Tani Olohun fojú balé ẹjọ́ gíga ìlú Ilorin, bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ lónìí rèé

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun/BBC
Abdulazeez Adegbọla ‘Tani Ọlọhun’ ti lọ jẹjọ nile ẹjọ giga ilu Ilorin niwaju adajọ FD Lawal lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an.
Ọkan lara awon agbẹjọro onisẹse naa, Ademola Banks lo gbe iwe beeli rẹ tọ ile ẹjọ naa lọ lori ọna ati gba oniduro fun un.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Ademola Banks ti kọkọ gbe iwe beeli naa lọ siwaju adajọ majistreeti Muhammad Ibrahim, ti adajọ naa si kọ ẹbẹ rẹ lori awọn kudiẹ kudiẹ kọọkan ti wọn ri ninu iwe beeli ọhun.
Eyi lo faa ti agbẹjọro naa fi pe fun ẹbẹ kotẹmilọrun to gbe lọ siwaju ile ẹjọ giga.
Ki lo ṣẹlẹ nile ẹjọ giga lonii?
Nibi igbẹjọ to waye nile ẹjọ giga ni agbẹjọro Ademola Banks ati Omotunde Adeola, SAN, ti jọ duro fun Tani Olohun, nibi ti wọn ti rọ ile ẹjọ ki o fun onibara awọn ni beeli.
Ni tirẹ, agbẹjọro alatako, amofin Sanni Oseni to ṣoju ẹgbẹ Ogo Ilorin, sọ fun ile ẹjọ pe ojulowo iwe beeli Tani Olohun lori ẹbẹ kotẹmilọrun rẹ ko tii tẹ ikọ oun lọwọ.
O rọ ile ẹjọ ko fun awọn ni asiko diẹ lati gba ojulowo iwe naa ki wọn si mọ boya ki wọn tako o tabi ki wọn gba a wọle.
Ki ni adajọ ṣe?
Bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro Omotunde Adeola tako ẹbẹ yii, adajọ FD Lawal gba a wọle, o ni aigbaa wọle yoo jasi riro ilẹ apa kan da ikan si.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ naa si ọjọ keji, osu Kọkanla, ọdun 2023 yii.












