Ó kù sọ́wọ́ àwọn onímàkàrúrù láti jẹ́ kí àbá ìsúná ₦27.5tn Ààrẹ̀ Tinubu so èso rere - Onímọ̀ ọrọ̀ ajé

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Awọn onimọ eto ọrọ aje ti sọ pe aba iṣuna ti aarẹ Tinubu kede mu ọgbọn wa amọ ọtọ ni ki aba dara loju ọtọ si ni ko di amuṣẹ lọwọ awọn to n ṣeto rẹ.
Wọn ki aba yi to le so eso ti ijọba foju sun, ayafi ki awọn inanakuna yi ọkan pada ki wọn si fi ọkan ṣe amuṣẹ aba naa bo ti ṣe yẹ.
Mustapha Hussein Olanrewaju,fca,to jẹ agba onimọ iṣiro ni ilu Abuja lo ṣalaye ọrọ yi lasiko to n ba BBC sọrọ lori aba iṣina triliọnu mejidinlọgbọn din diẹ ti aarẹ Tinubu fẹ gbe lọ siwaju ile aṣofin lọjỌru.
Aba iṣuna yi ju trilliọnu mejilelogun diẹ Naira ti aarẹ tẹlẹ Muhammadu Buhari gbe lọ sile ni ọdun ikẹyin to lo lori oye .
Mutapha sọ pe bi eeyan ba foju wo aba yi yoo ri pe ijọba fẹ na owo ju dede iye to n pa wọle ti eleyi si lanfaani tiẹ naa ti yoo mu ba araalu lopin igba ti wn be ṣe bo ti ṣe yẹ.
Ni atupalẹ rẹ, paṣiparọ owo Naira si dọla ti ijọba fi ṣe oṣunwọn iye ti wọn da laba yi jẹ aadọta le ni ẹẹdẹgbẹrin Naira si dọla kan(#750-$)
Iṣiro agba epo rọbi ti wọn si fẹ lo ja si dọla mẹtadinlọgọrin fun agba kan.
Alekun ba isiro yi lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ to gajulọ to sun owo aba isuna naa lati N26.01tn si N27.5tn ti aarẹ n gbe lọ siwaju ile
Ki lawọn nkan mẹta ti iṣuna gbọdọ koju
Mustapha Hussein ṣalaye pe eredi iṣuna yala nigba to wa ni aba ni tabi igba ti aarẹ ba buwọlu gbọde le ṣe awọn nkan mẹta kan.
Akọkọ ni pe aba iṣuna a maa fun awọn to n dari ilu lanfaani ati ṣe eto ipalẹmọ lori nkian to fẹ wọle fun ati eleyi to fẹ na sita.
O ni ọdọọdun si ni Naijiria a maa ṣe aba iṣuna pẹlu ero yi lọkan botilẹ jẹ wi pe pupọ awọn to wa ni ijọba ni kii foju sunukun wo bi wọn ṣe n na owo sita.
Bẹẹ naa lo ṣalaye pe ''aba iṣuna gbọdọ le jẹ ki awọn adari kẹkọ nipa ikoraẹni ni ijanu lori bi wọn ṣe n na owo''
O ni aibikita ni paapa lati ọwọ awọn adari a maa mu ki inakuna pọ ninu eto iṣuna Naijiria.
O ni bi aba iṣuna yoo ba di imuṣẹ ni paapa ti ọdun 2024 ti aarẹ n gbero yi, awọn to n ṣe amojuto iṣuna ni lati mura ṣiṣẹ gidi.
''Awọn araalu ko ni igbagbọ ninu iṣuna Naijiria.Eyi ko si ṣẹyin bi awọn to wa nidi amuṣẹ rẹ ṣe maa n ṣe owo kumọkumọ.''
''Ninu aba yi to ṣe pe ohun ti ijọba fẹ na ju eyi to n wọle lọ, o ṣe pataki ki awọn afunṣọ di gbogbo ọna ti owo fi n bọ si apo awọn oni makaruru''
Ọrun yoo tun wọ gbese ti Naijiria jẹ kalẹ tẹlẹ laisan
Iṣuna 2024 gẹgẹ bi Mustapha ti ṣe sọ jẹ eleyi ti ijọba yoo ti na owo ju iye to n wle fun lọ.
O ni bi eeyan ba tiẹ kọkọ wo paṣiparọ dọla si Naijiria nilẹ oni to mọ, yoo ri pe iyat wa nibẹ ti eleyi naa yo si farahan nibi iṣeto isuna ọdun 2024.
''Pupọ owo ti ijọba fẹ na ninu owo iṣuna yi jẹowo idẹkun, owo oṣu oṣiṣẹ, awọn to di ipo oṣelu mu ati awọn owo ina ojojumọ ti ijọba yoo maa na.''
''Lopin igba ti a ko ba ti na owo to pọ lori awọn nkan ti yoo mu idagbasoke ba ilu bi ipese oju ọna, ile igbe tabi kikọ awọn ohun amayedẹrun mii,aba yi ko le so eso baa ṣe fẹ''
Nigba taa beere lọwọ rẹ boya ọna mii wa ti ijọba le mu adinku ba gbese to wa nilẹ o ni eleyi yoo ṣoro diẹ.
Iye tiijọba yoo pa wọle ninu triliọnu mẹtadinlọgbọn le diẹ to fẹ na yi ko le ju triliọnu mejidinlogun lọ.Eleyi to ku nibo lẹ fẹ ki wọn ti ri bi kii ṣe pe ki wọn lọ ya owo sii?''
O ni owo yiya yi yoo tunbọ jẹ ki gbese to wa nilẹ pọ si lọrun ijọba ni.
Lasiko ijọba Buhari to kọja, iye gbese ti ijba jẹ kalẹ jẹ nkan bi triliọnu mẹtadinlọgọrin N77tn.
Aarẹ Tinubu naa ti ke gbajare lori gbese to ba nilẹ ti ko si daju pe ijọba rẹ ko ni jẹ kun eyi to wa nilẹ si ko tokuro lori oye.

Oríṣun àwòrán, Mustapha Hussain Olarewaju
Ijọba tuntun ree amọ to ba mura ọna abayọ wa
Onimọ yi ṣalaye pe ko si nkan to wa ninu aba iṣuna ti aarẹ n gbero yi ti oju ko riri.
O ni lọpọ igba awọn to maa n ṣe agbekalẹ aba iṣuna Naijiria a maa kọ lọna ti o maa n wueeyan lori .
Amọ o ni ibi amuṣẹ yi naa ni wahala wa tori pe awọn afunṣọ kii fi ẹmi daada ṣe eto to ba ti kan ọrọ owo nina ni Naijiria.
''Eto idagbasoke lo yẹ ka maa na owo si amọ taa ba ṣe iranwọ tabi idẹkun fun araalu lasiko ti nkan le yi, ko saburu nibẹ''
O fikun ọrọ rẹ pe ''Ijọba ko ni ọna mii lati pese owo dọla ti yoo na lati fi ṣeto iṣuna ju idi epo rọbi to n ta lọ.''
''Bi a ba wo iye odinwọn ti ajọ Opec fun wa, a ko ribi pese iye epo rọbi yi depo pẹ a o ta ju iye taa n ta lọ tẹlẹ.''
''Bi a ba fẹ ki owo to n wọle pọ si, a gbọdọ mura si awọn ileeṣẹ ipọnpo wa ki wn baa le pese epo rọbi to pọju ti tẹlẹ lọ.''
''Bi a ba ta epo rọbi ju ti tẹlẹ lọ, owo dọla yoo wọle si. Eyi yoo si jẹ ki a le pese awọn nkan amayedẹrun fawọn araalu''
Mustapha tẹsiwaju pe ijọba gbọdọ wa ọna ti owo to n wọle lati ilẹ okere ni paapa lọdọ awọn ọmọ Naijiria toi wa lẹyin odi naa gbọdọ maa lekun.
''Owo FDI taa mọ si Foreign Direct Investment to n wọle kere gaan. Ijọba ni lati ronu na ibaṣepọ pẹlu awọn aladani olokoowo ti yoo wa dokowo nilẹ wa.''
O ni iru owo bayii yoo tunbọ jẹ ki ọrọ aje Naijiria burẹkẹ si.












