Ojú máa ń tì mí, àwọn ọ̀rẹ́ máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí ọyàn kan ni mo ní - Titilope tó lárùn 'Poland syndrome'

Aworan Titilope Akintola
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ai rin jina lai ri abuke ọkẹrẹ, bẹẹ gan an lọrọ ri pẹlu ọdọbinrin Titilope Akintola ẹni to larun tawọn oloyinbo n pe ni 'Poland syndrome' eyi to jẹ ko ni ọmu kan dipo meji ti obinrin maa n ni.

Titilope ranti bi oju ṣe ti i nigba tawọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ wa nile ẹkọ girama mọ nipa bi ọmu rẹ ṣe ri.

Ọdọbinrin naa to baa BBC Pidgin sọrọ ṣalaye pe ojuti lo jẹ foun nigba naa tori awọn akẹgbẹ oun nilẹ ẹkọ bẹrẹ si ni gbe iroyin kiri wi pe ọmu kan loun ni.

Bayii ni Titilope ko ṣe ni igboya lati sọrọ mọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ nile ẹkọ tori ni gbogbo igba ni wọn maa n beere lọwọ rẹ pe ṣe loootọ lo ni ọmu kan.

Iriri yii jẹ ki oju maa ti Titilope debi wi pe o ṣakoba fun ẹkọ rẹ.

Lẹyìn o rẹyin, Titilope pada fi Naijiria silẹ lọ máa gbe lorilẹede Ghana nitori ọrọ naa.

"Iriri ti ko rọrun ni mo ni pẹlu awọn ọrẹ mi tori ohun to sẹlẹ si mi, ni ṣe ni wọn maa n fi mi ṣe yẹyẹ.

Bi wọn ṣe mọ ni pe ọrẹ mi kan lo ri ọyan mi nigba ti mo n wẹ nigba ti a wa nilẹ ẹkọ girama.

Lẹsẹ kẹsẹ ni ọrẹ mi naa beere lọwọ mi pe ṣe ọmu kan ni mo ni.

Bayii ni ọrẹ mi yii lọ sọ fun ẹgbọn rẹ ọkunrin nile wi pe ọyan kan ni mo ni,'' Titilopa lo sọ bẹẹ.

Ẹgbọn ọrẹ rẹ Titilope naa ko ṣe meni ko ṣe meji, lo ba beere lọwọ Titi funra rẹ pe ṣe loootọ lo ni ọmu kan tori ile ẹkọ kan naa ni wọn jọ n lọ.

Titilope ṣalaye pe nigba toun wa n balaga ni bii ọmọ ọdun mẹtala loun ṣakiyesi pe ọmu oun kan n tobi je ekeji lọ.

Titi sọrọ yii fun ibatan rẹ kan tan eyi to sọ fawọn obi rẹ wi pe ki wọn lọ tọju rẹ.

Amọ, si iyalẹnu, awọn obi Titi fi i lọkan balẹ wi pe ọmu keji naa yoo pada yọ nitori wọn o mọ nipa iru arun to ṣokunfa nnkan naa.

'Mo ṣetan lati ṣe ọmu ti mo ba lọwọ'

Aworan Titilope Akintola

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ni Titilope lọ si ile iwosan nibi ti dokita kan ti sọ fun un wi pe arun ''Poland syndrome'' lo ni.

Dokita naa gba a niyanju pe o le fi iṣẹ abẹ ṣe ọmu, bakan naa lo kilọ fun Titilope wi pe ko maa lo fun ayẹwo loorekoore nitori iru arun yii le jẹ ko ni arun jẹjẹrẹ ọyan.

Titilope ni oun ṣetan lati ṣe ọyan pẹlu iṣẹ abẹ ti oun ba ri owo toun le lo.

''Mo fẹ gbe igbe aye to tẹ mi lọrun, mi o si fẹ kawọn eeyan maa fi eebu ara bu mi mọ.

Mi o si tun fẹ kawọn eeyan maa fi mi ṣe yẹyẹ mọ,'' Titilope ṣalaye.

Amọ, Titilope ko ṣai kọminu lori siṣe ọyan nitori akoba to le ṣe nigba to ba bẹrẹ si ni fọmọ lọyan.

Ajọ NIH to n ri si ọrọ eto ilera sọ pe ''Poland syndrome'' jẹ arun kan ti ko wọpọ to maa n ṣẹlẹ si ọmọ ninu oyun.

Ajọ naa ni arun yii maa n fara han diẹ diẹ lati igba ti ọmọ ba ti wa ni ikoko titi ti yoo fi dagba.

Ati obinrin ati ọkunrin lo le ni arun yii, o kan jẹ wi pe lara obinrin lo ti maa n fara han julọ ni.

''Mo ti kọ eti ikun sawọn to n fi mi ṣe yẹye''

Titilope ni ọrọ awọn to n fi oun ṣe yẹyẹ ti di ipakọ o gbọ suti ori ẹlẹgan lo daru foun tori oun ko ri ti wọn ro mọ.

O ni oun ti gba fun Ọlọrun, oun si nifẹẹ ara oun tori pe ohunkohun to wu ko ṣẹlẹ, ko ṣẹni to maa duro ninu gbogbo awọn to n tabuku oun.

''Mo maa n ka ọrọ buruku tawọn eeyan mii kọ nipa mi ti mo si maa bu sẹrin-in.

Nigba mii, mo si tun maa n fi ibinu dawọn lohun,'' Titilope lo sọ bẹẹ.

O ni oun n ṣe ilanilọyẹ fawọn eeyan lori itakun ayelujara nipa arun ''Poland syndrome'' nitori iriri oun nigba toun wa nile ẹkọ girama.