"Kò rọrùn rárá láti gbaradì fún ìdíje ìrin oge Guiness World Record, N80m ló ná mi"

Àkọlé fídíò, "Kò rọrùn rárá láti gbaradì fún ìdíje ìrin oge Guiness World Record, N80m ló ná mi"
"Kò rọrùn rárá láti gbaradì fún ìdíje ìrin oge Guiness World Record, N80m ló ná mi"

Yoruba ni ohun to n wu ni, lo n pọ lọrọ ẹni, bi ọrọ omidan Ololade Ayelabola, tii se arinrin oge se ri ree.

Ololade yii lo gba ami ẹyẹ arinrinoge to le rin julọ lagbaye ti Guinness World Record lẹyin to pari irin ẹgbẹrun mejin ati mejidinlọgọta.

Irin yii si lo pọ ju afojusun Ololade lọ tori kilomita ọgọfa lo pinnu lati rin saaju idije naa.

Ni kete to gba ami ẹyẹ arinrinoge to le rin julọ lagbaye ti Guinness World Record, Ayelabola bẹrẹ si rinrin oge lati se afihan ọpọ awọn asọ igbalode fawọn aransọ igbalode lorilẹede yii.

Bakan naa lo safihan awọn asọ lati ẹka ti wọn ti n kọ nipa ere itage ni fasiti Eko, eyi to n tọkasi ẹbun atinuda ati iyapa lorisirisi ni ẹka oge sise ni orilẹede Naijiria.

Lẹyin to gba ami ẹyẹ yii tan, Ọlọlade ba BBC Yoruba sọrọ nipa bi idije naa se waye, igbaradi rẹ fun idije naa, iye to na lori ididje ọhun ati bo se bori nibi idije naa.

Ololade Ayelabola

"Awọn dokita ati Nọọsi se ayẹwo ara mi, wọn ko oogun fun mi, se atungbeyẹwo awọn ounjẹ ti mo n jẹ"

Ololade Ayelabola, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ko rọrun rara lati gbaradi fun ami ẹyẹ arinrinoge to le rin julọ lagbaye ti Guinness World Record.

"Igbaradi naa gba omi ati ẹjẹ ara mi, koda o gba owo to to ọgọrin miliọnu naira lọwọ mi lati mura silẹ fun irinajo ọjọ marun ti a se yii.

Osu mẹfa ni emi ati awọn ti a dijọ n sisẹ pọ fi gbaradi fun idije naa nitori pe kii se irin to rọrun rara.

Awọn dokita ati awọn Nọọsi se ayẹwo ara mi, wọn ko oogun fun mi, ti wọn si tun se atungbeyẹwo awọn ounjẹ ti mo n jẹ.

Wọn yọ awọn kan kuro, wọn fi awọn ounjẹ miran si, ki ara mi le wa letoleto lati rin irin oge ti mo fẹ rin naa."

Ololade Ayelabola

"Wọn sọ fun mi nibi ami ẹyẹ kan pe mo rin daadaa amọ mo kuru"

Ololade sisọ loju rẹ pe igbaradi fun idije ami ẹyẹ arinrinoge to le rin julọ lagbaye ti Guinness World Record naa bẹrẹ ni ọdun to kọja lẹyin to ti gba ami ẹyẹ mẹta.

"Wọn sọ fun mi nibi ami ẹyẹ kan pe mo rin daadaa amọ mo kuru.

Mo wa ro ninu ọkan mi pe orisirisi awọn eeyan ni wọn ti gbọ iru ọrọ ijakulẹ bayii lori nnkan ti wọn fẹ da laye, ti yoo si ti da omi tutu si wọn lọkan.

Irufẹ eeyan bẹẹ le gba kamu, ko si ma tẹsiwaju lati se amusẹ afojusun rẹ mọ

Idi ti mo se gunle idije naa niyẹn."