Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Fásítì LAUTECH pé Gómìnà Seyi Makinde lẹjọ̀.,Wo ohun tó dá lórí

Oríṣun àwòrán, @AWESOME206
Awọn akẹkọọ kan ni fasiti ẹkọ nipa imọ ẹrọ Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH), to wa ni Ogbomosho ti wọ Gomina ipinlẹ Oyo lọ s'ile ẹjọ.
Awọn nikan kọ, awọn obi akẹkọọ kan naa pẹlu ninu ipẹjọ yi to da lori bi ìjọba ṣe gbe ẹka ìmọ iṣẹ ọgbin fasiti naa lọ si ilu Iseyin.
Ohun ti igbesẹ ijọba yi tunmọ si ni pe gbogbo ẹkọ to niiṣe pẹlu ọgbin ko ni waye ni ìgboro Ogbomosho bi kii ṣe ni ilu Iseyin to jina si Ogbomoso bawọn obi ati akẹkọọ yi ṣe wí.
Ileeṣẹ iroyin Naijiria nii The Nation jabọ pe awọn akẹkọọ ẹka iṣẹ ọgbin ọlọdun keji fasiti naa ni awọn alaṣẹ fasiti ti ni ki wọn lọ tẹsiwaju ẹkọ wọn abala keji ọdún yi ni Iseyin lẹyin ti awọn alaṣẹ ko ẹka eto ẹkọ ọgbin lọ so ilu Iseyin.
Iwe ipẹjọ ti wọn fi pẹjọ HOG/34/2023 la gbọ pe wọn gbe lọ siwaju ile ẹjọ giga Ogbomosho.
Ninu awọn ti wọn si pe ẹjọ la ti ri Akintayo Abdulqoyuum Ajibola, Onwi Bassey Edet, Ezekiel Gbadegesin Ogunmola ati Prince Aderemi Olude. Awọn ti wọn pe lẹjọ la si ti ri Kọmisana eto ẹkọ ipinlẹ Oyo, adari ile ẹkọ fasiti ati adari ẹka fasiti naa to n mojuto eto ìmọ ẹkọ iṣẹ ọgbin to wa ni Iseyin.
Ohun t'awọn to pe ẹjọ l'awọn fẹ ní kí ile ẹjọ pàṣẹ fun gomina ati awọn to n gba aṣẹ lọdọ rẹ ki wọn ma ṣe tẹsiwaju pẹlu gbigbe ẹka ìmọ ọgbin fasiti naa lọ si Iseyin.
Nkan mẹta ni wọn fẹ lọdọ ile ẹjọ:
Yatọ sí eyi taa darukọ siwaju wọn láwọn fẹ ki ile ẹjọ pàṣẹ ki wọn ile ẹjọ paṣẹ ki wọn da gbogbo eto ẹkọ ti wọn sun kíkọ nípa rẹ lọ si Iseyin pada si Ogbomoso ni kiakia.
Wọn tun l'awọn fẹ ki wọn da awọn akẹkọọ ipele keji eto ẹkọ ti wọn fi iwe so pe ki wọn maa lọ si Iseyin lọjọ Kọkandinlogun oṣù Kẹwàá pada sí Ogbomoso.
Lakotan wọn ní awọn fẹ ki aṣẹ lọ sọdọ fasiti pe ki wọn ma ṣe gbe ẹka ẹkọ ọgbin tabi omiran to ba ti f'ẹsẹ rinlẹ ni Ogbomosho lọ si Iseyin tabi ibomiran ni ipinlẹ Oyo ti fasiti Lautech pẹka si.
Ijoba ipinlẹ Oyo ko ti fesi si ọrọ yii.
Wọn o ti kede ọjọ ti igbẹjo yi yoo waye.












