Ẹ forí jì mí n kò mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni títàbùkù ẹ̀sìn, Tani Olohun bẹ̀bẹ̀ lẹ̀yìn tí ilé ẹjọ́ gba béèlì rẹ̀ ní Ilorin

Ile ẹjọ Majisireeti kan ni ilu Ilọrin ti gba beeli ati oniduro fun gbajugbaja onisẹse, Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mọ si Tani-Ọlọhun.
Awọn Aṣiwaju ẹsin Musulumi kan atawọn ẹgbẹ mẹrin ọtọọtọ pe Tani Ọlọhun lẹjọ ni ile ẹjọ ọtọọtọ fun ẹsun ti o da lori ibanilorukọjẹ ati itabuku ẹṣin Islam.
Ẹjọ akọkọ ni eyi ti Kọmisonna Ọlọpaa Kwara pe e lorukọ ẹgbẹ̀ kan to n jẹ Association of Proud Sons and Daughters of Ilọrin (Ogo Ilorin) ni iwaju Magistrate Muhammad Ibrahim fun ẹsun ibanilorukọjẹ.
Ekeji ni ti Alfa Tonile Okutagidi ni iwaju Honourable Sunday Adeniyi ti ile ẹjọ Upper Area fun ẹsun ibanilorukọjẹ bakan naa.

Olupẹjọ ẹkẹta ni Sheikh Labeeb Lagbaji fun ẹsun ibanilorukọjẹ, ẹgbẹ Modrasat Muhammed ti Ọjọgbon Abdukadir Aliagan jẹ adari fun si ni olupẹjọ kẹrin, lori ẹsun jijo Kurani nina.
Iwaju Magistrate Muhammad Adam si ni wọn gbe ẹjọ mejeji ti o gbẹyin yi wa.
Saaju, Ile ẹjọ ti gba beeli ẹjọ meji akọkọ to si ku meji ti o gbẹyin yii fun un lati gba ominira.
Ni bi igbẹjọ mejeji to waye ni Ọjọbọ, agbẹjọro Ademola Banks to n duro fun onisẹse naa rọ ile ẹjọ lati gba beeli onibara oun, wi pe ko ni sa lọ, yoo si ma yọju si ile ẹjọ ni gbogbo ọjọ igbẹjọ.
Awon agbẹjọro alatako, Taofiq Olatẹju ati YY Ajibade kọ lati tako ẹbẹ fun beeli yii sugbon wọn fi gbogbo rẹ kọ ile ẹjọ lọrun.
Àwọn ìròyìn míràn tí ẹ tún lè kà:
Tani Olohun tọrọ aforiji lọwọ awọn to pe e lẹjọ

Olujẹjọ ohun, Tani-Ọlọhun gba iyọnda ile ẹjọ lati sọrọ, o si rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn olupẹjọ lati foriji oun.
Tani Ọlọhun fi kun un pe oun ko mo pe ohun ti oun n se nigba naa jẹ ẹsẹ sugbon oun ko see lati fi tabuku ẹni kan tabi ẹṣin kan.
Lẹyin eyi ni adajọ Muhammad Adam gbe idajọ ranpẹ kalẹ, o si gba beeli olujẹjọ naa ni odunwo millionu meji naira pẹlu oniduro meta ti meji gbudọ jẹ ibatan rẹ.
Oniduro yii gbọdọ ni dukia ile tabi ilẹ ni ilu Ilọrin tabi ipinlẹ Ọyọ, o si gbọdọ jowọ awon iwe dukia naa fun ile ẹjọ to fi mo iwe irina ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Agbẹjọro Ademola Banks dupẹ lọwọ ile ẹjọ sugbon o ni ti awon ba kan inira ninu awọn ilana ti o gbe kalẹ, awon yoo pada wa fun agbeyẹwo.
Adajọ gba ọrọ rẹ, o si sun igbẹjọ mii si ọjọ kẹsan osu kinni, ọdun 2024.












