Orúkọ ọmọ Nàìjíríà míì tún wọ ìwé ìtàn Guinness World Records fún ṣíṣe wíìgì tó gùn jùló ní àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Helen Williams/Instagram
Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe ń tiraka àti làkàkà káàkiri àgbáyé láti fitàn balẹ̀ pẹ̀lú àjọ Guinness World Records, ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tún ti fìtàn tuntun balẹ̀.
Helen Williams, ní ìpínlẹ̀ Eko fìtàn balẹ̀ nípa ṣíṣe wíìgì tí wọ́n fi ọwọ́ ṣe tó gùn jùlọ ní àgbáyé.
Àjọ Guinness World Records nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi sórí ẹ̀rọ X wọn ní ọjọ́ mọ́kànlá ni Helen lò láti fi ṣe wíìgì tó gùn ní ìwọ̀n 351.28 mítà.
Bákan náà ni wọ́n ní Helen ná owó tó lé ní mílíọ̀nù méjì náírà láti fi ṣe wíìgì ọ̀hún.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Helen lo koto kẹ̀kẹ́ èyí tó fi fìlà àti nẹ́ẹ̀tì sí láti fi ṣe wíìgì náà tó sì irun ẹgbẹ̀rún kan, ìparun méjìlá àti gílúù márùndínlógójì láti fi ṣe wíìgì ọ̀hún.
Ó ní láti bí ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn ni òun ti ń ṣe wíìgì, tí òun sì máa ń ṣe tó àádọ́ta sí ọ̀ọ́dúnrún wíìgì lọ́sẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé ṣíṣe wíìgì náà kò rọrùn fún òun bí ó ṣe jẹ́ pé láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni òun ti ń fi ṣe iṣẹ́ ṣe.
Ó sọ fún Guinness World Record pé òun fẹ́ jáwọ́ nígbà tó dé àárín kan àmọ́ àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ tó yí òun ká kò jẹ́ kí òun kó àárẹ̀ ọkàn.
Helen ni orúkọ rẹ̀ ń wọ ìwé àwọn tó ṣe nǹkan tó tayọ ní àgbáyé ní ọdún kan náà tí ọmọ Nàìjíríà, Hilda Baci tó jẹ́ alásè náà se oúnjẹ fún ìgbà tó pẹ́ jùlọ.
Hilda Baci di gbajúgbajà lẹ́yìn àsè ọ̀hún àmọ́ tí alásè mìíràn láti orílẹ̀ èdè míì ti gba ipò náà mọ́ Hilda lọ́wọ́ báyìí.















