Àwòrán réè tó ṣàfihàn bí àwọn èsì ìdìbò ṣe n jáde ní ìpínlẹ̀ Kogi,Bayelsa àti Imo

Oríṣun àwòrán, MELAYE/ODODO/AJAKA/FACEBOOK
Wẹrẹ wẹrẹ idibo ti kasẹ nilẹ ti wọn si ti bẹrẹ si ni ka esi lawọn ibudo idibo ti idibo sipo Gomina ti n waye lawọn ipinlẹ mẹta kan ni Naijiria.
Gẹgẹ bi ofin to de ilana idibo lorileede Naijiria ṣe laa kalẹ, akojọpọ ati ikede esi ibo jẹ ojuṣe ajọ eleto idibo Naijiria taa mọ si Inec.
Idi ree taa ṣe gbe atẹ klẹ ti a o maa fi awọn esi ti ajọ Inec ba ti kede si fun yin ki ẹ baa le mọ ẹgbẹ oṣelu to n mu oke ati eleyi to n fidirẹmi.
Kika taa n wi yi ati akojọpọ esi ibo ko tii bẹrẹ ṣugbọn ẹ ma ṣe jinna soju opo wa nitori aaye taa fi silẹ yi laa ti maa fi aworan ṣafihan dede ibi ti ibo ẹgbẹ oloṣelu kọọkan ba ta egbo de.
Ẹ ma gbagbe pe idibo n waye ni Bayelsa, Kogi ati ipinlẹ Imo.
Ipinlẹ Kogi
Ipinlẹ Imo

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/UZODIMMA/ATHAN/ANYANWU/EJIOGU
Ipinlẹ Bayelsa









