Tinubu buwọ́lu àfikún ètò ìṣúná ₦2.17trn láti gbọ́ bùkátà àfikún owó oṣù òṣìṣẹ́ pẹ̀lú ètò aàbò

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu afikun eto iṣuna ọdun 2023 pẹlu owo ti iye rẹ jẹ ₦2.17trn.
Ṣaaju ni Tinubu ti kọkọ kọwe sile igbimọ aṣofin pe ki wọn buwọlu ₦2,176,791,286,033 eyii ti yoo fi gbọ bukata afikun owo oṣu oṣiṣẹ, ato aabo atawọn nnkan mii.
Ọjọbọ to kọja ni awọn aṣofin fontẹ lu afikun ọhun lẹyin ti wọn ka a fun igba kẹta.
Awọn asọfin agba atawọn ọmọ ile igbimọ aṣojuṣofin lo pawọpọ buwọlu afikun eto iṣuna naa lẹyin ti wọn ni o wa fun anfani gbogbo araalu.
Ẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn aṣofin ọhun kọkọ buwọlu owo ti iye rẹ to ₦819bn ninu eyii ti ijọba yoo ti yọ ₦500b gẹgẹ bii owo iranwọ faraalu lẹyin to yọ afikun owo epo bẹntiro.
Ninu ọrọ Aarẹ, afikun naa ṣe pataki lati yanju awọn iṣoro ti awọn araalu n dojukọ lẹyin to yọ afikun owo ori epo.
Ibi ipade igbimọ ilu to waye niluu Abuja ni Aarẹ ti buwọlu afikun eto iṣuna naa.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin wọgílé ìpè ìjọba àpapọ̀ láti fí N5bn rá ọkọ̀ ojú omi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Saaju ni iroyin bẹ silẹ laana pe Aarẹ Bola Tinubu ti ṣe eto owo bilọnu marun-un naira lati fi ra ọkọ oju omi, eyi ti ileeṣẹ ologun oju omi bere fun un.
Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ fidi rẹ mulẹ pe ninu owo isuna ọdun to n bọ ti ijọba apapọ fi ransẹ si ile igbimọ aṣofin ni wọn ya owo toto bilọnu marun-un naira sotọ lati fi ra ọkọ oju omi naa.
Apapọ owo toto tirilọnu meji naira ni Aarẹ Tinubu fi sọwọ si ile igbimọ aṣofin Naijiria lati buwọlu.
Ile Igbimọ aṣofin kekere lorilẹede Naijiria ti wọgile ipe ìjọba apapọ lati ra ọkọ oju omi toto bilọnu marun-un naira.
Bakan naa lo tun bẹrẹ owo toto bilọnu marun-un mii fun atunse awọn ile ẹkọ niluu Abuja.
Ipele keji ni owo isuna naa wa bayii ni ile igbimọ aṣofin.
Ọkan lara ọmọ ile igbimọ aṣofin lo fìdí ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC.
Abubakar Bichi ni ile igbimọ asofin tí wa fi owo naa ṣe afikun si owoya fun awọn akẹkọọ ti ìjọba pese.
Ki ni ijọba apapọ sọ?
Ninu atẹjade tí Olubadamọran fun Aarẹ lori ọrọ ìròyìn, Bayo Onanuga gbe síta salaye pe ileeṣẹ ologun oju omi lo ni ọkọ oju omi kii ṣe Aarẹ Tinubu.
"Ohun tí wọn pe ni ọkọ oju omi Aarẹ yii in owo isuna jẹ ohun isẹ fun ileeṣẹ ologun oju omi, ki ṣe fun lilo Aarẹ rara.
"Wọn n pe ni ọkọ oju omi Aare nitori awọn nnkan to le se nípa di dabobo.
"Ileeṣẹ ologun oju omi lo ra ọkọ oju omi naa labẹ ìjọba ana. Aarẹ Tinubu ni ijọba oun yoo tẹsiwaju ninu sise awọn isẹ apati ìjọba ana.
"Sisan owo ọkọ oju omi yii wa lara owo Ọga ologun oju omi fi ransẹ si minisita fun eto abo.
"Gbogbo owo ti wọn bere fun jẹ igba bilọnu naira sugbọn bilọnu mejilelọgọta ni Aarẹ buwọlu.
Onanuga wa jẹ ko di mimọ pe Aarẹ Tinubu mu eto abo lọkunkun dun
Ki ni awọn araalu sọ?
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti tu sita lati tako ipe ìjọba apapọ lati bilọnu marun-un naira ra ọkọ oju omi, eyi wọn pe ni ọkọ oju omi fun Aarẹ.
Ajafẹtọ ọmọniyan ati ọmọ ile asofin tẹlẹri, Shehu Sani ni awọn araalu ko le ma jiya ki olori orilẹede wa ninu ọkọ oju omi to n gbadun.
Bakan naa ni ajafẹtọ ọmọniyan, Omoyele Sowore fẹsun kan ijoba apapọ lori bi wọn ṣe n na owo lasiko ti nnkan le fun pupọ awọn ọmọ Naijiria.
SERAP salaye pe igbesẹ ìjọba apapọ lati ra ọkọ oju omi lasiko ti nnkan le fun awọn ọmọ Naijiria lo ku diẹ kato.
Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti pariwo síta lori bi ọwọngogo ṣe bẹ silẹ lati igba ti Aarẹ ti yọ owo iranwọ Bentiroo ninu oṣu karun un.












