awọn eyan ilu naa si sa kuro ni ilu ti ọpọ wọn lọ sun ni Isọlo ọpin, Eruku ati awọn ilu mi to wa ni tosi.
O salaye pe ijọba ti ko awọn ọmọ ogun lọ si ilu naa latari ibẹru-bojo to gbalẹ pe ilu Osi fẹ gbẹsan awọn ọmọ wọn ti wọn seku pa.
Nigba ti BBC yoruba pe alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Arabinrin Ejirẹ Adeyemi Toun, o ni oun yoo fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ na laipẹ.
''Gbogbo awọn eleto abo lo tiwa ni ṣepẹ bayii lati daabo bo araalu''
Alukoro ọlọpaa ni awọn kan sọ pe alaga ijọba ibilẹ Ekiti Awẹlẹwa lo n ta epo si ọrọ naa nitori pe o jẹ ọmọbibi ilu Ẹpẹ Ọpin.
Nini ọrọ rẹ, alaga ijọba ibilẹ Ekiti Họnọrebu Awẹlẹwa sọ pe gbogbo igbesẹ to yẹ loun gbe lori iṣẹlẹ na,
O ni oun ko mọ nkankan nipa iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn nitori pe oun jẹ ọmọbibi ilu Ẹpẹ Ọpin ni wọn fi sọ bẹẹ.
Alaga ijọba ibilẹ Ekiti ni wọn ba ọkọ oun naa jẹ, wọn si seku pa awọn eyan.
O fikun ọrọ rẹ pe oun ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti, ati awọn Ọba alaye, pẹlu alaye pe ọrọ ilẹ naa ti wa ni ile ẹjọ tipẹ.
Alaga ijọba ibilẹ naa tun fi kun pe ile meji ni wọn bajẹ, pẹlu alaye pe oun ti fi ọrọ naa to kọmisona ọlọpaa ipinlẹ Kwara leti bakan naa.
Alaga naa ni gbogbo awọn eleto abo lo tiwa ni ṣepẹ bayii, koda, o ni oun o le gba oju-ọna tarata lati jade mọ wi pe kọrọ lon gba.















