Àjọ EFCC wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ OAU 11 lọ ilé-ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn jìbìtì orí ẹ̀rọ ayélujára

EFCC Logo

Oríṣun àwòrán, @EFCC Nigeria

Akẹkọọ mọkanla lati ile-ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo ti Ile-ifẹ ni ajọ to n gbogun ti bibana ọrọ-aje ati iwa ibajẹ lawujọ, EFCC, ti wọ de ile ẹjọ.

Iwaju Onidajọ Nathaniel Ayo-Emmanuel ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Osogbo nipinle Osun ni won ko won lo fun ẹsun lilọwọ ninu lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara.

Awọn akẹkọọ mọkanla naa lo wa lara awọn akekọọ mọkandinlaadọrin ti EFCC mu ni ‘Oduduwa Estate’ ni Ile-ife lọjọ kini, oṣu kọkanla, ọdun yii, ti wọn si fi mejidinlọgọta silẹ ki wọn maa lọle.

Nnekwelugo Nnaemeka, Moyosore Favour Oluwasakin, Daniel Olashile Maiye, Gbolahan Khalid Adesina, Yinka Temitope Jayeola, Olumuyiwa Emmanuel Adeleye, Abiola Emmanuel Oluwadare, Busari Abdulazeez Ayodeji ati Okesipe Tobiloba Paul ni wọn n jẹjọ lori ẹsun kọọkan, ti Perekebena Olombeni Micah ati Aghwaritoma Wisdom Obaro si n koju ẹsun mẹfa ọtọọtọ.

Ọkan lara ẹsun ti wọn fi kan Micah ka pe “nigba kan lọdun 2023 nilu Osogbo, nipinlẹ Osun labẹ agbeegbe iṣakoso ile-ẹjọ yii, iwọ parọ lori ikanni atẹjiṣẹ WhatsApp pe orukọ rẹ ni Pies, arabirin kan lati ilẹ Amẹrika, lati lee fi ọgbọn alumọkọrọyi gba owo lọwọ awọn ololufẹ arabirin naa, leyi to lodi si ofin ilẹ yi to si mu ijiya dani”.

Bakan naa ni ọkan ninu awọn ẹsun mẹfa ti wọn fi kan Obaro nii ṣe pẹlu pe o parọ fun arabirin kan, Megan Johnson, pe orukọ oun ni Alex Stephens ọmọ ilẹ Amẹrika lojuna ati lee gba owo lọwọ arabirin naa lọna aitọ leyi to lodi si ofin.

Botilẹ jẹ pe gbogbo awọn ẹni afẹsunkan naa wipe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, agbẹjọro olupẹjọ, Oluwatoyin Owodunni, beere fun ọjọ ti igbẹjọ yoo bẹrẹ ati pe ki awọn afunrasi naa o wa lọgba ẹwọn titi di ọjọ naa.

Ẹwẹ, awọn agbẹjọro fun Ayodeji, Adesina, Oluwasakin, Micah, Adeleye ati Okesipe rọ ile-ẹjọ lati jẹ ki wọn gba oniduro fun awọn afunrasi naa.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro lọtun losi, Onidajọ Ayo-Emmanuel gba ki wọn gba oniduro Ayodeji, Adesina, Oluwasakin, Adeleye ati Okesipe pẹlu miliọnu meji naira amọ ti o jọwọ Micah fun miliọnu mẹta naira.

Bakan naa lo wi pe ẹni meji gbọdọ duro fun ọkọokan awọn olujẹjọ ọun pẹlu iye owo kan naa ti oniduro akọkọ si gbọdọ jẹ obi afunrasi ọun, ti ẹnikeji yoo si jẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Osun.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla ati ọjọ kejila oṣu kejila ni adajọ mu lati bẹrẹ igbẹjọ naa.