Èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo tí INEC kéde ní èèrú nínú, mi ò gbà á wọlé - Asue Ighodalo olùdíje PDP

Oríṣun àwòrán, Asue Ighodalo/X
Oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo ipinlẹ Edo to waye lọjọ Abamẹta ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹsan an yii, Asue Ighodalo, ti fi aidunnu rẹ han lori abajade eto idibo naa.
Ighodalo sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Pidgin pe oun ni ijakulẹ ninu abajade eto idibo ọhun eyi ti ajọ INEC kede pe Okpebholo Monday oludije APC lo wọle.
‘’Mo ni ijakulẹ ninu eto idibo naa tori mo ti ro pe gbangba laṣa ta ni eto idibo naa yoo jẹ ti ko si ni si eeru nibẹ.
Inu mi bajẹ gidi gan an, o wa dabi ẹni pe eto idibo yii lo buru julọ ninu itan eto idibo lorilẹede Naijiria,’’ Ighodalo ṣalaye.
Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe akọsilẹ fihan pe oludibo 156 lo forukọ silẹ ni ibudo idibo Ologo ni Ikpoba Okha, ṣugbọn 2,110 ibo ni ajọ INEC kede pe APC ni nibẹ nigba ti PDP ri 57.
Ighodalo sọ pe o to aadọta ibudo idibo ti esi ibo ti ajọ INEC kede ti ju iye awọn oludibo to forukọ silẹ lọ.
Emi ati igbakeji mi ko ni gba esi ibo ti INEC kede wọle - Ighodalo
Ighodalo ni oun ati igbakeji oun ko ni gba esi ibo ti INEC kede wọle ti ajọ naa ko ba ṣe atunṣe.
‘’A ko ni faramọ aisododo, a fẹran alaafia ni ẹgbẹ oṣelu PDP, emi ati igbakeji mi kii ṣe onijagidijagan.
Ka ni pe eto idibo naa lọ ni irọwọ rọsẹ ni, a o ba fi tayọ tayọ gba a wọle,’’ Ighodalo lo sọ bẹẹ.
Ighodalo ni Gomina Godwin Obaseki fun ra rẹ lọ si ọfiisi ajọ INEC nibi to ti beere lọwọ ọga INEC wi pe ki lo ṣẹlẹ ti wọn fi da akojọpọ ibo ti wọn n ṣe duro.
O ni ọga INEC ko sọ nkan kan lori ọrọ naa, dipo bẹẹ, Ighodalo sọ pe ni ṣe lo lọ ba igbakeji ọga ọlọpaa ni Naijiria ti o si gba ibẹ lọ.
Oludije PDP sọ pe nitori ọrọ ti Obaseki sọ ni ajọ INEC fi bẹrẹ akojọpọ ibo ti wọn n ṣe pada.






















