A ó kéde èsì àyẹ̀wò òkú Mohbad láìpẹ́- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ti pari ayẹwo oku gbajugbaja olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad, ti awọn yoo si kede esi ayẹwo laipẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lo kede ọrọ yii loju opo ayelujara X rẹ ni orọlẹ Ọjọbọ.
Mohbad, ẹni to jade laye lọsẹ to kọja, ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n pe fun idajọ odoodo lori ohun to sokunfa iku rẹ.
Saaju ni Ọga agba fun Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Kayode Egbetokun palasẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko pe ki iwadi kunkun bẹrẹ lori ohun to ṣekupa Mohbad.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2
'Ileeṣẹ ọlọpaa ti hu oku Mohbad fun ayẹwo'
Bakan naa ni Iyabo Ojo jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ ti hu oku Mohbad fun ayẹwo l'Ọjọbọ.
Ojo ni Iya Mohbad ti gba pe ki wọn hu oku ọmọ rẹ fun ayẹwo ati tuntun sin ni ilana to bu ọla fun un.
Ṣaaju ni ọga ọlọpaa fi lede pe awọn yoo hu oku Mohbad ni ọsẹ yii fun ayẹwo ki o le ran iṣẹ iwadii lọwọ.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣeleri lati fi esi ayẹwo oku naa sita lẹsẹkẹsẹ lọsẹ yii.
“Ọlọpa ni ka fun awọn ni ọsẹ meji lati pari iwadii wọn, bi a ṣe n sọrọ awọn eeyan kan ti wa ni ahamọ ọlọpaa,'' Iyabo lo sọ bẹẹ.
Ọlọ́pàá ti ránsẹ́ pe Naira Marley, Sam Larry àti àwọn tí ọ̀rọ̀ ikú Mohbad kàn- Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti kede pe ileeṣẹ ọlọpaa ti hu oku Ilerioluwa Aloba ti ọpọ si Mohbad.
Hundeyin fi ọrọ yii lede loju opo ẹrọ agbọrọkaya X rẹ lọsan Ọjọbọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣalaye pe ayẹwo oku Mohbad maa bẹrẹ lọgan lẹyin ti oku naa ti di huhu bayii.
Ṣaaju ni kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko gbe igbimọ ẹlẹni mẹtala kan dide lati tọ pinpin ohun to ṣe okunfa iku Mohbad.
Nigba naa ni ileeṣẹ sọ pe awọn yoo hu oku ọdọmọde olorin naa lati le ran iṣẹ iwadii awọn lọwọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

End of X post, 4
Iyabo Ojo ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ranṣẹ pe awọn ti ọrọ iku Mohbad kan
Gbajugbaja oṣere tiata, Iyabo Ojo, lana jisẹ ipade ti oun ati awọn mii ṣe lori iku olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ si Mohbad pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko.
Ojo salayẹ lẹkunrẹrẹ loju opo itakun ayelujara Instagram rẹ, to si ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fi iwe ransẹ si Azeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley ati Samson Balogun, ti ọpọ mọ si Sam Larry lati fara han si ileeṣẹ ọlọpaa.
Gẹgẹ bi o ṣe salaye, Ojo ni ileeṣẹ ọlọpaa ni o ṣe koko ki awọn ti awọn fi iwe pe yọju si ileeṣẹ Ọlọpaa lati wa wi tẹnu wọn tabi ki wọn kede wọn pe awọn n wa wọn lọsẹ to n bọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
“Fun ifọrọwa ni lẹnu wo, ileeṣẹ ọlọpaa ti kan si awọn eeyan meji ti ọrọ kan ati awọn yooku, ti wọn si ti fi iwe pe wọn, eyi tumọ si gbogbo orukọ ti wọn darukọ, Naira Marley ati Sam Larry, ti wọn si ti fun wọn gbedeke ọjọ lati fesi pada, to tunmọ si pe ki wọn foju han.
“Ọlọpaa ni ti awọn ti awọn fi iwe pe ba kuna lati foju han, awọn yoo kede wọn gẹgẹ bi ọdaran ti wọn n wa ati pe, ọrọ pe wọn ko si ni ilu ko ni ri ẹsẹ mulẹ nitori wọn le awọn ọlọpaa oke okun lati mu wọn jade.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
'Nọọsi to fun Mohbad ni abẹrẹ ti wa ni ahamọ'
Iyabo Ojo tun jẹ ko di mimọ pe nọọsi to fun Mohbad ni abẹrẹ lasiko to wa ni ile iwosan ti wa ni ahamọ ọlọpaa fun ifọrọwanilẹnuwo bayii.
“Wọn ti ọpọlọpọ eeyan, bi nọọsi to fun ni abẹrẹ .
“Gbogbo awọn nnkan ti mo mọ, ti mo si le sọ fun yin bayii re.
“Bakan naa ni wọn ti fi iwe pe awọn eeyan lati wa wi tẹnu lori iku Mohbad.”
Saaju ni Iyabo Ojo gbero lati ṣe iwọde lori iku Mohbad sugbọn to pada forisọnpọn nitori ileeṣẹ ọlọpaa ni o ṣeeṣe ki wọn janduku lo akoko naa lati da wahala silẹ.