Kò sí iṣẹ́ tí àwọn abarapá ń ṣe tí n kò le ṣe - Akanda Taibat Ọba Ara
Taibat Oba Ara to jẹ olorin ati oṣere tiata ti jẹ ko di mimọ pe oun ko jẹ ki bi Ọlọrun ṣe da oun ṣe idiwọ tabi akoba ninu ilọsiwaju irinajo rẹ.
Oba Ara, ẹni to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn lo le ni ipenija ẹsẹ mejeeji, ti ko si le rin sugbọn to gbiyanju lati tẹsiwaju ninu irinajo rẹ.
O ba ileeṣẹ BBC News Yoruba sọrọ pẹ oun ko le sọ pato bi oun ṣe di akanda ẹda nitori bi oun ṣe gbọnju mọ ara oun niyẹn.
“Bi wọn ṣe bi mi re, bi mo se gbọnju ba ara mi ree. Mo ran ronu pe ki ẹsẹ mi ti Ọlọrun da mi bayi sugbọn nigba to ya mo pada riro pe ati ẹni to pe ati akanda, nkankan ni gbogbo wa.
“Ọpọlọ to wa lori ẹni to pe lo wa lori temi naa.”
Taibat ko ki n fẹ jade sibi ti awọn eeyan wa nitori itiju- Afẹsọna Taibat

Kini ololufẹ Taibat to n jẹ Solomon sọ nipa re?
Solomon Idowu to jẹ afẹsọna Taibat Ọba Ara ni inu oun bajẹ lọjọ ti oun kọkọ ri nitori ko ki fẹ wa laarin awọn eeyan nitori itiju.
Idowu ni oun lati lọ ba pe oun ti pinnu lati ma tọju rẹ , ko si ri gẹgẹ bi ẹnikeji rẹ
“Mo lọ ba Taibat pe ko ri gẹgẹ bi ẹnikeji rẹ, ti ma si ma mu inu rẹ dun.
”Ọpọ awọn mọlẹbi ati ọrẹ ti ni iki ṣe iru eeyan to yẹ ki fẹ ree sugbọn mo dupẹ loni pe yẹyẹ awọn eeyan ti n di ayẹyẹ fun wa.”
Taibat fikun pe lọwọlọwọ bgayi ko si nnkan ti awọn eeyan to pe le ṣe ti oun akanda o le ṣe.
“Awọn to pe le kọrin, mo n kọrin, wọn ṣe sinima, mo n ṣe sinima, awọn to le rin n taja, mo n taja temi naa.
“Mo ti ṣe ọpọlọpọ orin ti mo si ti ba awọn eeyan ṣe sinima sugbọn o wu mi lati le gbe sinima temi gan jade.”













