Abẹ́rẹ́ mẹ́rin sí mẹ́jọ ni mo máa ń gbà lójúmọ́ torí àrùn ìtọ̀ ṣúgà - Adewumi

Aworan Oluwabunmi Adewumi
Àkọlé fídíò, Abẹ́rẹ́ mẹ́rin sí mẹ́jọ ni mo máa ń gbà lójúmọ́ torí àrùn ìtọ̀ ṣúgà - Adewumi

Oni ni ayajọ arun itọ ṣuga ni agbaye eyi ti o n ṣi oju awọn eniyan si ipese itọju to yẹ fun ẹni to ba ni arun yii.

Ayajọ yii tun n jẹ ki awọn eeyan mọ idena ati itọju to yẹ lori arun itọ ṣuga.

Oluwabunmi Adewumi ni arabinrin to mu BBC Yoruba rin irin ajo aye rẹ lati igba to ti ni arun yii lọdun mẹtalelogun sẹyin.

Adewumi mẹnuba ẹru to maa n wa lookan aya ẹni to ni arun yii ati ẹbi rẹ pe ṣe kii ṣe pe ẹni naa ti gba ọjọ iku rẹ ni?

Oluwabunmi sọrọ lori itọju ti oun n gba, o mẹnuba iru ounjé ti o n jẹ ati awọn nkan to n ṣe lati fi mu inu ara rẹ dun laye.