Goodluck Jonathan wà lára ọgọ́rùn ún èèyàn tó gbàmì ẹ̀yẹ àlááfíà ní Áfíríkà

Aworan Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Goodluck Jonathan/Facebook

Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan wa lara eeyan ọgọrun un to gba ami ẹyẹ alaafia nilẹ Afirika.

Ni Ọjọbọ lajọ to n ri si eeyan ọgọrun to n lepa alaafia fun Jonathan ni ami ẹyẹ naa niluu Abuja.

Ọgbẹni Kingsley Amafibe, to jẹ oludari ajọ naa l’Afirika ṣalaye pe ami ẹyẹ naa tọ si Jonathan latari isẹ takun takun to ti ṣe nipa wiwa alaafia ati iṣọkan ilẹ Afirika.

Amafibe ni awọn eeyan ọgọrun un yii jẹ awọn ti wọn ti lo ẹbun, ipo ati owo wọn lati lepa alaafia ni Afirika, eleyii ti Jonathan si ti ṣe.

O fikun ọrọ rẹ pe ajọ naa fun Jonathan ni ami ẹyẹ ọhun lẹyin ti wọn ti ṣiṣẹ iwadii lori aarẹ ana orilẹede Naijiria ki wọn awọn to fi ami ẹyẹ naa da a lọla.

Amafibe sọ pe ‘’Jonathan jẹ ami alaafia, ifiraẹnijin fun ilẹ baba rẹ Naijiria.

Bakan naa ni Jonathan jẹ apẹẹrẹ olori to ṣe e mu yangan fawọn ọdọ ni gbogbo orilẹ Afirika.

Jonathan fi apẹẹrẹ nla lelẹ nigba to gba pe oun fidi rẹmi ninu ibo aarẹ Naijiria ọdun 2015..

Koda, o tun sọ pe ipo oṣelu ti oun n du ko to itajẹ silẹ ọmọ Naijiria kankan.

Ifẹ ti Jonathan fihan si Naijiria nipa bi o ti gbe ijọba fun Muhammadu Buhari ni ko jẹ rogbodiyan bẹ silẹ ni Naijiria.

Nitori naa, Jonathan pegede laarin awọn ọgọrun eeyan to gba ami ẹyi naa.’’

Ninu ọrọ rẹ, Jonathan ki awọn to ṣagbatẹru ami ẹyẹ naa fun imọyi ti wọn ṣe fun oun.

O wa ṣeleri pe oun yoo tẹsiwaju lati maa lepa alaafia iṣọkan ati ilọsiwaju Naijiria.