Iléẹjọ́ wọ́gilé ẹjọ́ 'Oluwo Nla Tede', ó dá Tani Ọlọhun padà sí àhámó

Aworan Tani Olohun ati Oluwo Nla Tede

Ile ẹjọ Upper Area ti o kalẹ si ilu Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara ti wọgile ẹjọ ti Alfa Tonile Okutagidi pe Oluwo Nla Tede, Oloye Ademola Olawoore.

Oluwo Nla Tede ati Abdulazeez Adegbọla ti wọn n pe ni Tani Ọlọhun ni wọn jọ n jejọ ni ile ẹjọ ọhun fun ẹsun ibanilorukọjẹ, dida omi alaafia ru ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Sugbọn nibi igbẹjọ toni tii se ọjọ kẹtala osun kọkanla, Oluwo Nla Tede ni ile ẹjọ ni ko maa lọ layọ ati alaafia ti wọn si da Tani-Ọlọhun pada si ahamo ijọba Oke-Kura.

Saaju, agbẹjọro olupẹjọ naa, Usman Saad Imam, fi to ile ẹjọ leti wi pe onibara ohun ko fẹ tẹsiwaju pẹlu ẹjọ naa nitori Oluwo Nla ti tọrọ aforiji lọwọ rẹ ati awon yooku.

O fi kun pe Oluwo Nla tun seleri lati tun lọ sori ayelujara lẹyin ti o ba gba ominira patapata lati dupẹ lọwọ awọn ti ọrọ naa kan.

Ni ti Tani-Ọlọhun, Usman Imam sọ pe ikọ ohun ati awọn ikọ agbẹjọro olupẹjọ yoo pada wa jabọ fun ile ẹjọ ibi ti won de duro lori eto alaafia ati tubi n nubi ti wọn ti bẹrẹ.

Agbẹjọro olujẹjọ, Ademola Banks fidii rẹ mulẹ pe eto n lọ lọwọ lori ẹbẹ alaafia naa.

Mo dupẹ lọwọ gbogbo ilu Ilorin

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba, Oluwo Nla sọ pe oun dupẹ lọwọ gbogbo awọn to darijin oun lori ọrọ to gbe de ileẹjọ.

Nigba ti BBC beere lọwọ rẹ pe bawo lo ṣe ri lọkan rẹ lẹyin to gbọ pe ileẹjọ wọgile ẹjọ ti wn tori rẹ gbe wa siwaju adajọ, o sọ pe ''Bi eeyan ba gun ẹsin ninu mii, ko ni kọsẹ rara''

''Mo dupẹ pupọ lọwọ Alfa Okutagidi ati gbogbo ilu Ilorin''

Lẹyin ti adajọ agba, Sunday Adeniyi fagile ẹjọ Oluwo Nla tan, o sun igbẹjọ mii si ọjọ kẹtadinlọgbon osu kọkanla ọdun ti a wa yii.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post