Èyí ni àlàyé Saudi lórí ìdí tí wọ́n fi dá àwọn Alálàájì ọmọ Nàìjíríà padà sílé

Oríṣun àwòrán, National Hajj Commission of Nigeria/X
Ileeṣẹ to n ri sin irinajo wọ orilẹ-ede Saudi Arabia ti ṣalaye idi ti wọn fi da awọn alalaaji 177 pada si Naijiria lẹyin ti wọn de Jeddah.
Ijọba Saudi sọ pe awọn eeyan naa ko tẹle ofin iwọle s’orilẹ-ede awọn ni.
Ọjọru ọsẹ yii tii ṣe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla ọdun 2023 ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ to n ri si iwọle-wọde s’orilẹ ede naa ṣalaye, pe awọn eeyan tawọn da pada naa ko fi awọn akọsilẹ to ba ohun ti wọn fẹ wa ṣe mu silẹ ninu awọn iwe ti wọn kọwọ bọ lasiko ti wọn n ṣeto irinajo naa.
Eyi ni wọn lo fa a to fi jẹ pe fisa ti ko tọ si wọn ni wọn gba lati wọ Saudi.
Wọn ni nigba tawọn si ti fidi eyi mulẹ, ko sohun to kan mọ ju kawọn da awọn tọrọ naa kan pada si Naijiria ti wọn ti n bọ lọ.
Atẹjade to wa lati ileeṣẹ ijọba Saudi Arabia naa sọ pe, ''ẹmbasi Saudi Arabia to wa l’Abuja fẹ ṣe awọn alaye kan ti yoo jẹ kawọn eeyan mọ otitọ nipa awọn eeyan ta a da pada si Naijiria lati Jeddah lasiko ti wọn fẹẹ wọ Saudi.
Awọn arinrinajo ti a da pada ko tẹle ofin to de wiwọle siluu wa ni.
Ohun ti wọn kọ ranṣẹ lo fa iru fisa ti wọn gba, eyi ti ki i ṣe iru fisa to yẹ ki wọn gba rara, nigba ti wọn si de lawa ṣẹṣẹ mọ.
Ohun to fa a ta a fi da wọn pada niyẹn.’’
Ileeṣẹ to n ri si irinajo silẹ Saudi naa sọ pe o ṣe pataki kawọn arinrinajo maa tẹle ofin to de irinajo wọn, ati ohun ti wọn fẹẹ waa ṣe niluu naa .
Wọn ni ki wọn ri i pe gbogbo rẹ wa ni ibamu pẹlu ohun ti wọn fẹẹ waa ṣe ki wọn too gbera lorilẹ-ede wọn rara, kiru ohun to ṣẹlẹ yii maa baa waye mọ.
Eyi ki i ṣe fawọn eeyan Naijiria nikan bi wọn ṣe ṣalaye, fun gbobo arinrianjo kaakiri agbaye ni.















