Ohun tí a jogún lórí ọ̀rọ̀ ètò ààbò le díẹ̀, ẹ ṣe sùúrù fún wa - Ribadu

Aworan Nuhu Ribadu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nuhu Ribadu

Bí kudiẹkudiẹ ṣe ba eto abo lorilẹede Naijiria, Olubadamọran pataki fun Aarẹ lori eto abo, Nuhu Ribadu tí rọ àwọn ọmọ Naijiria lati ṣe suuru pẹlu isejọba Aarẹ Bola Tinubu.

Ribadu, ẹni to jẹ igbakeji Ọga Ọlọpaa tẹlẹri salaye pe ìjọba tuntun to wọle ninu oṣu karun un jogun akoko to le.

"A jogun akoko to le. A bere fun suuru lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria ," O sọ eyi lasiko to n sọrọ níbi apero awọn Ọga Akọroyin to waye ni Uyo, nipinlẹ Akwa Ibom.

Ribadu ni oun ti orilẹede Naijiria nilo bayii ni ifọwọsowọpọ pẹlu ìjọba apapọ lati fopin si gbogbo kudiẹkudiẹ to de ba eto abo.

"Asiko yii le. A ko naaka si ẹnikẹni sugbọn otitọ ọrọ ni. Awọn to wa ni ijọba ni lati sọ otitọ ọrọ lori bi nnkan ṣe wa, ti a si ni ireti pe nnkan yoo dara si."

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe nnkan ti yatọ ju ti tẹlẹ lọ sugbọn isẹ sì wa lati se lati fopin si bi eto abo ṣe mẹyẹ.

"Gbogbo wa ni a ní isẹ lati se lati ti Aarẹ Tinubu lẹyin.

"Mo ti wa nipo yii fun bi oṣu marun un, ti mo si ri bi nnkan ṣe n lọ ati bi o ṣe wa nigbati a de si ijọba sugbọn igbagbọ wa pe ilana ti a n tọ yii yoo so eso rere."