Àìsàn onígbá méjì ṣekúpa ènìyàn 84, àwọn 2,860 míì tún lùgbàdì rẹ̀ – NCDC

Oríṣun àwòrán, Others
Àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ àrùn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NCDC ti kéde pé ènìyàn mẹ́rìnlélọ́gọ́rin ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsàn onígbá méjì láàárín oṣù kìíní ọdún yìí sí oṣù Kẹjọ.
Bákan náà ni wọ́n ní ènìyàn 2,860 ló tún lùgbàdì àìsàn náà láàárín àsìkò kan náà.
Àtẹ̀jáde tí àjọ náà fi sórí ayélujára X lọ́jọ́rú ní ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní ìjọba ìbílẹ̀ 124 ni wọ́n ti rí àìsàn náà.
Cholera jẹ́ àìsàn tí ó máa ń mú ènìyàn yàgbẹ́ gbuuru àti èébì ti kòkòrò àìfójúrí Vibrio cholerae máa ń fà.
Ènìyàn le ní cholera tí wọ́n bá jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tí kòkòrò tó ń fa Cholera bá wà.
Fún àwọn ẹlòmíràn, àmì àìsàn yìí kìí burú púpọ̀ ní ara wọn tí àwọn sì lè gba ibẹ̀ kú tí àìsàn náà bá gbòdì lára wọn.

Oríṣun àwòrán, Others
Ní Nàìjíríà àìsàn onígbá méjì jẹ́ èyí tó máa ń wáyé ní ọdọọdún pàápàá ní àsìkò òjò tó sì máa ń jà ní àwọn agbègbè tí ìmọ́tótó kò bá sí.
Àtẹ̀jáde NCDC ní àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì pé ọdún márùn-ún ló lùgbàdì àìsàn náà jùlọ, tí àwọn tí ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún mẹ́rìnlá sì tẹ̀lé wọn.
Bákan náà ni wọ́n ní pé ìdá mọ́kànléláàdọ́ta nínú àwọn tó ní àìsàn náà jẹ́ ọkùnrin tí àwọn mọ́kàndínláàdọ́ta jẹ́ obìnrin.
Àwọn ìpínlẹ̀ tó ní àkọ́ọ́lẹ̀ Cholera ní ọdún yìí ni Ondo, Oyo, Ekiti, Osun, Zamfara, Cross River, Katsina, Bayelsa, Ebonyi, Niger, Abia, Jigawa, Kano, Borno, Kaduna, Bauchi, Sokoto, Plateau, Gombe, Adamawa, Kebbi, Benue, Rivers, Imo àti Anambra.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ ìpínlẹ̀ Zamfara ló ní àkọ́ọ́lẹ̀ àìsàn náà jùlọ .
Wọ́n fi kun pé àkọ́ọ́lẹ̀ àìsàn Cholera àti àwọn ènìyàn tó ba lọ ní ọdún yìí dínkù jọjọ sí ti ọdún tó kọjá.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post













