Oladips, olórin tàkasúfèé míì dolóògbé lẹ́yìn Mohbad; Ohun tí a mọ̀ nípa ikú rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, @oladips instagram
Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni pe gbajugbaja olorin taka-sufee, Ọladipupọ Ọlabọde Ọladimeji tawọn eeyan mọ si Oladips, ti jade laye.
Aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹrinla alẹ ọjọ Iṣegun, ọjọ Kẹrinla oṣu Kọkanla ọdun 2023 yii ni Oladips jade laye gẹgẹ bi awọn alabaṣiṣẹ rẹ sẹ gbe soju opo Instagraamu rẹ l’Ọjọru.
Ninu atẹjade ti wọn fi kede iku Oladips ni wọn ti ṣalaye, pe o ti ju ọdun meji lọ tọmọkunrin to doloogbe naa ti n da ogun aye rẹ ja lai sọ fẹnikan kiku to de lojiji lalẹ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.
Iku Oladips yii waye lẹyin oṣu meji ati ọjọ mẹta ti Mohbad, iyẹn Ileri Oluwa Alọba, jade laye, ti ariwo iku ọhun ko si ti tan nilẹ titi dasiko yii.
Awọn mọlẹbi Oladips ti wa sọ pe kawọn eeyan fawọn laaye lati ṣe idaro rẹ.
Ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) ni Oladips ko to jade laye.
Ṣe Oladips ti riran iku rẹ ṣaaju?
Loju opo rẹ ni Instagram ọrọ idaro lo pọ ju nibẹ.
Awọn ololufẹ rẹ lagbo idaraya ko dakẹ fifi ọrọ iranti ranṣẹ si loju opo rẹ.
Ohun to jẹ ki iku rẹ ṣe ọpọ ni kayeefi ni awo orin to gbe jade kẹyin to ti sọrọ nipa iku.
Ninu fidio orin yi to pe akọle rẹ ni ''Die Young'' akọle yi gaan jẹ bi atọka si bi akọrin yi ṣe ku lewe.
Ninu rẹ o ṣadura pe ki oun ma ku lewe tori pe oun ṣi ni oun lati gbese nile aye.
O sọ ninu orin naa pe awọn eeyan a maa ṣe idaro ẹni ba lọ lẹyin iku wọn ti wọn o si ni bikita lati beere wọn nigba ti wọn wa laye.
Awọn ọrọ inu orin yi mu ki ọpọ maa woye si iru iku rẹ ti wọn si n beere pe ṣe kii ṣe pe o riran iku rẹ ṣaaju asiko yi.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oladipsoflife
Sibẹ awọn eeyan ṣe idaro rẹ loju opo rẹ lọna ati fi ifẹ han si oloogbe naa.
Lara awọn taa ri ni gbajugbaja oṣere tiata Itele d Icon.

Oríṣun àwòrán, oladipsoflife
Kayeefi mii to tun jẹ ki ẹnu maa dakẹ lori iku rẹ ni pe o fi aworan Mohbad to jade laye laipẹ yi soju opo rẹ to si fi ṣe ohun taa mọ si aworan DP.
Awọn alaṣẹ ko ti sọ boya iku rẹ ni ọwọ magomago ninu bo ti lẹ jẹ wipe awọn ẹbi rẹ naa ti beere pe ki awọn eeyan fawọn ni aaye lati daro rẹ.
Iku rẹ yi tun mu iriwisi wa nipa iru igbe aye tawọn ọdọ n gbe pẹlu awn ipenija ti wọn n koju ti wọn o le ba eeyan sọ.
Awọn iriri ati iṣẹlẹ ẹnu ọjọ mẹta yi fihan pe awọn ti awujọ n ri gẹgẹ bi gbajumọ laarin awọn ọdọ n koju ogun labẹle ti wn o le sọ sita.
Labẹ eleyi naa ni awọn nowoye kan ti ni kawọn eeyan mojuto ọrọ irẹwẹsi ọkan taa n pe ni Depression ki awọn to n koju rẹ si gbiyanju lati ba awọn eeyan s nipa ohun ti wọn koju ko to di pe yoo mu ẹmi wọn lọ.












