A wọ́gilé gbogbo ipò Yoruba tí Obasanjo jẹ - YCW

Aworan Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Ẹgbẹ ọmọ Yoruba lagbaye, Yoruba Council Worldwide ni awọn ti wọgile ipo ki ipo ti Ọba ni ilẹ Yoruba fi Aarẹ tẹlẹ ri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo jẹ nitori bi o ṣe kuna lati tọrọ aforijin lọwọ awọn Ọba alade nipinlẹ Oyo.

Ikede yii lo wa ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Aarẹ Ọba Oladotun Hassan buwọlu, to si pe akiyesi

Ọba Saka Metamilola, Olowu ti ilu Owu si.

Hassan ni ọrọ ti Obasanjo sọ si awọn lọbalọba lasiko to n ṣe ifilọlẹ isẹ kan akanṣe Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lo jẹ apejuwe iwuwasi ologun to n ba awọn ọmọde sọrọ, ti ko si ni itẹwọgba ni ilẹ Yoruba.

Aworan Ikede YWC

Oríṣun àwòrán, YWC

“A n palasẹ pe a ti wọgile gbogbo ipo ki ipo ti Ọba alade fi Obasanjọ jẹ, paapa ti Balogun ti ilu Owu lẹyin Obasanjọ kọ lati tọrọ aforijin.

“Ọrọ to waye ni LAUTECH lo jẹ ọrọ to dojutini pupọ, ki eeyan pasẹ bi Ọga ile ẹkọ to n ba awọn akẹkọọ sọrọ.

“Awọn lọbalọba, ori ade nla ni awọn Ọba yii. A ko le tẹwọgba iwuwasi yii.

Aarẹ Ọba Hassan wa rọ gbogbo ọmọ karọ ojire, ọdọ, iya lọja ati awọn olori wọn lati tẹle asa naa.

Mo dúró lórí ọ̀rọ̀ tí mo sọ sáwọn ọba ní ìpínlẹ̀ Oyo - Obasanjo

Aworan Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Olusegun Aremu Obasanjo/X

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin ti awuyewuye lori ọrọ ti aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Oloye Olusegun Obasanjo sọ sawọn ori-ade kan nipinlẹ Oyo, Oloye Obasanjo ti sọ pe oun si duro lori ọrọ ti oun sọ.

Lọjọ Ẹti to lọ nibi ifilọlẹ ati ṣiṣi ẹka ile ẹkọ fasiti LAUTECH to nii ṣe pẹlu eto ọgbin niluu Iseyin ni Obasanjo ti sọ fawọn ori-ade to wa ni ijokoo lati dide fun gomina Seyi Makinde ipinlẹ naa to si tun sọ fun wọn pe ki jokoo pada.

Ọrọ yii ti di iṣu ata yan-an yan an kaakiri ilẹ Yoruba debi wi pe ọpọ lo ti bẹnu ẹtẹ lu aarẹ ana pe ihuwa si kudiẹ kaato.

Oluwo ti ile Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi, tiẹ kepe Obasanjo lati tọrọ aforijin tori pe o wọ awọn ọba alaye nlẹ pẹlu ọrọ to sọ.

Bakan naa ni ẹgbẹ ọmọ Yoruba lagbaaye, YCW sọ pe Obasanjo yoo foju wina ofin ti o ba kọ lati tọrọ aforijin.

Lọjọ Aiku ni obinrin kan ti o n jẹ Taiwo Obasanjo ti ọpọ ri i gẹgẹ bi iyawo aarẹ Naijiria tẹlẹ ri tọrọ aforijin lorukọ Obasanjo.

Ninu ọrọ ti obinrin naa fi sita lo sọ pe ni ikọkọ lo ti yẹ ki Obasanjo ba awọn ori-ade yii sọ ọrọ to sọ ni gbangba.

Amọ, Obasanjo fesi pada lọjọ Aje wi pe oun ko ni ko ọrọ oun jẹ lori awọn ọba Oyo.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Kehinde Akinyemi fi sita ni o ti ṣalaye pe Arabinrin Taiwo Martins bi ọmọ meji, Jonwo ati Bunmi fun Oloye Obasanjo, ṣugbọn ki i ṣe iyawo Obasanjo, bẹẹ si ni ki i ṣe ẹbi Obasanjo.

Ọgbẹni Akinyemi ni Obasanjo duro gidigba lori ẹsẹ rẹ pe gomina ni ọfiisi ga julọ ni ipinlẹ ti wọn ba wa.

Akọwe iroyin aarẹ ana orilẹede Naijiria sọ pe ohun kohun ti Arabinrin Taiwo ba sọ ko ni ṣe pẹlu Obasanjo.