Gómìnà tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní Kogi gbàwé ẹ̀rí mo yege lọ́wọ́ INEC

Oríṣun àwòrán, Itopa J Azeez
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC ti fún gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Kogi, Usman Ododo àti igbákejì Joel Salifu ní ìwé ẹ̀rí mo yege.
Ní oríkò àjọ INEC tó wà ní ìlú Lokoja ni wọ́n ti fi ìwé ẹ̀rí náà lé Ododo àti igbákejì rẹ̀ lọ́wọ́.
Ododo, tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ìbò 446,237 níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kọkànlá oṣù Kọkànlá ọdún 2023.
Olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party, SDP, Murtala Ajaka ló tún súnmọ́ Ododo nígbà tí òun ní ìbò 259,052 tí Dino Melaye tẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní ìbò 46,362 gẹ́gẹ́ bí INEC ṣe kéde.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó gba ìwé ẹ̀rí náà, Ododo ní òun máa ri dájú pé gbogbo ìlérí tí òun ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ni òun máa múṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Itopa J Azeez
Ó ní òun máa gùnlé àwọn àṣeyọrí Gómìnà Yahaya Bello láti mú ìlọsíwájú àti ìṣọ̀kan bá ìpínlẹ̀ Kogi.
Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún òun lásìkò ìbò ní èyí tó ṣàpejúwe gẹ́gẹ́ okùn tó so ìpínlẹ̀ Kogi ró.
Bákan náà ló tún sọ àrídájú rẹ̀ pé ìṣèjọba òun máa mú ìgbélárugẹ àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin ní òkúnkúndùn gẹ́gẹ́ bí ìjọba tó wà lóde náà ṣe ń ṣe.
“Ìpinnu mi láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ àti láti ri pé ètò ẹ̀kọ́ wà ní oókan àyà ìṣèjọba mi kò ní yẹ̀.
“Gbayawu ni ilẹ̀kùn ọ́fíìsì mi máa ṣí fún gbogbo ènìyàn láìfi ẹ̀yà, ẹ̀sìn tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe, gbogbo àwọn ará ìlú ni mà á fún láàyé nínú ìṣèjọba mi.
Gómìnà Yahaya Bello tí òun náà wà níbi ètò náà rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Edo láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú pẹ̀lú Ododo láti mú ìpínlẹ̀ Kogi gòkè àgbà.
Aṣojú INEC ní ìpínlẹ̀ Kogi, Gabriel Longpet ní ètò náà wà lára ojúṣe INEC lásìkò ìbò.
Ta ni Usman Ododo tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn sípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kogi?

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alhaji Ahmed Usman Ododo
Ahmed Usman Ododo tẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ti gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi.
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC ló kéde yìí lẹ́yìn tí wọ́n ka àkójọpọ̀ àwọn èsì káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.
Gíwà àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Nsukka, Ọ̀jọ̀gbọ́n Johnson Ozoemenam Urama, tó ń ṣiṣẹ́ fún INEC níbẹ̀ kéde pé Ododo ní ìbò 446,237 láti fẹ̀yìn àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ dupò náà janlẹ̀.

Oríṣun àwòrán, bbc
Bákan náà ló kéde pé olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, Dino Melaye rí ìbò 46,362 tí Murtala Ajaka, ti ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party, SDP ní ìbò 259,052.
Ododo gbégbá orókè ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹtala nígbà tí Murtala Ajaka ti ẹgbẹ oṣelu SDP ni ibo to pọ jul lawọn ijba ibilẹ mẹjọ.
Dino Melaye to jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP ko mu ijọba ibilẹ kankan.
Ní ọjọ Kọkànlá, oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi wáyé tí INEC sì kéde ṣíṣe ìdádúró ìbò dídì ní wọ́ọ̀dùn mẹ́sàn-án látàrí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan tó wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò náà.
Nǹkan bí aago mẹ́wàá òwúrọ̀ kọjá ní ọjọ́ Àìkú ni ètò kíkéde èsì ìbò bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Lokoja tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Kogi.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alhaji Ahmed Usman Ododo
Ta ni Usman Ododo?
Ọdun 1982 ni wọn bi Ahmed Usman Ododo nipinlẹ Ogun.
Ẹya Ebira ni Ododo ti wa lati Okene.
Oun ni oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo Gomina to n bọ.
Usman Ododo ti fi igba kan jẹ olori igbimọ aṣofin awọn ọdọ lorilẹede Naijiria.
O ti figba kan ri jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina Yahaya Bello lori ọrọ ọdọ.
Yatọ si pe o jẹ oludamọran fun Gomina, Ododo tun ti ṣe oluyẹwe owo wo awọn ijọba ibilẹ labẹ ijọba gomina Yahaya Bello.
Iroyin ni ile ẹkọ giga fasiti Ahmadu Bello, Zaria ni Ahmed Usman ti kawe gboye ninu imọ oṣelu.
Ododo ri atilẹyin gomina Yahaya Bello lasiko ipolongo ibo ipinlẹ naa.














