Akọ̀ròyìn Al-Jazeera pàdánù aya, ọmọ méjì àti ọmọ-ọmọ lásìkò ìkọlù Israel sí Gaza

Oríṣun àwòrán, getty images
Àwọn ẹbí akọ̀ròyìn ilé iṣẹ́ ìròyìn Al-Jazeera kan ti pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù tó wáyé ní Gaza.
Ìkọlù ọ̀hún ló wáyé ní ààrin gbùngbùn Gaza lẹ́yìn tí Israel ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn láti kúrò ní àríwá Gaza.
Ìkìlọ̀: Ìròyìn yìí ní àwọn àwòrán tó lè mú ọkàn ènìyàn pami.
Ìyàwó Wael Al-Dahdouh, àtàwọn ọmọ rẹ̀ méjì pàdánù ẹ̀mí wọn ní ilé àwọn aṣatìpó tó wà ní ààrin gbùngbùn Gaza gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Al-Jazeera ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Bákan náà ni ìròyìn tún ní ọmọ-ọmọ rẹ̀ tún bá ìkọlù ọ̀hún lọ.
Al Jazeera bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà àtàwọn ìkọlù tí Israel ń ṣe sí Gaza.

Oríṣun àwòrán, Getty Images / Anadolu Agency
Jíju àdó olóró sí ààrin gbùngbùn Gaza láti inú afẹ́fẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images / Anadolu Agency
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Al-Jazeera, àwọn ẹbí Al-Dahdouh ń gbé ní ilé kan nínú ọgbà Nuseirat tó wà ní àárín gbùngbùn Gaza lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilé wọn ní àríwá Gaza látàrí ìkìlọ̀ tí Israel ṣe fún wọn láti kó lọ sí gúúsù nítorí ogun tó ń wáyé níbẹ̀.
Mahmoud, ọmọ Al-Dahdouh, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ti wà ní ipele tó kẹ́yìn ní ilé ẹ̀kọ́ girama, tí Sham sì jẹ́ ọmọ ọdún méje.
Adam tó jẹ́ ọmọ-ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọmọ oṣù méjìdínlógún.

Oríṣun àwòrán, Getty Images / Anadolu Agency
Àwọn ẹbí mìíràn ni wọ́n sin sábẹ́ àwọn ilé tó dàwó ṣùgbọ́n àwọn mìíràn móríbọ́ nínú ìkọlù náà.
Iléeṣẹ́ ètò ààbò Israel (IDF) ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ṣe ìkọlù sí ikọ̀ Hamas ní agbègbè ibi tí àwọn ẹbí Al-Dahdouh ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Nígbà tí BBC bi Agbẹnusọ IDF, Peter Lerner nípa àwọn ará ìlú tí àdó olóró Israel pa ní Gaza, tó fi mọ́ àwọn ẹbí akọ̀ròyìn náà, ó ní gbogbo ẹ̀mí tó bá sọnù ló jẹ́ àdánù.

Oríṣun àwòrán, Getty Images / Anadolu Agency
Ògbéré ẹkún ní ilé ìwòsàn
Àwòrán Al-Dahdouh tó wà lórí ayélujára ṣàfihàn bí ó ṣe ń dá omi lójú nílé ìwòsàn bí ó ṣe di òkú ọmọbìnrin, ọmọ ọdún méje rẹ̀ dání, tó sì kúnlẹ̀ ti ọmọkùnrin rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images / Anadolu Agency
Al-Dahdouh ní kò sí ibi tí ààbò wà ní Gaza rárá nígbè tó ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Al-Jazeera.
Al-Dahdouh ni Ọ̀gá àgbà Al-Jazeera ní Gaza tó sì ti ń bá ilé iṣẹ́ ìròyìn náà ṣiṣẹ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images / Anadolu Agency
Al-Jazeera ní àwọn kọminú lórí ààbò àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tó wà ní Gaza tí wọ́n sì fi ààbò wọn kọ́ ìjọba Israel lọ́rùn.
"A rọ àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé láti dá sí ọ̀rọ̀ yìí, kí wọ́n sì fi òpin sí ṣíṣe ìkọlù sí àwọn ará ìlú, kí ààbò le wà fún ẹ̀mí àwọn ènìyàn."

Oríṣun àwòrán, Getty Images / Anadolu Agency
Gaza ló ti ń kojú ìkọlù látọwọ́ Israel lẹ́yìn tí ikọ̀ Hamas ṣe ìkọlù àìròtẹ́lẹ̀ sí Israel ní ọjọ́ Keje oṣù Kẹwàá níbi tí èèyàn tó lé ní 1,400 ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Ènìyàn tó lé ní igba tó jẹ́ ọmọ Israel ló ṣì wà ní àhámọ́ Gaza títí di àsìkò yìí.
Iléeṣẹ́ ètò ìlera tí ikọ̀ Hamas ń ṣe àmójútó rẹ̀ tó wà ní Gaza ní ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje ènìyàn tí Israel ti ṣekúpa.
Israel ti ṣe ìdádúró pípèsè epo, iná àti omi sí agbègbè náà láti ìgbà tí ìkọlù náà tí bẹ̀rẹ̀.
Láti orílẹ̀ èdè Egypt ni ìwọ̀nba ìrànlọ́wọ́ ti ń wọlé sí Gaza.

Oríṣun àwòrán, Getty Images / Anadolu Agency












