Ọmọ-iṣẹ́ tó fi N64.4m ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó tuntun dèrò ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún

Aworan ile ẹjọ giga l'Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwọn ọdun marun-un ti ko si aaye owo itanran fun ni ile-ẹjọ giga to wa ni Ikẹja, ipinlẹ Eko ti paṣẹ bayii, pe ki ọkunrin oluṣiro owo kan, Tunde Abdulramon lọọ bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Eyi ri bẹẹ latari owo to le ni miliọnu mẹrinlelọgọta owo ọga rẹ ti Abdulramọn fi fẹyawo tuntun to si tun ṣi iru ileeṣẹ ọga rẹ fun iyawo ọhun.

Alaye kootu lori ẹsun yii ni pe, laarin 2009 si 2012 ti Tunde fi jẹ oluṣiro owo nileetaja naa to wa l'Oke Aarin nipinlẹ Eko, iṣẹ rẹ ni lati ṣe akọsilẹ owo ọja, ko fi awọn risiiti ọja ọhun ṣọwọ sibi to yẹ ko si kowo si banki lorukọ ileetaja naa.

Ṣugbọn kaka ki olujẹjọ ṣe bẹẹ, kootu sọ pe ẹri foju han, pe niṣe lo n dari owo to ba pa sapo ara rẹ, to si n pa awọn ẹri to le tọka sowo to ba gba rẹ.

Lasiko to n huwa jibiti naa lo fẹyawo tuntun to si bẹrẹ si i ra awọn dukia to ju owo oṣu rẹ lọ.

Adajọ Raliat Adebiyi to gbọ ẹjọ naa ṣalaye, pe ninu owo ti Abdulramon ko jẹ ni ileetaja naa lo ti fẹyawo tuntun, to si tun lọ ṣi ileeyata nla bii ti ọga rẹ fun iyawo tuntun naa.

Nigba to n ṣalaye, ọga to ni ileetaja naa, Constance Obi, sọ fun kootu pe Abdulramọn ki i ṣe oluṣiro owo nigba toun gba a siṣẹ. O ni o kan maa n ba awọn yooku rẹ ja ọja kalẹ lati inu kọntena ni.

Arabinrin Obi tẹsiwaju pe igba ti Tunde wa beere iranlọwọ oun ni 2004 loun gba a gẹgẹ bii ojulowo oṣiṣẹ, ṣugbọn ki i ṣe oluṣiro owo. O ni ẹka awọn to n ta ọja fawọn onibaara loun gba a si nigba naa.

‘’Ẹnikan tiẹ ti sinmi ni gbẹrẹ ipakọ lori Tunde ri nigba to bẹrẹ si i fowo mi ra awọn dukia nla nla. Ẹni yẹn pe mi, mi o mọ ọn ri, ṣugbọn o ni ki n wadii akantanti mi wo, pe o n ja mi lole pẹlu awon nnkan to n ko jọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‘’Ọjọ kẹta ti mo gba ipe yẹn ni Tunde wa fiwe silẹ fun mi pe oun ko ba mi ṣiṣẹ mọ, ṣugbọn mi o gba a lọwọ ẹ . Igba ti mo fi maa mọ pe niṣe lo n pa awọn akọsilẹ owo to ba gba rẹ, owo to ti ko ti wọ miliọnu mẹrinlelọgọta, okoo-le ni irinwo ati órundinlégbẹrun naira (N64,420,900 ).’’

Yatọ si olupẹjọ to ṣalaye bayii nipa Abdulramọn, awọn ẹlẹrii marun-un mi-in naa tun wa ni kootu lati fidi ẹ mulẹ, pe oluṣiro owo naa ti ba nnkan jẹ jinna kaṣiri rẹ too tu.

2013 ni igbẹjọ ti bẹre lori ẹjọ naa, ko too di pe Adajọ Adebiyi gbe idajọ kalẹ lọsẹ to kọja yii.

Bo tilẹ jẹpe Abdulramon loun ko jẹbi awọn ẹsun naa, Adajọ sọ pe gbogbo ẹri lo foju han, pe o huwa jibiti to le ba aye ẹlom-in jẹ. O ni bo tilẹ jẹ pe ọga to ṣe e loore ko tete mọ pe o n ji owo ko, sibẹ, ohun to ṣe naa yoo nipa buburu lori ileeṣe yii, eyi si lodi labẹ ofin.

Fun bo ṣe fowo olowo fẹyawo to si tun ṣi ileetaja to le fa orogun owo funyawo rẹ, to tun fowo ọga rẹ ra dukia, Adajọ Adebiyi paṣe pe ki olujẹjọ da gbogbo ohun to fowo naa ra pada fun ọga rẹ. Ko si tun da gbogbo owo to ji pada pẹlu.

Adajọ pasẹ pe ki akantanti to huwa jibiti yii sare lọọ faṣọ penpe roko ọba, ko le jẹ ẹkọ fawọn eeyan mi-in ti wọnb ba n hu iru iwa yii ti aṣiri wọn ko si ti i tu, ki wọn le jawọ ninu iwa afibiṣu-oloore.