Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa olùdíje PDP, APC àti LP tó ń du ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa

Oríṣun àwòrán, DIRI/UDENGS/SYLVA/FACEBOOK
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii ni eto idibo sipo gomina ipinlẹ Bayelsa yoo waye.
Ipinlẹ Bayelsa ni ipinlẹ to kere julọ ni Naijiria pẹlu ijọba ibilẹ mẹjọ pere, ti ọpọ awọn eeyan rẹ jẹ ẹya ijọ.
Bo tilẹ jẹ pe ipinlẹ naa ni epo rọbi, eyii to mu ko jẹ ọlọrọ lawujọ awọn ipinlẹ ni Naijiria, oniruru iṣoro lo n ba finra.
Eto idibo ti yoo waye lọjọ Abamẹta yii yoo jẹ eyii ti yoo lagbara, paapaa no bayii ti ẹgbẹ oṣelu Labour ti jẹ ọkan lara awọn to n dije, ati bi ọpọ awọn ọdọ kan ṣe gbagbọ pe Labour nikan ni ẹgbẹ oṣelu to ni ifẹ araalu lọkan.
Awọn mẹta to n leke tente ninu awọn oludije naa ni gomina to wa lori oye, Duoye Diri, gomina ati minisita tẹlẹ ri, Timpre Sylva ati olori ọdọ kan ti irawọ rẹ n milẹ titi, Udengs Eradiri.
Duoye Diri- PDP

Oríṣun àwòrán, BAYELSA GOVT NEW MEDIA
Duoye Diri ni gomina to wa lori oye lọwọ to si n du ipo fun saa keji labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ọmọ ijiọba ibilẹ Kolokuma/Opokuma ni Diri, o si ti fi akoko igba kan ṣe Sẹnetọ aringbungbun ipinlẹ naa ri.
Diri maa n pe ara rẹ ni ‘gomina iyanu’ latari pe ile ẹjọ wọgile esi idibo ọdun 2019 to waye nipinlẹ ọhun ninu oṣu Keji ọdun 2020.
Eyii ko ṣẹyin bi ile ẹjọ naa ṣe gba iṣẹ lọwọ gomina David Lyon lẹyin to ni igbakeji rẹ Biobarakuma Degi-Eremienyo fun ajọ INEC ni awọn ayederu iwe kan.
Ile ẹjọ naa wa ni ki INEC gbe iwe ẹri mo yege esi ibo naa fun Diri.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2020 kan naa ni wọn burawọle fun Diri gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.
Timipre Sylva- APC

Oríṣun àwòrán, @Timipre
Timipre Sylva lo n ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo gomina ipinlẹ Bayelsa ọdun yii.
Oun ni gomina ipinlẹ naa laarin ọdun 2008 si ọdun 2012.
Lọdun 2006, oun lo ṣe ipo keiji ninu idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin Aarẹ tẹlẹ, Goodluck Jonathan.
Lẹyin ti Jonathan di oludije sipo igbakeji Aarẹ pẹlu oloogbe Umaru Yar'Adua, Sylva bọ si ipo oludije sipo gomina ipinlẹ naa, o si jawe olubori ninu ibo sipo gomina lọdun 2007.
Inu oṣu Kẹjọ, ọdun 2019 ni wọn burawọle fun un gẹgẹ bii minisita abẹle fun ọrọ epo bẹntiro.
Udengs Eradiri- Labour Party

Oríṣun àwòrán, @Udengs Eradiri
Udengs Eradiri lo n sọju ẹgbẹ oṣelu Labour ninu ibo gomina Bayelsa lọjọ Abamẹta ọsẹ yii.
Ko to bẹrẹ si n du ipo gomina Eradiri ni Aarẹ ẹgbẹ awọn ọdọ Ijaw Youth Congress, IYC.
Lọdun 2019, o gbiyanju lati du ipo Sẹnetọ ni ẹkun idibo Kolokuma/Opokuma/Yenagoa.

Oríṣun àwòrán, UDENGS ERADIRI
Eradiri ti ṣiṣẹ kọmiṣọnna ri nipinlẹ Bayelsa, o tun sinlu gẹgẹ bii olubadamọran pataki lori ọrọ awọn ọdọ fun alaga fidihẹ ajọ NDDC.
Yatọ si awọn mẹta wọnyii, awọn mẹtala mii tun n du ipo gomina ipinlẹ naa.
Lara wọn ni Osuluku Binlaye ti ẹgbẹ oṣelu SDP, Simeon Imomotimi Karioru ti ẹgbẹ oṣelu ZLP, Azebi Bestman Ayabeke ti ẹgbẹ oṣelu NNPP, ati bẹẹ bẹẹ lọ.












