Bọ́ọ̀sì t’áwọn akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH jóná sínú rẹ̀ kò ní táǹkì epo, jálá tí wọ́n rọ epo sí kún ohun tó mú u laná

Àkọlé fídíò, Bọ́ọ̀sì t’áwọn akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH jóná sínú rẹ̀ kò ní táǹkì epo,
Bọ́ọ̀sì t’áwọn akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH jóná sínú rẹ̀ kò ní táǹkì epo, jálá tí wọ́n rọ epo sí kún ohun tó mú u laná

Awọn akẹkọọ ti ori ko yọ ninu ijaba bọọsi to gbina to gbẹmi awọn akẹkọọ fasiti LAUTECH Ogbomọṣọ ti ṣalaye fun BBC pe igba mẹrin ọtọọtọ ni ọkọ bọọsi to gbe wọn naa ti bajẹ loju ọna ki o to wa pada di eyi to gbina to si jo awọn akẹkọọ to wa ninu rẹ.

Awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti imọẹrọ LAUTECH naa ko ijamba lọna lasiko ti wọn n bọ nibi irinajo afẹ ti wọn ṣe si omi ori apapa ni ilu Ẹrin Ijẹṣa ni ipinlẹ Ọṣun.

Ọjọru Ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan an ni ijamba ọkọ naa waye, ninu eyi ti ọkọ bọọsi to gbe awọn akẹkọọ naa ti gbina.

Igba mẹrin ọtọọtọ nilọkọ bọọsi wa bajẹ ki o to lana

Aworan ọkan lara awọn aladugbo ibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ

Timothy Afunaya, ọkan lara awọn akẹkọọ ti ori ko yọ, ṣugbọn ti ina jo ara rẹ ba BBC News Yoruba sọrọ.

Timoth ni, awakọ bọọsi naa ti kọkọ gba ọlọkada kan ti awọn eeyan tilẹ n pariwo pe ko duro ṣugbọn ti ko dahun.

“Ohun ti a ri tẹle ni pe nṣe ni ọkọ naa takiti.

Awakọ to gbe awọn akẹkọọ LAUTECH gbe jala epo pamọ sinu ọkọ

Awọn aladugbo lagbegbe Ọkinni nilu Osogbo, nibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ ṣalaye pe awakọ naa n sa ere asapajude lẹyin to ti gba ọlọkada naa. Ere yii ni ọgbẹni Mudashiru Lukman sọ pe o ba wọ kọrọ kan.

“Nibi to ti n wo ẹyin wo lati mọ boya awọn eeyan ti oun gba ṣi n le oun lo ti sọ ijanu ọkọ rẹ nu ti kọ naa si bẹrẹ si nii gbokiti leralera...ko pẹ pupọ to balẹ bayii bi ọkọ naa ṣe lana niyẹn.”

O ni wọn tun gbe epo bẹntiro si inu ọkọ naa eyi to tubọ mu ki ina naa o lagbara sii.

Timothy Afunaya naa fi idi eyi mulẹ pe ọkọ naa ko ni agba epo. Jala epo lo wa ko epo naa si.