Ọ̀rọ̀ ìwúrí tí Florence Ajimobi sọ láyàájọ́ ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ Abisola, kó tó ò kú lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì

Abilekọ Florence Ajimobi ati ọmọ rẹ, Oloogbe Bisola Kola-Daisi

Oríṣun àwòrán, Florence Ajimobi/ Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ eeyan ni ko mọ pe inu oṣu kẹta ni wọn bi Oloogbe Bisola Kola-Daisi, ọmọ gomina Oyo tele; Abiola Ajimobi to ku l'Ọjọbọ ọsẹ yii.

BBC fidi ẹ mulẹ, pe ọjọ kejila, oṣu Kẹta ọdun 2025 ni ayajọ ọjọọbi ọmọ gomina tẹlẹ naa.

Eyi tumọ si pe ko ti i ju nnkan bii ọsẹ meji lọ lẹyin ọjọọbi ọdun kẹrinlelogoji rẹ lo jade laye.

Lọjọ ayẹyẹ naa ni iya rẹ, Florence Ajimobi, sọ awọn ọrọ iwuri nipa Abisola, ẹni ti i ṣe akọbi ọmọ rẹ.

Ọmọwe Florence Ajimobi ko mọ pe gudugbẹ yoo ja lẹyin ọjọ diẹ to n ki ọmọ rẹ kuu ayẹyẹ ọjọọbi pẹlu ọpọlọpọ adura.

Afi bi ọlọjọ ṣe de lẹyin ọjọ mẹrindinlogun to si mu ọmọ naa lọ.

Báyìí ni ìyàwó Ajimobi sọ nípa ọmọ rẹ láyàájọ́ ọjọọbi Bisola to dagbere faye

Oloogbe Bisola Kola-Daisi

Oríṣun àwòrán, Bisola Kola-Daisi/ Facebook

Loju opo ayelujara Facebook rẹ, Florence Ajimobi, ki Abisola bayii pe:

Ọjọọbi ayọ fun ọmọbinrin mi pataki, Abisola- ọmọ to sọ mi di abiyamọ!

Lonii ọjọ pataki yii, mo dupẹ fun iwọ to o jẹ ẹbun iyanu fun mi. O mu ọpọ ayọ, ifẹ ati imọlẹ wa sinu ẹbii wa.

Bi mo ti n wo ọ to n dagba di eeyan pataki n wu mi lori, o si n jẹ ki n maa dupẹ f'Ọlọrun.

K'Oluwa bu kun ọ gidi, ko tọ iṣisẹ rẹ ko si jẹ ki ayọ, alaafia, ifẹ ati aṣeyọri kun aye rẹ.

Mo gbadura pe Oluwa yoo maa ro ọ lagbara ni gbogbo igba, yoo jẹ ko o maa ri ayọ ni gbogbo asiko, yoo si fun ọ ni igboya lati koju ipenija aye.

Mo si tun gbadura pe ọjọọbi rẹ pataki yii yoo jẹ gbigba adura fun ọ ju bẹẹ lọ. Oluwa ti bu kun fun ọ ju ibi ti o rokan lọ lorukọ Jesu.

Mo nifẹẹ rẹ, mo si dupẹ f'Ọlọrun fun bo ṣe fun mi lanfaani lati jẹ ki n bi ọ bi ọmọ mi obinrin ati akọbi.

Jẹgbadun ayajọ rẹ pataki yii, ifẹ mi, pẹlu irori pe Ọlọrun fẹran rẹ.''

Bayii ni Abilekọ Florence, Iya Bisola sọ nipa ọmọbinrin rẹ to di oloogbe naa.

Ki lo pa Bisola Kola-Daisi?

Oloogbe Bisola Kola-Daisi

Oríṣun àwòrán, Bisola Kola-Daisi/Facebook

Ṣadeede ni iroyin iku naa balẹ gudẹ l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2025.

Gbogbo ori ayelujara kun fun iroyin iku ọmọ Ajimobi, gomina Oyo tẹlẹ.

Bo tilẹ jẹ pe iroyin fidi ẹ mulẹ pe orilẹede United Kingdom lọhun-un ni Bisola dakẹ si , sibẹ, ko sẹni to fidi iku naa mulẹ pato.

Iroyin kan ti a ko le fidi rẹ mulẹ, sọ pe aisan jẹjẹrẹ ọyan lo mu Bisola Kola-Daisi lọ sọrun ojiji.

Awọn ẹka iroyin naa sọ pe o ti ṣe diẹ ti ọmọ Ajimobi ti n koju iṣoro ọhun.

Ati pe arun naa lo da ẹmi rẹ legbodo to fi di oloogbe lẹyin ọjọ mẹrindinlogun to ṣe ọjọọbi.

Àwọn eeyan nla-nla ti n ba ẹbi Ajimobi daro iku Bisola

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Latigba ti iroyin iku naa ti balẹ ni ọpọ eeyan ti wọn jẹ alẹnulọrọ ti n ranṣẹ ibanikẹdun si idile Ajimobi.

Lara awọn eeyan to ti ba ẹbi naa kẹdun ni: Teslim Folarin, ondupo gomina Oyo nigba kan.

Teslim Folarin kọ ẹdun ọkan rẹ pe:

''O ba mi lọkan jẹ gan-an lati gbọ iroyin iku Abilekọ Bisola Kola-Daisi, ọmọ Ajimobi.''

O ni iku ọmọ naa ti baba rẹ jẹ ibatan oun, ti da ọgbẹ ọkan kalẹ, nitori aburu nla ni ki obi gbe ọmọ sin.

Folarin sọ pe bii ọmọ ni Bisola jẹ foun, iku rẹ si jẹ ofo foun naa, gẹgẹ bo ṣe ri fun iya rẹ to bi i.

Awọn mi-in to tun ba ẹbi Ajimobi daro ni Gomina Seyi Makinde, ẹni to ṣapejuwe iku Bisola bii iyalẹnu gidi.

Olamijuwonlo Alao-Akala, ọmọ gomina Oyo tẹlẹ, Oloogbe Alao Akala naa ba wọn kẹdun.

Bakan naa ni Senator Buhari AbdulFatai, ẹni to ṣapejuwe Bisola bii ẹlẹyinju aanu.

O ni bi ọmọbinrin naa ṣe ku lẹyin ọdun diẹ ti baba rẹ ku, jẹ nnkan ibanujẹ ti ko yẹ ko kan ẹnikankan.

Bakan naa ni Olori ile igbimọ aṣofin Oyo, Adebo Ogundoyin ati bẹẹ bẹẹ lọ ti ba ẹbi Ajimobi daro, ikini naa n tẹsiwaju.

Ta a ni Bisola Kola-Daisi?

Oloogbe Bisola Kola-Daisi

Oríṣun àwòrán, Bisola Kola-Daisi/ Facebook

Bisola, ti ọpọ tun mọ si ẹlẹyinju aanu jẹ gbajumọ lawujọ awọn oniṣowo lorilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni oju opo LinkedIn rẹ, oun ni Oludari Agba fun ileeṣẹ Grandex Nigeria Limited, ileeṣẹ karakata kan ti iroyin sọ pe o jẹ ti iya rẹ, Florence Ajimobi.

Bakan naa ni iroyin sọ pe o jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Florence H, ile itaja aṣọ ati bata.

Orukọ inagijẹ ti ọpọ mọ Abisola si ni Abi-KD nigba aye rẹ.

Loootọ, ilu Eko ni wọn bi Abisola si, amọ, ilu California lorilẹede Amẹrika lo dagba si nibi to ti kẹkọọ gboye ninu imọ eto iṣuna ni ile ẹkọ giga fasiti ipinlẹ California to wa ni Northridge.

Abisola ti figba kan ri ṣiṣẹ nile ifowopamọ, bakan naa lo tun ṣiṣẹ nile iṣẹ epo rọbi ati ile iṣẹ to n ri si kiko ọja wọle ati jade pẹlu ọkọ oju omi.

Lẹyin ti Abisola ṣiṣẹ lọkan o jọkan ile iṣẹ tan ni o bẹrẹ iṣẹ iṣe ara loge to yan laayọ gan an.

Ṣaaju ki o to lọ si orilẹede Amẹrika ni Abisola ti kọkọ lọ ile ẹkọ British School ni Lome lorilẹede Togo nibi to ti kẹkọọ nipa sisọ ede Faranse.

Abisola tun kẹkọọ gboye MBA nile ẹkọ giga fasiti lorilẹede United Kingdom, koda, arabinrin yii ti ọpọ mọ si ẹlẹyinju aanu tun gboye keji nile ẹkọ giga Havard Business School lorilẹede Amẹrika lọdun 2022.

Abisola ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọga agba nile iṣẹ Victoria's Secret lẹyin to pari ẹkọ rẹ lorilẹede Amẹrika, ki o to pada wale fun eto agunbanirọ ni Naijiria lọdun 2008.

Gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu ti ọpọ eeyan mọ ọ si, Abisola da ajọ AKD Foundation silẹ eyi to n lo lati ṣaanu fawọn ọmọ alainiya atawọn ọmọ to n rin igboro kiri lai nile ni Naijiria.

Ẹwẹ, ẹni to jẹ minisita fun eto owo iṣuna ati eto ijọba ni Naijiria, Atiku Bagudu, yan an oloogbe Abisola sipo gẹgẹ bi oludamọran pataki fun un.

Ipo naa lo si wa titi to fi ku.