Wo bí òpin ṣe dé bá agbègbè tó rẹwà jùlọ ní Gaza

Adugbo al Zahra ṣaaju ikọlu to waye lẹyin ọjọ Keje oṣu Kẹwaa
    • Author, Alice Cuddy
    • Role, BBC News, Jerusalem

Ni nkan bi ago mejila ọsan lawọn olugbe adugbe al Zahra pejọ lati wo ohun to ṣẹku lẹyin ti ikọlu deba ile wọn.

Ọjọ pataki ni ọjọ Ẹti yẹ kojẹ:ọjọ ti wọn n kora jọ ki irun Jumaah ti o si tun jẹ ibẹrẹ opin ọsẹ.

Lasiko yi lawọn araadugbo a maa pejọ lati ṣe faaji ni ẹhinkule ile wọn.

Ni afiwe , awọn araadugbo yi mọ pe awọn tun yi lanfaani alaafia ju awọn araadugbo mii lọ ni Gaza.

Amọ loru mọju ni awọn ado oloro ti Israeli sọ lu wọn lati inu baalu wo awọn ile mẹẹdọgbọn to jẹ ibi ti ọgọrọ eeyan n gbe.

Ni idahun si ikọlu Hamas si awọn eeyan rẹ lọjọ Keje oṣu Kẹwaa ni Israel ti bẹrẹ si ni sọ ado oloro lu Gaza.

Ṣaaju akoko yi, al-Zahra ko farakasa ado oloro wọn yi.

Pupọ awọn to n gbe adugbo yi-oniṣegun,agbẹjọro,awọn onimọ ẹkọ,oniṣowo ati awọn mii- ni wọn gbiyanju lati foripamọ laarin ile to wo amọ ọpọ lo ko ẹru wọn ti wọn si wa ibi gba lọ.

Hana Hussen to gbe al Zahra dagba n fi ọkan ba iroyin ohun to n ṣẹlẹ nibẹ lati Turkey to ko lọ lati nkan bi ọdun meji sẹyin.

O pe awọn mọlẹbi rẹ sori ago lọjọ taa nwi yi lati mọ boya alaafia ni wọn wa.

O sọ fun wọn pe oun nifẹ wọn.

O sọ ọ tan ni ago ba dakẹ pim.

Olugbe kan ree nibi to ti n rin laarin awọn ile to wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

‘ Ẹ ṣeun ti ẹ beere, A ṣi wa laye.’

Inu ọgba fasiti kan to wa ni itosi lawọn araadugbo yi foripamọ si.

Ọpẹlọpẹ Mahmoud Shaheen to ṣeto bi wn ṣe aimọye awọn araadugbo rẹ lọ sibẹ.

A mu itan iṣẹlẹ yi wa sietiigbọ yin lọsẹ to kọja nibi taa ti ṣalaye bi o ṣe n gba ipe lati ọwọ oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ Israel kan to n kilọ awọn ile tawọn fẹ ju ado oloro lu fun.

A fi ibeere ranṣẹ si ileeṣẹ ologun Isreael IDF nipa kini wn ri ti wọn fi ṣe ikọlu sawọn ileegbe al Zahra amọ wọn sọ pe ''awọnko ni le dahun awọn ibeere to niiṣe pẹlu iṣẹ ikọlu tawọn gbe ṣe''

Wọn fi kun pe ''Hamas n ṣe ikọlu si Israellati Gaza ti wọn si sapamọ saarin awọn araalu''

Wọn ko darukọ ọmọ ogun Hamasa kankan ti wọn ri pa ninu ikọlu wọnyi ti wọn ṣe si al-Zahra.

Igbagbọ si wa wi pe eeyan kankan ko ku ninu ikọlu yi.

Awọn araadugbo Mahmoud le ti moribọ ninu ikọlu yi ṣugbọn kii ṣe gbogbo wọn lori ko yọ ninu nkan to tẹle iṣẹlẹ yii.

Arakunrin ọmọ Palestine yi joko to si n woye ikọlu to pa ọpọ ile rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC ti fi aimọye ọsẹ ba awọn idile sọrọ lati agbegbe yi to fi mọ awọn to dagba sibẹ ati awọn mii to ṣẹṣẹ darapọ mọ wọn.

Wọn tẹnubọ ọrọ bi wọn ṣaa ṣe fa nkan ti ọwọ wọn ba ti wọn si fọn kaakiri Gaza lẹyin ti ile wọn sọna loju wọn.

Ati ẹni toribi foripamọ ati awọn to gbe inu ile lẹyin ikọlu yi, aimọye eeyan lo fifẹ han lati sọ iriri wọn fun wa nipa igbe aye wọn ati bi adugbo ti wọn nifẹ ṣe parẹ mọ wọn loju.

Ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ la fi n ba wọn sọrọ.

Igba mi ipe naa yoo maa ja ti a o si ni gbọ ara wa daada pẹlu bi ado oloro ṣe n bu gbamu labẹ ipe naa.

A lo Whatsapp naa.

Awọn mii a si maa ja ipe tori pe wọn fẹ sa asala fun ẹmi wọn.

Nigba mii, o maa n to bi ọjọ meloo kan ti a ko ni gburo awọn taa n ba sọrọ lori ago.

Eeyan kan ninu awọn taa n gbiyanju lati ba sọrọ pada ri bi kan si wa lori opo Whatsapp to si dahun pe ''Ẹ ṣeun ti ẹ beere.A ṣi wa laye''

Ọrọ taa sọ pẹlu awọn eeyan fihan pe kii ṣe gbogbo eeyan to sa kuro ni al-Zahra lo ye e.

Ninu awọn taa gbọ pe o padanu ẹmi wọn ni arakunrin agberinsapa kan ti iroyin sọ pe ọrọ to kọ soju opo ayelujara kẹyin jẹ ''gbogbo rẹ ti parẹ tan''

Ileeṣẹ ilera ti Hamas n ṣamojuto rẹ sọ pe o le ni ẹgbẹrun mẹwaa ọmọ Palestine to ti padanu ẹmi wọn latiigba ti ikọlu yi bẹrẹ.

Ida mẹta ninu wọn si jẹ ọmọde.

Nashwa: Kikọ akọsilẹ awọn to padanu ẹmi wọn

Nashwa Rezeq, to gbe ni al Zahra fun ọdun mejidinlogun

Oríṣun àwòrán, Nashwa Rezeq

Gaza jẹ aaye kan to kun fọfọ ti iṣẹ ati inira nipa wiwọle tabi jijade si pọ nibẹ.

Amọ agbegbe al Zahra jẹ ibikan to rẹwa pẹlu aaye inaju to tẹ to si tun rẹwa.

Laarin ọdun 1990 ni aarẹ tẹlẹ Palestinian Authority (PA) Yasser Arafat da al Zahra silẹ gẹgẹ bi ibugbe fawọn oṣiṣẹ ati alatilẹyin.

Awọn to n gbe ibẹ sọ pe o ṣi ni ohun ṣe pẹlu Palestinian Authority to wa ni agbegbe West Bank.Ikọ to jẹ alatako Hamas.

O wa ni apa ariwa odo Wadi -ibi ti Israel sọ pe ki awọn araalu ko lọ si ni Guusu lọjọ Kẹtala oṣu Kẹwaa.

Eyi waye lẹyin aimọye ọjọ ti Israel fi n ṣe ikọlu si Gaza ni idahun si bi awọn ọmọ ogun Hamasa ṣe ṣeku pa eeyan 1,400 ti wọn si ko eeyan igba lẹru.

Ikọlu Hamas lawọn abule Israel to wa ni Guusu Israel jẹ nkan to dẹru ba ọpọ.

Aworan agbegbe ti al-Zahra wa

Gbogbo awọn taa ba sọrọ sọ pe agbegbe yi jina si Hamas ati iṣejọba rẹ.

Ọkan ninu wọn sọ pe ''Ko si awọn ologun nibi yi.'' ''Mi o si ro pe awọn alatilẹyin Hamas kankan wa nibi''

Lọkan Nashwa Rezeq to ti gbe bi al Zehra lati nkan bi ọdun mejidinlogun sẹyin, o ni ''ilu to gbajumọ julọ nibẹ jẹ''

Najwa jẹ ọkan lara awọn alakitiyan ọdọ ni al Zahra to si jẹ ọkan lara awọn to n dari oju opo adugbo wọn ni Facebook fun ọdun mẹwaa.

Ti o ba beere araadugbo kankan lọdọ rẹ,o ṣeeṣe ki o mọ ibi ti wọn n gbe koda yoo pese nọmba ẹrọ ibanisọrọ wọn.

Awọn to n tẹle oju opo Facebook yi sunmọ ẹgbẹrun mẹwaa.

Laisun ọjọ ti ikọlu yi waye, wọn kede idije kan to fẹ waye koda wọn ki akẹkọọ kan to n parieto ẹkọ rẹ ku oriire.

Ni bayii, oju opo yi ni wọn ti n fi iroyin ranṣẹ nipa ikọlu to waye lagbegbe naa ti wọn si fi n mọ awọn to padanu ẹmi wọn.

Awọn nkan ti Nashwa gbin sinu ikoko ni ile rẹ

Oríṣun àwòrán, Nashwa Rezeq

Ọrọ kan ti wọn kọ soju opo yi kẹdun iku mọlẹbikan ti wọn kagbako iku ninu ile ounjẹ ara Italy kan.

Nigba ti Israel kede ogun, Nashwa ati ọkọ rẹ ko awọn ọmọ wọn lọ si agbegbe Guusu gẹgẹ bi awọn ẹbimii naa ṣe ṣe.

O fi kọkọrọ kalẹ fun alabagbe rẹ kan pe ko maa ba ohun mojuto awn nkan to gbin sile rẹ.

Lẹyin ọjọ meji ti ikọlu akọkọ waye, wọn ju ado oloro lu ile rẹ to jẹ eyi to ga julọ ni al Zahra lowurọ kutu.

O ni ''Eeyan kan pe mi lori ago to si sọ fun mi pe ''mo gba ẹgbẹ rẹ kọja gbogbo rẹ pata lo si ti wo lulẹ''

Aworan al Zahra

O ṣapejuwe ile rẹ gẹgẹ bi ibi to gbaaye.

''Ọpọ eeyan lo n sọ pe owo nikan naa la apdanu.Amọ ni temi, ile mi ni ọkan mi''

Bayii to si wa ni apa Guusu Gaza, oun ati mọlẹbi rẹ si wa ninu ewu.

''Lọjọ mẹta sẹyin,wọn ju ado oloroluile to wa lẹgbẹ ti wa.Eefin to jade nibi ile naa ko si wa nimu''

Awọn ọmọ rẹ ko ye maa beere idi ti wọn o ṣe le gbe ẹrọ amuletutu wọn ati ẹrọ amohunmaworan wọn lọwọ nigba ti wọn sa kuro ni al Zahra.

Wọn a si tun maa bere nipa awọn nkan iṣere ọmọde wọn bakan naa.

Lohun to jẹ Nashwa logun, awọn nkan ọgbin rẹ ni. O ni ''Mo nifẹ wọn''

Ahmed Hammad leti omi

Oríṣun àwòrán, Ahmed Hammad

Ọjọgbọn fasiti Ahmed Hammad to gbe ninu ile kan to sunmọ ile to sunmọ ti Nashwa jẹ ọkan lara awọn to gbe ni al Zahra.

O wa lara awọn to pinnu lati duro lẹyin ikọlu ti Israel ṣe.

Ẹni aadọta ọdun ni Ọjọgbọn fasiti to n ṣiṣẹ ni fasiti kan lariwa agbegbe naa.

O yara lati fi awọn iṣẹ ọwọ rẹ ranṣẹ to si tun bawa sọrọ nipa awọn ọmọ rẹ mẹfa ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹjọ si mẹtadinlọgbọn.

Ọkan ninu wọn jẹ onimọ ilera itọju eyin, kan n ṣiṣẹ lẹka imọ ẹrọ tẹkinọlọji,ọkan si kẹkọ nipa litireṣọ ede Gẹẹsi.

''O ni awọn mẹta yoku ṣi n kẹkọ ni ile ẹkọ''

Nigba taa sọrọ lori ago loṣu to kọja, Ahmed ati awọn mọlẹbi rẹ n sa pamọ ni ile wọn to wa ni al Zahra ti ko ni ferese tabi ilẹkun.

Wọn duro sibẹ nitori ẹru n ba wọn lati sa kuro nibẹ ti ibẹru si gba ọkan wọn pe ikọlu yoo de ba awọn bi wọn ba ṣe n lọ si agbegbe Guusu.

Amọ lalẹ ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwaa, Israel mura si ikọlu jiju ado oloro pẹlu baalu ti wọn si tun mura siikọlu awọn ọmọ ogun ilẹ wọn.

Laarin igba yi,awa ati Ahmed ko ribi ba ara wa sọrọ mọ.

O sọ fun wa pe ''gbogbo igba ti ado oloro ba balẹ, a maa n sun gbalaja silẹ nii''

Awọn olokoowo al-Zahra

Hana Hussen ati ọmọ iya rẹ ọkunrin Yahya

Oríṣun àwòrán, Hana Hussen

Ni Turkey, Hana duro ti ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ ko baa le gburo awọn mọlẹbi rẹ.

Nibi to ti n duro, o bẹrẹ si ni sọ nipa ibi to juwe gẹgẹ bi ibi to rẹwa julọ lagbaye.

O ni niṣe lawọn olugbe al Zahra maa n kora jọ leti okun ti wọn a si tun kun oju ọna.

Lọjọ Ẹti Hana ati awọn ọrẹ rẹ wọn a tun maa s nipa nkan ti wọn ṣe lọsẹ to kọja.

Hana tun sọ nipa bi ogun yi ṣe yi igbe aye rẹ pada.

Lara rẹ ni bi awọn ọrẹ rẹ ti wọn jijọ n ṣere tẹlẹ ṣe n fi atẹjisẹ ranṣẹ pe ṣe oun yoo ba wọn tọju ọmọ wọn ti wọn ba jade laye.

Lẹyin ọpọ ọjọ ti o ti n duro, Hana pada ribi kan si awọn mọlẹbi rẹ to fi mọ ọmọ iya rẹ ọkunrin Yahya.

Yahya wa lara awọn oniṣowo ode oni.

Ẹni ọgbọn ọdun fẹran lati maa s nipa igbe aye rẹ ṣaaju ogun yi dipo ko maa sọ nipa ibi to n gbe nisinyi ti ero pọ nibẹ.

O ranti bi awọn ẹyẹ ṣe n kọrin lati ori orule ile awọn obi rẹ ti wọn n gbe nigba naa.

Aworan eti omi ni Gaza

Awọn eeyan a maa saba fi fọnran fidio ṣọwọ eyi ti wọn ya lati ori orule ile wọn ni al Zahra.

Ọpọ aworan yi a si maa jẹ oju ni gbese.

''Gbogbo awọn nkan wọnyi lo mu inu wa dun''

Bẹẹ naa ni Yahya ti ṣe sọ fun wa loju opo Whatsapp.

Nigba to n mẹnu ba awọn nkan to fẹran julọ nipa agbegbe rẹ, Yahya sọ ninu atẹjiṣẹ Whatsapp rẹ pe ''Mo nifẹ si ina ti o maa n tan yinyin lalẹ.Omi okun.Ilu alaafia to si yaayi ni o jẹ''

Baagi meji pere lo gbe kuro ni al Zahra.

Ninu rẹ lo si ko awọn iPad rẹ si, awọn iwe rẹ,ike to bu omi si,iwe aṣẹirina rẹ.

O fi ọpọ awọn aṣọ to rẹwa to ran kalẹ silẹ ti ko si ribi ko wọn lọwọ.

Mohammed niwaju ile rẹ ti ado oloro wo lulẹ.

Ibatan ni Ali ati Mohammed jẹ ti awọn mejeeji si jẹ oniṣowo.

Iṣẹ ti wọn ṣe nigba naa ni pe wọn n jẹ alase ounjẹ ati oludasilẹ ile tawọn eeyan ti n mu ọti ẹlẹrindodo.

Awọn mejeeji gbe ninu awọn ile kan ti wọn sọ ado oloro lu ni ọjọ Kejidinlogun ati ogunjọ oṣu Kẹwaa.

Ọpọ owo ni wọn ko sidi owo wọn ninu ile naa.

Ibẹrẹ ọdun yi ni Ali ṣe igbeyawo to si na ẹgbẹrun mẹfaa dọla lori awọn ẹsọ inu ile ti wọn baa ko sọdọ mọlẹbi kan ti oun ati iyawo rẹ to loyun sinu n gbe lọdọ rẹ.

Ọdun 2014 ni o ko kuro ni Gaza wa si al Zahra lasiko ogun to waye nibẹ laarin Hamas ati Gaza.

Aworan ile ounjẹ Mohammed to wa ni fasiti to wa ni al Zahra.
Àkọlé àwòrán, A photo of Mohamed's cafe at the university

O ni oun maa n ranti isẹmi aye tawn gbe nigba naa .

O loun ṣe afẹku awọn ọrẹ rẹ ti ''wọn a jijọ maa rẹrin, ṣe awada ti wọn a si jijọ maa joko ṣe faaji titi di oru ganjọ.''

Akọroyin Abdullah al Khatib naa sọ pe awọn mọlẹbi rẹ padanu ile wọn mẹrin lasiko ti awọn ado oloro ja lu wọn.

O ni gbogbo igba lọmọ oun maa n beere pe igba wo lawọn yoo pada sile ti wọn o jijọ maa ṣere papọ.

Amọ ko jọ pe iru anfaani bẹẹ yoo pada wa.

''Aarin titi ni ile wa wa bayii.Gbogbo nkan ni wọn ti bajẹ tan''

Aworan to ṣe afihan awọn ile tiado oloro parẹ mọlẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Mahmoud,dokita itọju ilera eni taa lo ṣagbatẹru bi wọn ṣe doola awọn ti wọn ko kuro ninu ile ti wọn opada sọ ado oloro lu ti n ṣiṣẹ iranwọ fun ibudo ilera kan ni aarin gbungbun Gaza.

''Oorun buruku ni mo maa n gboorun nibi.O o ribi wẹ ara rẹ bẹẹ naa si ni awn to wa layika rẹ naa''

Mahmoud ni oun lanfaani pe o rọrun lati ra awọn nkan ti o n gbowo lori lojojumọ.

O sọ pe oun ṣẹṣẹ fi owo ranṣẹ si ọkan lara awọn ọrẹ rẹ ti ko kuro ni al Zhara ko le fi ra iyẹfun ti wọn yoo fi ṣe burẹdi.

Amọ riri awọn nkan wọnyi ti da bi ogun bayii.

Mahmoud sọ pe o wu oun lati pada sil al-Zahra lọjọ kan ti ogun naa ba ti wa si opin.

''Mo lero pe Ọlọrun yoo jẹ ki a moribọ a o si gbiyanju lati ṣe atunṣe awọn nkan''

Aworan ti wọn kọ Mo nifẹ Gaza si ni al-Zahra

IDF sọ pe Hamas ṣ i n ṣe ikọlu lati Gaza.

Oṣu marun un sẹyin ni Hana lọ si al-Zahra kẹyin lae mọ pe igba ikẹyin ti yoo foju ba ile rẹ nuu.

''Kani mo mọ ni, mi o ba tidagbere fun ogiri ile mii ti mo nifẹ ti mo si ti ri ọpọ nkan to mu inu mi dun to si tun mu ibanujẹ bami ni igbesi aye mi.''

''Wọ n o jẹ ka ri nkankan mu dani.''