Láti gbógun ti ààrùn, àwọn ọ̀dọ́ kó arawọn jọ láti ṣe ìmọ́tótó

Àkọlé fídíò, Láti gbógun ti ààrùn, àwọn ọ̀dọ́ kó arawọn jọ láti ṣe ìmọ́tótó

Awọn ọdọ kan lorilẹede Malawi ko arawọn jọ lati ṣe imọtoto ayika wọn lati le gbe ogun ti aarun onigbameji to nba ilu naa ja.

Dwanyne Nyambo, oludasilẹ ‘vibrant keeps it clean’ ni ipiinu oun ni lati ṣe amojuto gbogbo ọga ni Malawi.

“Awọn ọdọ lo jẹ ọmọ ogun ti Dwayne kọ jọ lati ṣe imọtoto ilu.

Aworan awọn ọdọ to n ṣe imọtoto

“Idi ti mo fi gbe igbimọ yii kalẹ lati ri mu imọtoto ba agbegbe wa lati mu adikun ba bi aarun ṣe n ba wa ja.”

Awọn araalu kan sara si igbesẹ awọn ọdọ yii, ti wọn si ni o mu inu awọn dun.

“Inu wa dun si nnkan ti awọn ọdọ yii ṣe, ti wọn ṣe amojuto ọja.”