Dupe Jayesinmi, oṣere tiata, fomijé ṣàlàyé ìdí tí kò ṣe lọ́mọ láyé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún

Oríṣun àwòrán, Dupe Jayesinmi/ Facebook
Odu ni oṣerebinrin tiata nni, Modupe Adetoun Jayesinmi Kazeem, lagbo oṣere.
Ọkan ninu awọn tawọn eeyan bọwọ fun un daadaa nibi iṣẹ naa ni.
Ko sẹni to mọ ibi ti bata ti n ta iya to ti le lọgọta ọdun (60) naa lẹsẹ, afi nigba to fi omije ṣalaye ibanujẹ rẹ nipa aibimọ ati awọn iṣoro mi-in.
Ori eto oṣere tiata, Biola Bayo ti a mọ si Talk-To-B ni Dupe Jayesinmi ti fi omije sọ pe:
''Mo ṣe igbeyawo lọjọ Kejilelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 1988.
Mo fi oyun ṣegbeyawo ni, ṣugbọn lẹyin ọsẹ diẹ ti mo ṣegbeyawo ni oyun yẹn walẹ.
'' Lẹyin igba yẹn, mi o ri oyun ni mọ. "

Oríṣun àwòrán, Talk-To-B
''Ọsẹ keji ti mo kuro nile ọkọ mi ni iyawo mi-in wọle pẹlu oyun ninu"
Dupe Jaiyesinmi tẹsiwaju pe "Mo gbiyanju titi, Dokita waa sọ fun mi pe wọn maa ṣe itọju kan fun mi ti wọn maa fi ṣi ara mi, ṣugbọn wọn ni mo gbọdọ sun mọ ọkọ mi lẹyin rẹ.
''Ọsẹ meji ni ọkọ mi maa n lo nibi iṣẹ, mo sọ fun un pe wọn fẹẹ ṣe iṣẹ abẹ fun mi, ṣe o maa tete de ka le ṣunmọ ara wa, o si ni oun maa tete de.
''Wọn ṣiṣẹ abẹ naa fun mi tan, ọkọ mi o wale. Oṣu kẹta lẹyin to ti yẹ ka ṣere lo too de.
''Mo lọ s'Ekoo ki wọn le ba mi pe e lorii foonu, ko si foonu nigba yẹn, ko da mi lohun.
''Igba to de ti mo binu, o ni ti ko ba tẹ mi lọrun ki n kẹru mi jade. Igbeyawo wa ti pe ọdun marun-un nigba yẹn.
Ti a ba jọ sun, niṣe lọkọ mi maa fi pilo da bẹẹdi si meji, ko ni i jẹ ki ara rẹ kan temi.
''Nigba to su mi ni mo kẹru mi jade nile rẹ, igbeyawo naa tuka.
''Mo kuro ninu ile ọkọ mi ni lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila ọdun 1995.
''Ọsẹ keji ti mo kuro nile rẹ ni iyawo mi-in wọle pẹlu oyun ninu.
Igba ti mo ko dele oniyara mẹta ti mo gba lẹyin ti mo kuro nile ọkọ mi, mo sunkun titi nigba ti mo n wo ara mi lemi nikan.

Oríṣun àwòrán, Talk-To-B
"Mo pàde Àláàjì to fẹran mi gidi, mo loyun fun un, oyun bọ si ẹyin ile ọmọ, iyawo rẹ tun gbogun ti mi"
Nigba to n tẹsiwaju, Dupe Jayesinmi sọ pe oun pade Alaaji kan lẹyin toun fi ọkọ oun silẹ.
''Alaaji fẹran mi, o gbiyanju fun mi, o duro bii ọkọ, o ba mi sare ki n le bimọ.
''Laaarin ẹ, mo ṣaa bẹrẹ si i ri ẹjẹ, bẹẹ ni mo n ni inira nikun mi. Mo pe nọọsi, o ni ki n lọ si ọsibitu.
''Dokita sọ fun mi pe mo loyun ni, inu mi dun gidi.
''Aṣe ẹyin ile ọmọ ni oyun naa wa, ko sohun ti wọn le ṣe si afi ki wọn gbe oyun naa kuro.
''Mo sunkun kikoro, mo siregun si Ọlọrun, mo ni iru oore ẹdẹ wo lo ṣe fun mi yii, Ọlọrun. Mo dẹ ti pe ẹni ogoji ọdun nigba yẹn.
''Alaaji tiẹ tun ni ki n ṣi jẹ ka gbiyanju si i, ṣugbọn iyawo ẹ to wa niluu oyinbo tun bẹrẹ si i gbogun ti mi. To ba ji laaarọ to pe Alaaji bayii, epe lo maa maa ṣẹ.
''Wahala yẹn ti pọ ju fun mi, baba mi dẹ ti ni ki n ma ba eeyan ja si nnkan mẹta: Ogun, owo ati ọkunrin, nitori ẹ ni mo ṣe fi Alaaji silẹ, ti mo ni ki wọn maa lọ.
Latigba naa, mi o gba ọkunrin kankan laaye laye mi mọ, nitori irọ lo pọ, awọn to ti fẹẹ gba pata nidii eeyan tẹlẹ ti wọn n gbori wọle.
"Mo pe ẹni ọgọta ọdun, mi o rọmọ ba mi ṣe ọjọọbi, owo ara mi ni mo fi dana ounjẹ, mo lọọ gba yara si otẹẹli, mo fi ọjọ yẹn sunkun ni"
Gẹgẹ bi oṣere tiata yii ṣe fomije ṣalaye, o ni lọjọ toun pe ọgọta ọdun (60) toun ko ri ọmọ ba oun ṣajọyọ, ti ko sẹni kan to foun ni nnkan kan, omije tun bọ rẹpẹtẹ.
''Tawọn eeyan ba fẹẹ ṣe ọjọọbi, ṣebi mo maa n ri i pe awọn ọmọ lo n ṣe e fun wọn, emi pe sisti, mi o rọmọ ba mi sẹ e.
''To ba jẹ pe emi naa tete bimọ lasiko, ṣebi awọn ọmọ mi lo maa pate ayẹyẹ fun mi.
''Gbogbo awọn ọmọ aburo ti mo tọ, wọn ko fun mi ni pinni(pin) lọjọ ti mo pe 60.
''Owo ara mi ni mo fun wọn pe ki wọn fi se ounjẹ ti wọn ha laduugbo.
''Mo kuro nile lọjọ naa, mo lọọ gba yara kan si otẹẹli, mo sunkun ti mi o le sun nita lojuu gbogbo aye.
''Ṣe ọmọ ti mo tọ to di ọjọ igbeyawo ti iya rẹ ni mi o le jokoo ṣe iya ni mo fẹẹ sọ ni, abi tawọn aburo mi ti wọn gbogun nitori ogun ti baba wa fi silẹ.
Ohun to kan dun mi ni ti iya mi ti ko jẹ ki n gba ọmọ tọ (Adoption).
''Niṣe ni iya mi sọ pe oun maa rọ ọmọ ọmọ ti mo ba gba tọ pa.
''Gbogbo ọjọ ti lọ tan, ṣugbọn mo nigbagbọ pe oku mi o ni i rare.
''Ko sẹni to ku ti wọn ju oku rẹ si titi ri, ti wọn ni ki lo de, kaye waa ni nitori ko bimọ ni.
Mi o sọrọ ara mi sita bayii ri, ọpọ eeyan ni ko mọ pe mi o bimọ, ṣugbọn mo pinnu lati wa sori eto yii, nitori eto ọmọ mi ni.
''Mo kẹkọọ ninu ohun to ṣe mi, mo si fẹ kawọn eeyan kọ ẹkọ lara mi pẹlu.
''Bi o ba n wa ọmọ gẹgẹ bii obinrin, ma jẹ ki ọkunrin parọ gba pata nidi ẹ, opurọ lo pọ ju.
''Boya ka ni mo gba ile sita lẹyin ti mo kuro lọdọ Alaaji, ti mi o lọọ gbe pẹlu iya mi, boya mi o ba ti gba ọmọ tọ tipẹ.
''Ohun ti mo ṣaa fẹ bayii ni pe ki n ri ọmọ kan ti ko ti i dagba ju, ti mo le maa mu jade, ti maa mu lọ sileewe, tawọn eeyan aa maa ri pẹlu mi, bii ọmọ ọdun mẹfa.''
Bẹẹ ni Dupe Jayesinmi wi














