Ẹnikẹ́ni tó bá dí ojú pópó nítorí ayẹyẹ wẹ̀jẹwẹ̀mu yóò fojú ba ilé ẹjọ́ – Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, @MobilePunch
Ijọba ipinlẹ Eko ti koro oju si bi awọn olugb eipinlẹ naa kan ṣe n di oju popo lasiko ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ, paapaa lawọn kọrọkọdndu adugbo, eyii to n ni awọn ẹlomiran lara.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ajọ to n gbofinro ‘taskforce’ nipinlẹ naa, Gbadeyan Abdbulraheem fi lede, o ni ijọba Eko ko ni faye gba irufẹ iwa bẹẹ mọ.
Atẹjade naa ni alaga ajọ ọhun, CSP Shola Jejeloye juwe iwa naa gẹgẹ bii iwa imọtaraẹni nikan.
Jejeloye ni ko tọ ki awọn eeyan maa ni awọn ẹlomiran lara nitori pe wọn n ṣe ayẹyẹ wẹjẹwẹmu.
O ṣalaye pe ajọ naa ti da oju agbo ọjọ ibi kan ru lagbegbe Yaba nipinlẹ naalẹnu ọjọ mẹta yii, lẹyin ti ẹni to n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi gba ida 95% oju popo to yẹ ki awọn eeyan maa gba kọja fun ayẹyẹ rẹ.
Alaga ajọ ọhun fi kun pe awọn agbegbeb bii Lagos Island, Oworonshoki ati Agege ni irufẹ iwa bẹẹm ti gbilẹ julọ.
O ni “o jẹ ohun ti ko ṣe itẹwọgba ki awọn adanikanjọpọn kan maa di ọna adugbo nitori wọn n ṣe ayẹyẹ ki wọn tun maa pariwo di awọn olugbe agbegbe naa leti.”
“O jẹ ohun ti ko bojumu ki eeyan maa wu irufe iwa bẹẹ, nitori naa, lati akoko yii lọ ẹnikẹni ti a ba gbamu yoo foju bale ẹjọ lai fi akoko ṣofo.”
Jeleloye kilọ pe ti irufẹ nnkan bẹẹ yoo ba waye, awọn to n ṣe ayẹyẹ gbọdọ gba aṣẹ lọwọ ijọba ki wọn to di oju popo.
Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati fi ẹjọ ẹnikẹni to ba di oju popo sun latari pe o n ṣe ayẹy eki wọn le fi imu irufẹ ẹni bẹẹ danrin.













