Kò sí ọ̀wọ́ngógó Naira, àwọn èèyàn ló ń kó owò Naira pamọ́ – CBN

Oríṣun àwòrán, The Cable
Banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN ti ṣe ikilọ fun awọn to n ko owo Naira pamọ eyi to ti mu ki riri owo Naira gba le bayii.
Kaakiri awọn ilu nalanla kan lorilẹede Naijiria, ati ri owo naira gba nigboro ti n di ogun pẹlu bi ọpọlọpọ awọn oju ẹrọ ipọwo ATM ti ṣe gbofo ti awọn eeyan ṣi n lọgun irora airi owo Naira gba.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, adari akoso awọn ẹka ni banki apapọ orilẹede Naijiria, Shehu Alhaji Goringo ti fi ọkan araalu balẹ pe lati ọdọ Banki apapọ Naijiria, CBN owo Naira n jade, bẹẹni ko si idi fun ọwọngogo Naira nibikibi lorilẹede Naijiria.
Shehu Goringo ni oun to ku ni fun ki awọn eeyan dẹkun fifi waduwadu gba owo jọ lati inu banki.
O ni gẹgẹbi aṣẹ ti ile ẹjọ to ga julọ gbe kalẹ ninu idajọ rẹ laipẹ yii, igba , awọn ẹẹdgbẹta ati ẹgbẹrun kan naira olodindi atijọ yoo ṣi wa fun nina pẹlu awọn tuntun titi di igba ti wọn ba parẹ.
O ni ko si gbedeke fun nina awọn owo wọnyii bẹẹni iye owo to to na wa fun araalu lati na ni Naijiria.
Bakan naa ni adari agba ni banki apapọ Naijiria naa tun rọ araalu lati maa lo awọn ọna isanwo igbalode miran titi kan lilo ẹrọ ibanisọrọ wọn lati san owo.
Kò síbẹ̀rù, ẹ máa ná owó náírà àtijọ́ papọ̀ mọ́ tuntun lọ - Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti dájọ́ pé kí àwọn ọmọ Nàìjíríà máa ná owó náírà àtijọ́ ìyẹn igba náírà (200), ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà (500) àti ẹgbẹ̀rún kan náírà (1,000) láìsí gbèdéke lórí rẹ̀ mọ́.
Ilé ẹjọ́ náà ní kò sí gbèdéke ìgbà tí owó náà kò ní jẹ́ gbígbà mọ́ pé àtòhun àti tuntun tí yóò máa jẹ́ níná.
Wọ́n ní ó dìgbà tí ìjọba bá ti pèsè owó tuntun náà lọ́pọ̀ yanturu, tí wọ́n sì fẹnukò pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ni kí wọ́n tó kó àwọn owó àtijọ́ náà nílẹ̀.
Ìgbìmọ̀ adájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́sàn-án tí Adájọ́ Inyang Okoro ṣaájú rẹ̀ ló gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ lórí ẹjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ pè láti bèèrè fún àlékún ọjọ́ lórí ìgbà tí àwọn owó náà yóò máa jẹ́ níná dà.
Bákan náà ni ìjọba àpapọ̀ tún bèèrè lọ́wọ́ ilé ẹjọ́ láti yí ìdájọ́ tó gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kẹta oṣù Kẹta nítorí ó pọn dandan láti pèsè àwọn owó tuntun náà lọ́pọ̀ yanturu èyí tó máa tó ná kí wọ́n tó kó tàwọn àtijọ́ kúrò nílẹ̀.
Nínú ẹjọ́ tí agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà, Lateef Fagbemi pè ṣàlàyé pé tí ilé ẹjọ́ kò bá sún gbèdéke náà síwájú, ó ṣeéṣe kí àwọn ọmọ Nàìjíríà tún kojú ìṣòro tí wọ́n kojú lásìkò tí wọ́n kọ́kọ́ kó àwọn owó náà nílẹ̀.
Ó ní àwọn kan tún ti ń kó owó tuntun náà pamọ́ ní ìrètí pé owó àtijọ́ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́ tó bá máa fi di ìparí ọdún yìí.
Ní ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kọkànlá ni ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, CBN ti kéde pé kò séwu kí àwọn ọmọ Nàìjíríà máa ná owó náírà àtijọ́ lọ.
Ọmọ Nàìjíríà, ẹ máa náwó náírà àtijọ́ lọ, kò séwu - CBN

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Banki apapọ ilẹ Naijiria (CBN) ti kede pe ko si gbedeke fun ninu owo naira atijọ ti i sẹ ọgọrun-un kan, (N100) igba (N200) ati ẹẹdẹgbẹta naira(N500) mọ, CBN ni ki araalu maa na owo naa lọ pẹlu tuntun lai ni gbedeke igba kankan.
Ṣaaju ni banki apapọ ti kede lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa ọdun 2022, pe oun yoo paarọ awọn owo naa si tuntun, opin yoo si de ba nina tatijọ lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2023 yii.
Ṣugbọn lọjọ Iṣegun ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹrinla oṣu kọkanla 2023, atẹjade kan wa lati ọfiisi adari eto ikede ni CBN, Isa Abdulmumin, ninu eyi ti banki naa ti ṣalaye pe awọn ti wọgile gbedeke lori owo atijọ naa.
Atẹjade naa fi kun un pe ẹnikẹni ko gbọdọ kọ awọn owo N100, N200 ati N500 atijọ naa rara, nitori owo tofin faaye gba to si fọwọ si ni wọn n ṣe.
Gẹgẹ bi CBN ṣe wi, igbesẹ yii waye lati dena wahala ati idaamu to waye lasiko tawọn eeyan ko fẹẹ maa gba awọn owo atijọ naa mọ nitori tuntun tijọba fi paarọ rẹ, eyi to bẹrẹ lasiko iṣakoso Godwin Emefiele ti i ṣe ọga agba ileefowopamọ apapọ nigba yẹn.
Igbesẹ naa di wahala tawọn ọmọ Naijiria n fẹhonu han kiri nitori airowo gba ni banki.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Tẹ o ba gbagbe, awijare Emefiele nigba naa ni pe ayipada owo atijọ naa yoo ṣẹgun ijinigbe, ibo rira ati ọwọngogo ọja, ṣugbọn iṣoro airowona lo pada ja si faraalu.
Lati dena iṣoro naa lasiko yii ati lọjọ iwaju, Banki apapọ sọ pe gbogbo owo atijọ ti iṣakoso Emefiele paarọ ti di nina bayii lai ni gbedeke ipari kankan















