Kí ló n fa ikọ́ọfe àti pé báwo lo ṣe le dènà rẹ̀?

Aworan awọn eeyan to lo ibomu, ti wọn jokoo tẹle ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbogbo ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta ọdun ni ayajọ ikọọfe (Tuberculosis) kaakiri agbaye.

Akori ti wọn fun arun naa fun ọdun 2025 ni: 'Yes! We Can End TB: Commit, Invest, Deliver'

Arun ikọọfe jẹ ọkan gboogi lara awọn ailera to maa n ṣakoba fun ẹdọforo lara awọn to ba lugbadi rẹ.

Kokoro aifojuri kan lo maa n fa arun yii, eyi ta a mọ si 'Mycobacterium tuberculosis.'

Yatọ si ẹdọforo, o tun maa n ṣe akoba fun kindinrin, egungun ẹyin ati ọpọlọ eeyan.

Oríṣi méjì ikọ́ọfe ló wà

Aworan igba aya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu alaye tawọn onimọ sayẹnsi ṣe, meji ni ikọọfe pin si.

Akọkọ ni eyi ti ki i ran ta a mọ si Latent TB, ti ikeji si jẹ eyi to maa n ran ka.

Ẹni to ba ni eyi ti ki i ran yii ki i ṣe afihan apẹẹre kankan, koda o le ma rẹ iru ni bẹẹ bo ṣe maa n rẹ ẹni to ba ni ikọọfe.

Ko wọpọ ki ẹni to ni iru ikọọfe yii ko o ran ẹlomiran.

Pupọ awọn to ni iru ikọ yi, ayẹwo ẹjẹ tabi awọ wọn lo le fi han pe wọn ni ikọ naa.

Ṣugbọn itọju ṣe pataki fun iru ẹni bayii, ki ikọ to ni naa ma baa di ohun ti yoo tan kaakiri.

Bi wọn ko ba gba itọju to peye, ida marun-un si mẹwaa awọn to ni ikọọfe yii lo le pada waa ni ikọọfe gangan lọjọ iwaju.

Ikọ́ọfe ojúlówó

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu awọn apẹẹrẹ to maa n ṣe afihan pe eeyan ni ikọọfe ni pe yoo maa hukọ ẹjẹ, aya aa si maa ta iru eeyan bẹẹ.

Irufẹ awọn to ni iru ikọ yii aa maa ru, wọn aa maa laagun lalẹ, iba aa maa daamu wọn pẹlu otutu, yoo si maa tete rẹ wọn.

Itọju wọn maa n gba to nnkan bii oṣu mẹfa, ti wọn aa si maa fun wọn ni oriṣiiriṣii oogun lati fi koju ikọ yii.

Ikọọfe jẹ ọna kan gboogi to n fa iku awọn to ni aisan HIV, iyẹn arun ko-gboogun.

Awọn to ba ni itọ ṣuga naa wa ninu ewu ikọọfe.

Inu afẹfẹ lawọn eeyan n gba ko ikọọfe

Bi eeyan ba sin lẹgbẹẹ rẹ, to hukọ, to sọrọ tabi to kọrin, ti ẹni bẹẹ ba ni ikọọfe, o le gbabẹ tan kokoro aifojuri ikọ yii ka, ko si ṣe bẹẹ maa ràn.

Bi eeyan ba pin ounjẹ tabi to fọwọ kan awo ile igbọnsẹ, ko le tibẹ ko ikọọfe.

Lọdun 2019, nnkan bii miliọnu mẹwaa eeyan lagbaye lo ko ikọọfe, awọn miliọnu 1.4, to fi mọ awọn to ni HIV si padanu ẹmi wọn lati ọwọ ikọ yii.

O kere tan, eeyan biliọnu meji, ida kan iye eeyan to wa lagbaye, ni wọn ni ikọọfe eyi ti ki i foju han.

Naijiria ati ikọ́ọfe

Aworan nọọsi to n fun ẹni to nawọ si i loogun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọdọọdun ni Naijiria, o maa n to eeyan 245,000 to maa n padanu ẹmi wọn lọwọ ikọọfe .

Awọn to maa n ṣẹṣẹ lugbadi rẹ si to nnkan bi 590,000.

Ninu onka yi, awọn to ni HIV ninu wọn a si maa to 140,000.

Ni akọsilẹ, TB ko ida mẹwaa ninu ida ọgọrun-un aisan to n ṣeku pa awọn eeyan ni Naijiria.

Ǹjẹ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára wà fún ikọ́ọfe?

Ajọ ilera lagbaye (WHO) gba awọn eeyan nimọran lati gba abẹrẹ ajẹsara BCG nigba ti wọn ba ṣi wa ni ikoko.

Ni orileede Naijiria to se pe aarun yii peleke, kete ti wọn ba ti bi ọmọ ni wọn ti maa n gba a fun wọn nile iwosan, ki ọmọ naa ma baa ṣalabapade kokoro to n fa ikọ yii.

Awọn to wa ninu ewu ati ko ikọọfe ni awọn ọmọde to n gbe nibi ti ẹni to ni ikọ naa wa.

Pẹlu awọn eeyan mi-in naa ti wọn ba ni ẹbi ti ikọ naa n da laamu nitosi wọn.

Awọn orilẹede ti akọsilẹ wa pe ikọọfe ti pọ ni:

Africa - paapaa julọ, sub-Saharan Africa ati Iwọ Oorun Africa ( West Africa)

Guusu Asia - India, Pakistan, Indonesia ati Bangladesh

Russia

China

South America

Vietnam, Cambodia ati Philippines