Dẹ́kun lílo ẹ̀sìn àti ẹlẹ́yàmẹ̀yà tú àwọn ọmọ Nàìjíríà ká- Tinubu dá a padà fún Obi

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Bola Tinubu ti ní kí olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi lọ wá ọ̀nà mìíràn tí yóò lò láti fi ṣe ìpolongo ìbò lílo ẹ̀sìn àti ẹlẹ́yàmẹ̀yà tí yóò bá tún kópa nínú ètò ìdìbò tí yóò bá tún wáyé.
Tinubu ní Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ń sọ fún ara wọn pé àwọn ni àwọn borí ìbò ààrẹ nínú ìbò tí wọ́n ti gbé ipò kẹta.
Ọ̀rọ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Peter Obi pe ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn ní ọjọ́ Ajé ọjọ́ Kẹfà oṣù Kọkànlá níbi tó ti ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórí ètò ìdìbò ọdún 2023 kìí ṣe òpin ìrìnàjò fún òun.
Obi fẹ̀sùn kàn ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ pé wọn kò ṣe àmúlò àwọn ẹ̀rí tó wà níwájú wọn bíi ẹ̀sùn tó fi kàn pé INEC kò ṣe àmúlò òfin ìdìbò
Àmọ́ agbẹnusọ Tinubu nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde ní Obi ń gbèrò láti fi ẹrẹ̀ yí ẹ̀ka ètò ìdájọ́ lára àti pé ó ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí Atiku Abubakar, tó jẹ́ olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party.
Ó ní àwọn méjéèjì ń bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀ka ètò ìdájọ́ nítorí ilé ẹjọ́ kò kéde wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí.
Ó fi kun pé ó yẹ Kí Peter Obi tún èrò ara rẹ̀ pa, kó sì ṣe àtúngbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tí wọn yóò máa fi ṣe ìpolongo dípò lílo ẹlẹ́yàmẹ́yà àti ẹ̀sìn níbi ìpolongo tó kọjá.
Ó ní Obi gbèrò láti kọ ẹ̀yìn àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi àti mùsùlùmí síra wọn níbi ètò ìdìbò náà.
Onanuga nínú àtẹ̀jáde náà ní irọ́ ni Obi mọ̀ láti máa pa fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Èyíi kọ́ ni òpin - Obi sọ fún àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/Peter Obi
Oludije Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP) ninu eto idibo to waye ninu oṣu keji, Peter Obi ti ni ipinnu oun ati ala oun ko ba idajọ ti ileẹjọ Supreme gbe kalẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwaa lọ, ti ko si kin ṣe opin irinajo fun oun.
Obi sọ eyi nigba to n ba awọn akọrọyin sọrọ niluu Abuja lẹyin ọsẹ meji ti ileẹjọ to ga julọ fidi eto idibo aarẹ to waye ninu oṣu keji mulẹ pe Aarẹ Bola Tinubu lo bori eto idibo naa.
Obi ni inu ko dun si idajọ ileẹjọ sugbọn sibẹsibẹ o gba lati fopin si lilọ ile ẹjọ lori esi eto idibo.
Nigba to ba awọn alatilẹyin ti wọn n pe ni ‘Obidents’ sọrọ, Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹri ni irinajo oun ko ti dopin rara.
O ni oun dupọ lọwọ gbogbo awọn ọdọ Naijiria ti sugba oun lasiko eto idibo.
“Mo n fi da wọn loju pe eyi kọ ni opin irinajo wa koda, a sẹsẹ bẹrẹ .
“A jọ sisẹ titi a fi de ibi ti a n lọ, ti a ti fẹ pese orilẹede Naijiria tuntun.”
Idajọ ileẹjọ ko jẹ ki ọmọ Naijiria ni igbagbọ ninu eto idajọ mọ
Bakan naa ni Peter Obi bu ẹnu atẹlu idajọ ileẹjọ ti kede pe Bola Tinubu lori bori eto idibo aarẹ, eyi to pe ko jẹ ki araalu ni igbagbọ mọ ninu eto idajọ lorilẹede Naijiria.
Bi nnkan bi ọsẹ meji sẹyin ni Ileẹjọ to ga ju lorilẹede wọgile ipe oludije aarẹ labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ati ti Peter Obi to jẹ oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party.
Nigba to n sọrọ, Obi ni ko tọna bi ileẹjọ ṣe kuna lati wo awọn ẹri ti wọn gbe siwaju rẹ.
“Lai si aniani, idajọ yii ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ, ti wọn ko si ni igbagbọ mọ ninu eto idajọ mọ. Idajọ na da nnkan pọ















