Inú wa dùn sí bí Gómìnà Makinde ṣe fààyè gba kóòtù Sharia bàyíì l'Oyo - Muric

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Lodi si iroyin to jade lati ọfiisi Akọwe iroyin fun Gomina Seyi Makinde laipẹ yii, nibi ti ijọba Oyo ti ni oun yoo gbe ijokoo Sharia ti wọn bẹrẹ nipinlẹ naa lọ sile ẹjọ, Seyi Makinde ti ni ọrọ ko ri bẹẹ mọ.
Ṣaaju ni iroyin ti sọ pe igbimọ Sharia kan ti n gbọ ẹjọ ni mọṣalaaṣi nla to wa l'Akesan, niluu Oyo.
Ijọba si sọ pe oun yoo gbe e lọ si kootu lati yanju ọrọ naa labẹ ofin ni.
Ṣugbọn ninu fidio kan to tẹ BBC lọwọ bayii, Gomina Seyi Makinde ti sọ pe ero ọkan oun kọ ni iroyin akọkọ naa.
O ni ẹni to ba nifẹẹ si igbimọ Sharia l'Oyoo le gbe ẹjọ lọọ ba wọn bayii, ki wọn si ba a yanju ẹ.
Lóòótọ́ ni mo ti sọ ohun tó jọ pé mò ń lọ sílé ẹjọ́ tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ báyìí- Gomina Seyi Makinde
Nigba to n ṣalaye ninu fidio naa, Gomina Seyi Makinde sọ pe oun ri i ninu iwe iroyin pe, oun fẹẹ lọ si kootu lori idasilẹ ofin Sharia nipinlẹ Oyo.
''Loootọ ni mo ti sọ ohun to jọ bẹẹ tẹlẹ, ṣugbọn ko ri bẹẹ mọ bayii.
'' Ohun ti mo n wi bayii ni pe ohunkohun to ba wa ninu ofin ilẹ wa, a maa ṣatilẹyin fun un.
''Oju temi fi wo ọrọ yii ni pe koda ninu ẹbi wa, ki i ṣe gbogbo nnkan ni a n gbe lọ si kootu.
''Awọn eeyan le ni ede aiyede ninu ẹbi, awọn agba ninu ẹbi naa a ba wọn da si i.
''Fun ti igbimọ Sharia yii, oju temi fi wo o ni pe ẹni to ba fẹẹ gbe ẹjọ lọọ ba wọn, boya wọn jẹ Musulumi tabi wọn ki i ṣe Musulumi, ti wọn ba ti ri i bii ọna abayọ lori ọrọ wọn, ki wọn lọọ ba wọn.
''Yoo ran ijọba lọwọ, yoo jẹ ki ẹjọ tawọn adajọ wa n da dinku. Fun idi eyi, a maa faramọ ilana igbẹjọ mii to le yanju ọrọ.
Ohun kan ti mo kan le sọ ni pe to ba di abala ka fi ofin mu eeyan, awọn ti kootu fiṣẹ naa le lọwọ ni wọn le ṣeyẹn''
Bẹẹ ni Gomina Seyi Makinde wi.
Èrò aráàlú ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Latigba ti gomina ti sọrọ yii ni o ti n fa ariyanjiyan lori ayelujara.
Idi ni pe bawọn kan ṣe n pe Gomina Makinde ni ẹni ti ko lagbara lati ja fun ẹtọ rẹ, bẹẹ lawọn kan n sọ pe ohun to daa ju lo ṣe.
Awọn eeyan kan n sọ pe Sharia to le fa wahala fun ilẹ Yoruba ni gomina faaye gba.
Bẹẹ la ri awọn ti wọn ni gomina fi aaye gba ohun ti ofin sọ ni, ati pe eyi lo daa ju.
A kò fẹ ki Kristẹni gbé ẹjọ wa si igbimọ Sharia, Musulumi nìkan ló wà fún- MURIC

Oríṣun àwòrán, Isiaq Akintola/Facebook
Ọkan lara awọn to n lewaju ninu ibeere fun Sharia nilẹẹ Yoruba ni Ọjọgbọn Isiaq Akintola tawọn eeyan mọ si MURIC. (Muslim Right Concern).
BBC kan si Akintola lati mọ ohun to kan bayii ti Gomina Makinde ti faaye gba Sharia nipinle Oyo.
Ninu alaye ti ajafẹtọọ ẹsin Islam naa ṣe lo ti ni:
''A dupẹ gan-an lọwọọ Gomina Seyi Makinde, inu wa ni MURIC dun si i gan-an.
'' A o kuku nija pẹlu ijọba, ohun ta n beere naa ni ẹtọ, ki wọn ṣe deede fun Musulumi ati Kristẹni, nigba ti wọn si ti da wa lohun bayii, inu wa dun si i gan-an.
''Nigba ti gomina kọkọ sọ pe ko si Sharia ninu ofin ilẹ yii, o dun wa gan-an. Bii ẹni to n fi ẹtọ eeyan dun eeyan ni.
''Ṣugbọn ofin Sharia ko si fun Kristẹni, ko si fun ẹni ti ko ba n ṣe Musulumi, nitori Kristẹni ko gbọ agbọye Kurani, a o si gbọdọ lo ofin rẹ fun un.
''A o fẹ ki Kristẹni wa sile ẹjọ Sharia. Ko ba ofin wa mu, a o gbọdọ gbe Kristẹni wa sibẹ.
''Koda, ti Musulumi ati Kristẹni ba ja, Musulumi ko gbọdọ gbe ẹjọ rẹ lọ sile-ẹjọ Sharia, nitori ẹni yẹn ki i ṣe Musulumi
''Nigba to ba ya nisinyi, wọn aa ni wọn ti n ko awọn Kristẹni lọ sile ẹjọ Sharia, wọn aa dẹ mu ẹri wa bi wọn ṣe sọrọ.
''Ẹ jẹ ki awa musulumi lo ofin wa funra wa, ibi yoowu ti a tile maa jokoo nilẹẹ Yoruba, Musulumi nikan lo wa fun, ki i ṣe fun Kristẹni tabi ẹlẹsin miran.
Àwọn ẹjọ́ tí a o maa gbọ nile ẹjọ Sharia
Nigba to n ṣalaye nipa iru ẹjọ ti wọn yoo maa gbọ ni kootu Sharia, Ọjọgbọn Akintola sọ pe:
''Ẹjọ nla-nla ni ti awọn ole ati janduku, a ko ti i beere fun iyẹn lati maa gbọ, tabi ti awọn oniṣina.
''Ohun ta a fẹẹ maa gbọ bayii ni awọn ẹjọ bii fifi ilana Sharia pin ogun oku to ba ku.
''Bi baba ba niyawo mẹta, to fun ẹyọkan loruka. Ofin alakọwe; (Common Law) yoo sọ pe oloruka lo ni gbogbo ogun ati owo to wa ni banki.
''Bẹẹ ofin Sharia yoo fun gbogbo iyawo ati awọn ọmọ , lai si iyanjẹ.
'' Ko si orijori ninu Islam, iya ọlọmọ kan aa gba ogun tiẹ, ọmọ kan to bi yoo gba tiẹ.
'' Iya to bimọ mẹfa yoo gba tiẹ, awọn ọmọ kọọkan to bi naa yoo gba tiwọn ni.
Bi Islam ṣe pin in niyẹn.
''Boya ẹnikan gbeṣẹ fun oniṣẹ ọwọ ti ko sanwo rẹ fun un, a maa fi ofin Sharia sọ ọ pe ko lọọ san owo rẹ fun un.
Igbẹjọ lọkọ-laya naa wa ninu ẹjọ ti wọn n gbọ ni kootu Sharia.
Awọn nnkan ta a fẹẹ maa fi Sharia ṣe niyẹn.''
Akintola sọ pe ibi yoowu ti wọn ko ba ti maa lo ilana ofin Sharia nilẹẹ Yoruba, ki i ṣe lati fi da wahala silẹ rara.
'Sharia ko lagbara lati fi ofin mu ẹni ti wọn ba dajọ fun'

Oríṣun àwòrán, @MURIC
Gẹgẹ bi oludasile MURIC ṣe wi, ko si agbara kankan fun kootu Sharia lati mu, tabi fiya jẹ ẹni ti wọn ba dajọ fun.
''Niwọn igba to ti jẹ pe Kurani ni wọn fi n dajọ ni kootu Sharia, ko si agbara ofin kankan to le mu ẹni ti wọn dajọ fun.
''Ohun kan to kan wa nibẹ ni pe wọn yoo ka ohun ti iwe mimọ wi si i leti.
Won yoo fi i silẹ lati huwa ẹrusin to bẹru Oluwa, ti yoo si tẹle aṣẹ naa.
''Bi ko ba tẹle e, Ọlọun lo n tapa si i.''
Bẹẹ ni oludasilẹ ajọ MURIC naa wi.














