Obasanjo gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn lóri bí ó ṣe fi àwọn Orí-adé wọ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo- Oluwo

Aworan Oluwo ati Olusegun Onasanjo

Oríṣun àwòrán, Oluwo Oba Abdulrasheed Akanbi Telu 1/Facebook

Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrosheed Akanbi, ti kepe aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Oloye Olusegun Obasanjo lati tọrọ aforijin lọwọ awọn ọba ipinlẹ Oyo lẹyin ti o peṣẹ fun wọn pe ki wọn dide fun Gomina Seyi Makinde.

Lọjọ Ẹti ni fidio kan ninu eyi ti Obasanjo ti fi ibinu sọ fawọn ọba alaye pe ki wọn dide lati bu iyi fun Makinde ti o si tun ni ki wọn jokoo padaa, eleyii ti awọn naa si ṣe bẹẹ tan kalẹ kaakiri ori ayelujara.

Lati igba naa lawọn eeyan ti n bu ẹnu ẹtẹ lu ihuwasi Obasanjo sawọn ori-ade ipinlẹ Oyo tọtọ naa kan.

Ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ Alli Ibrahim akọwe iroyin rẹ, Oluwo ni aarẹ Naijiria tẹlẹ ri ni lati kọ lẹta lati tọrọ aforijin lori iṣẹlẹ naa.

Oluwo sọ pe awọn ọb alaye nilẹ Yorubo kọja ẹni ti Obasanjo le maa paṣẹ fun bi ẹni pe awọn iṣọmọgbe sọja lo n baa wi.

Oluwo ni ‘’awọn nkankan wa ti n ko le mu mọ ra rara niwọn igba ti mo si wa laaye.

Awọn ọba ti wọn dide nigba ti Obasanjo sọrọ ni mo ba wi ju, ohun to buru jai ni Obasanjo ṣe.

Eleduwa lo fawọn ori-ade yii jọba, kii ṣe eeyan.

Nitori naa, a ni lati bu ọla fun wọn ni awujọ.

Awọn ọba alade kii ṣe ọmọ kekere, baba ni a jẹ lawujọ.

Obasanjo gan an ko le dan iruẹ wo fawọn Ẹmia nilẹ Hausa.''

Ẹgbẹ ọmọ Yoruba lagbaaye YCW ni Obasanjo le foju wina ofin ti ko ba tọrọ aforijin

Ẹwẹ, ẹgbẹ ọmọ Yoruba lagbaaye, Yoruba Council Worldwide, naa ti sọ pe Obasanjo gbọdọ tọrọ aforijin.

Ẹgbẹ YCW ṣapejuwe ihuwasi Obasanjo gẹgẹ bi eewọ nilẹ Yoruba.

Ẹgbẹ naa sọ pe gbogbo ọmọ Yoruba ni Obasanjo tabuku wọn lori bi o ṣe wọ awọn ọba alaaye nilẹ.

Ẹgbẹ naa leri pe ọrọ naa le mu ki Obasanjo gbena woju ofin to ba kọ lati tọrọ aforijin.

Lọjọ Abamẹta ni aarẹ ẹgbẹ YCW, Oba Oladotun Hassan, fọrọ yii lede niluu Abuja nibi to ti bawọn akọroyin sọrọ.

Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni àwọn lọ́balọ́ba ṣẹ Obasanjo tí ọ̀rọ̀ fi di ariwo ní ìpínlè Oyo?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo fi idi ọrọ mulẹ pe ijọba, olori ilu yala gomina tabi aarẹ ni agbara ju Ọba lọ, to si yẹ ki Ọba ma bọwọ fun wọn.

Obasanjo, lasiko to n sọrọ nibi to ti n ṣe ifilọlẹ oju ọna Oyo- Iseyin nipinlẹ Oyo, palasẹ fun awọn Lọbalọba lati duro, ki wọn si bọwọ fun.

O salaye pe ipo Ọba ko ni ki eeyan ma rin agba tabi ẹni to wa nipo Ijọba fin gẹgẹ bi asa ilẹ Yoruba ṣe salaye.

“Mo ki gbogbo Lọbalọba, ẹ se ti wa si ibi bayi

“Sugbọn ẹ jẹ ki sọ nkankan, ibi ti gomina ba wa tabi ti aarẹ ba wa.

“Ko si Ọba naa, o ni lati dide fun gomina tabi aarẹ, ẹ dide, ẹ joko”

Oba tẹsiwaju pe ni ilẹ kaarọ ojire, nkan meji ni Yoruba bọwọ fun, ojo ati ipo, to si itumọ si pe ipo gomina tabi aarẹ ju ti Ọba lọ

“Nigba ti mo jẹ Aarẹ, mo n dọbalẹ fun Ọba, sugbọn ti mo ba wọ yara, Ọba yoo dọbalẹ fun mi.

“Ẹ je ki a gbe asa wa larugẹ.”

Aarẹ tẹlẹri, Olusegun Obasanjo lo jẹ Aarẹ orilẹede Naijiria lati ọdun 1999 ti wọ ọdun 2007.

Ọpọ eeyan lo ti fajuro si ọrọ ti aarẹ tẹlẹri sọ si awọn lọbalọba.