Emefiele kọ̀wé fipò sílẹ̀ bí Cardoso ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN ti kéde pé gómìnà àná ní ilé ìfowópamọ́ náà, Godwin Emefiele ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀.
Ìkọ̀wéfipòsílẹ̀ náà ló ń wáyé lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí Ààrẹ Tinubu ní kí Emefiele lọ rọ́kún nílé fún ìgbà kan ná.
Lẹ́yìn tí Tinubu ní kí Emefiele lọ rọ́kún nílé ni àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS fi sí àhámọ́ tí wọ́n sì gbé lọ sílé ẹjọ́.
Ìjọba àpapọ̀ yàn igbákejì Emefiele láti máa delé, kí ó máa ṣe àkóso ilé ìfowópamọ́ náà.
Àtẹ̀jáde kan láti ọ́fíìsì Agbẹnusọ akọ̀wé ìjọba orílẹ̀ èdè yìí, Willie Bassey ní ìdí tí ìjọba ṣe ni kí Emefiele lọ rọ́kún nílé ni ìwádìí kan tó ń lọ lọ́wọ́ lórí rẹ̀ àti pé ìjọba fẹ́ ṣe àtúntò ẹ̀ka ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.
Ẹ̀wẹ̀ ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kẹsàn-án ni ìjọba kéde ìyànsípò Olayemi Cardoso bíi gómìnà tuntun tí ilé aṣòfin àgbà bá buwọ́lu ìyànsípò náà.
Àtẹ̀jáde látọwọ́ agbenusọ Tinubu, Ajuri Ngalele ni wọ́n ti kéde ìyànsípò ọlọ́dún márùn-ún náà.
Láti fìdí èyí múlẹ̀, CBN nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹsàn-án ní Cardoso ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún.
Agbenusọ CBN, Isa Abdulmumin nínú àtẹ̀jáde náà ní Cardoso yóò máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adelé títí tí ilé aṣòfin àgbà fi máa buwọ́lu ìyànsípò rẹ̀.
Abdulmumin ní èyí ń wáyé lẹ́yìn tí Godwin Emefiele kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà CBN.
Bákan náà ló ní àwọn mẹ́rin tí Tinubu yàn gẹ́gẹ́ bí igbákejì sí Cardoso ni àwọn náà tí wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn tí àwọn igbákejì Emefiele tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀.
Cardoso ni alága ilé ìfowópamọ́ Citibank Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ tó sì ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí lẹ́ka ètò ìsúná àti ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.
Tinubu yan Yemi Micheal Cardoso ní gómìnà CBN, fi orúkọ rẹ̀ ránṣẹ́ sílé aṣòfin

Oríṣun àwòrán, OLAYEMI CARDOSO
Ààrẹ Bola Ahned ti buwọ́lu ìyànsípò Dókítà Olayemi Micheal Cardoso gẹ́gẹ́ bí gómìnà ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN fún sáà ọdún márùn-ún tí ilé aṣòfin àgbà Nàijíríà bá buwọ́lù ú.
Ìdarí yìí ló wà ní ìbámu pẹ̀lú abala kẹjọ ìwé òfin ilé ìfowópamọ́ CBN tọdún 2007 èyí tó fún ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láṣẹ láti yan gómìnà CBN àti àwọn igbákejì rẹ̀ mẹ́rin.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ààrẹ Ajuri Ngalele fi léde laja Ẹtì ní Tinubu tún buwọ́lu ìyànsípò Emem Nnana Usoro, Muhammad Sani Abdullahi Dattijo, Philip Ikeazor àti Dókítà Bala M. Bello bí i igbékejì gómìnà CBN.
Ngalele ní ààrẹ ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí pé àwọn tí wọ́n yàn náà yóò ṣe àwọn àtúntò ní CBN tí yóò mú àyípadà bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.
Ó ní tí àtúntò gidi bá ti bá ọrọ̀ ajé Nàìjírí, àwọn olùdókoòwò yóò wá láti gbé ọrọ́ ajé Nàìjíríà lárugẹ.
Ta ni Yemi Cardoso?
Cardoso tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Eko tó sì dàgbà ní Eko.
Bàbá rẹ̀ ni Felix Bankole Cardoso tó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tó jẹ olùṣirò àgbà Nàijíríà lọ́dún 1963 àti igbékejì alága àti adarí àkóso ilé ìfowópamọ́ Barclays Bank of Nigeria lọ́dún 1972.
Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Corona School Ikoyi kó tó tẹ̀síwájú lọ sí St Gregory College fún ẹ̀kọ́ girama.
Ní ọdún 1980 ló parí ẹ̀kọ́ gíga nínú ìmọ̀ nípa àkóso àti ètò ìyẹn Managerial and Administrative Studies ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Aston University.
Ní ọdún 2005 ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè kejì nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Public Administrative ní ilé ẹ̀kọ́ Harvard Kennedy School of Government.
Ní ọdún 2017 ni ilé ẹ̀kọ́ Aston University fi oyè ọ̀mọ̀wé da lọ́lá fún àwọn àṣeyọrí Cardoso ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ aládani àti ti ìjọba.
Cardoso ti gba àmì ẹ̀yẹ ní oríṣiríṣi lórí iṣẹ́ tó yàn láàyò.














