Irọ̀ ni pé Dókítà ṣe iṣẹ́ fún wákàtí 72- LUTH

Oríṣun àwòrán, Twitter
Awọn alasẹ ile iwosan ijọba ipinlẹ Eko, LUTH, Idi-Araba ti kede pe irọ ni iroyin kan to ni ọkan lara awọn dokita ile wosan naa, Dr Michael Umoh jade laye lẹyin to sisẹ lia duro fun wakati mejilelaadọrin.
LUTH ni bi awọn mọlẹbi ṣe n daro eeyan wọn to jade laye naa ni o ṣe koko fun ile iwosan lati tan imọlẹ si isẹlẹ to waye paapa iroyin nipa iku rẹ.
Ọga agba fun ile iwosan naa, Ọjọgbọn Lanre Adeyemo na ileeṣẹ iroyin abẹle PunchNG ni oun ko ti ri gbọ pe Dokita ọhun jade laye nitori pe o sisẹ fun ọjọ mẹta.
Saaju ni awọn igbimọ Dokita ti ẹka LUTH, ninu atẹjade kan ti wọn fi lede pe Dr Umoh jade laye nitori o wa lẹnu isẹ fun ọjọ mẹta gbako.
Dokita Umoh jade laye lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan an ọdun 2023 nigba to wa ni ile ijọsin pẹlu awọn obi rẹ
“Iku Dokita Umoh dun wa pupọ sugbọn irọ ni iroyin to ni o sisẹ fun ọjọ mẹta.
“Akọsilẹ wa fihan pe o wa ni ibi isẹ lọjọ kẹtala ati ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an. Ko si ni ibi isẹ lọjọ kẹdogun, kẹrindinlogun ati kẹtadinlogun to jade laye.
“O wa ni ile lọjọ awọn obi rẹ lọjọ kẹrindinlogun ati kẹtadinlogun ọdun 2023.”
Bakan naa awọn alasẹ ile iwosan ti ṣe abẹwo si mọlẹbi Dokita Umoh ni ohunjọ oṣu kẹsan an lati bawọn kẹdun lori eeyan to jade laye ati lati mọ nipa oun pato to sokunfa iku naa.
Ile iwosan LUTH sapejuwe Umoh gẹgẹ Dokita to n sisẹ takutakun lati ṣe iranwọ fun awọn eeyan to nilo rẹ ni ile iwosan.












