Mú ṣíṣe àtúntò Nàìjíríà ní ohun tí ìjọba rẹ máà gbájúmọ́ - Gani Adams kọ ìwé sí Tinubu

Oríṣun àwòrán, @aareganiadams/INSTAGRAM
Aare Ona Kakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adama ti rọ Ààrẹ Bola Tinubu láti ṣe mímú àtúntò bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ́ òkúnkúndùn ètò ìṣèjọba rẹ̀.
Nínú ìwé àkọránṣẹ́ kan tí Gani Adams kọ ránṣẹ́ sí ààrẹ lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìlá, ọdún 2023 kí Tinubu kú oríire lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ p’r òun ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò náà.
Adams ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ náà ti ṣàfihàn pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ló fìbò gbé Tinubu wọlé gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí.
Ó ní ìdájọ́ náà fi ìfarajìn ààrẹ sí ìdájọ́ òdodo àti ìbọ̀wọ̀ fún òfin hàn láì sí ìbẹ̀rù kankan àti pé lásìkò ètò ìdìbò dandan ni kí ẹnìkan jáwé olúborí kí àwọn yòókù sì fìdí rẹmi.
“Ohun kan tó dájú ni pé ọ̀kan náà ni gbogbo wa ní Nàìjíríà tí kádàrá so pọ̀ láti máa léwájú nílẹ̀ Adúláwọ̀.
"Nàìjíríà ń kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan lásìkò yìí àti pé ẹni tó lè kojú àwọn ìṣòro náà ló wà nípò olórí tí èyí tí ó túmọ̀ sí ìgbà ọ̀tùn lágbo òṣèlú Nàìjíríà.
Aare Ona Kakanfo náà ní òun wòye pé àsìkò gan ló yẹ láti mú àtúntò bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kí orílẹ̀ èdè yìí lè dùn-ún gbé fún gbogbo ènìyàn.
Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ṣíṣe àtúntò Nàìjíríà máa wá ojútùú sí àwọn ìṣòro tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí fínra àti pé òun túnbọ̀ máa ṣe àtìlẹyìn fún ààrẹ Tinubu kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lè gòkè àgbà.
Bákan náà ló rọ ààrẹ láti sin àwọn ọmọ Nàìjíríà tọkàntọkàn láì fi ti ẹ̀yà tàbí òṣèlú kankan ṣe.















